Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 14:1-32

14  Nítorí Jèhófà yóò fi àánú hàn sí Jékọ́bù,+ ó sì dájú pé òun yóò ṣì yan Ísírẹ́lì;+ yóò sì fún wọn ní ìsinmi lórí ilẹ̀ wọn+ ní ti tòótọ́, àtìpó yóò sì dara pọ̀ mọ́ wọn, wọn yóò sì so ara wọn mọ́ ilé Jékọ́bù.+  Àwọn ènìyàn yóò sì mú wọn ní ti tòótọ́, wọn yóò sì mú wọn wá sí ipò wọn, ilé Ísírẹ́lì yóò sì gbà wọ́n mọ́ra bí ohun ìní lórí ilẹ̀ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin;+ wọn yóò sì di amúnilóǹdè+ àwọn tí ó mú wọn ní òǹdè, wọn yóò sì máa jọba lórí àwọn tí ń kó wọn ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ rí.+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ náà, nígbà tí Jèhófà bá fún ọ ní ìsinmi kúrò nínú ìrora rẹ àti kúrò nínú ṣìbáṣìbo rẹ àti kúrò nínú ìsìnrú nínira nínú èyí tí a ti sọ ọ́ di ẹrú,+  pé ìwọ yóò sọ ọ̀rọ̀ òwe yìí lòdì sí ọba Bábílónì, pé: “Ẹ wo bí ẹni tí ń kó àwọn mìíràn ṣiṣẹ́ ṣe wá sí òpin, ìninilára ti wá sí òpin!+  Jèhófà ti ṣẹ́ ọ̀pá àwọn ẹni burúkú, ọ̀gọ àwọn tí ń ṣàkóso,+  ẹni tí ń fi ẹgba na àwọn ènìyàn láìdabọ̀ nínú ìbínú kíkan,+ ẹni tí ń tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba nínú kìkì ìbínú pẹ̀lú inúnibíni tí a kò dá dúró.+  Gbogbo ilẹ̀ ayé ti sinmi,+ ó ti bọ́ lọ́wọ́ ìyọlẹ́nu. Àwọn ènìyàn ti tújú ká pẹ̀lú igbe ìdùnnú.+  Àní àwọn igi júnípà+ pẹ̀lú ń yọ̀ ọ́, àwọn kédárì Lẹ́bánónì, wí pé, ‘Láti ìgbà tí o ti dùbúlẹ̀, kò sí agégi+ tí ó dìde sí wa.’  “Kódà, Ṣìọ́ọ̀lù+ nísalẹ̀ ni ṣìbáṣìbo ti bá nítorí rẹ, láti lè pàdé rẹ bí o ti ń wọlé bọ̀. Nítorí rẹ, ó ti jí àwọn tí ó jẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú,+ gbogbo àwọn aṣáájú ilẹ̀ ayé tí wọ́n jẹ́ oníwà-bí-ewúrẹ́.+ Ó ti mú kí gbogbo ọba àwọn orílẹ̀-èdè dìde lórí ìtẹ́ wọn.+ 10  Gbogbo wọn sọ̀rọ̀ sókè, wọ́n sì wí fún ọ pé, ‘Ṣé a ti sọ ìwọ náà di aláìlera bí tiwa ni?+ Ṣé a ti sọ ọ́ di ẹni tí ó ṣeé fi wé wa ni?+ 11  A ti mú ìyangàn rẹ sọ̀ kalẹ̀ wá sí Ṣìọ́ọ̀lù, ariwo adún-lọ-rére ti àwọn ohun èlò ìkọrin rẹ olókùn tín-ín-rín.+ Lábẹ́ rẹ, ìdin tẹ́ rẹrẹ bí àga ìrọ̀gbọ̀kú; kòkòrò mùkúlú sì ni ìbora rẹ.’+ 12  “Wo bí o ti já bọ́ láti ọ̀run,+ ìwọ ẹni tí ń tàn, ọmọ ọ̀yẹ̀! Wo bí a ti ké ọ lulẹ̀,+ ìwọ tí ń sọ àwọn orílẹ̀-èdè di aláìlágbára!+ 13  Ní tìrẹ, ìwọ ti sọ nínú ọkàn-àyà rẹ pé, ‘Ọ̀run ni èmi yóò gòkè lọ.+ Òkè àwọn ìràwọ̀+ Ọlọ́run ni èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sí,+ èmi yóò sì jókòó sórí òkè ńlá ìpàdé,+ ní àwọn apá jíjìnnàréré jù lọ ní àríwá.+ 14  Èmi yóò gòkè lọ sí àwọn ibi gíga àwọsánmà;+ èmi yóò mú ara mi jọ Ẹni Gíga Jù Lọ.’+ 15  “Bí ó ti wù kí ó rí, Ṣìọ́ọ̀lù ni a óò mú ọ sọ̀ kalẹ̀ wá,+ sí àwọn apá jíjìnnàréré jù lọ nínú kòtò.+ 16  Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjú mọ́ ọ; wọn yóò ṣe àyẹ̀wò rẹ fínnífínní, wọn yóò wí pé, ‘Ṣé ọkùnrin yìí ni ó ń kó ṣìbáṣìbo bá ilẹ̀ ayé, tí ó ń mú kí àwọn ìjọba mì jìgìjìgì,+ 17  tí ó mú kí ilẹ̀ eléso dà bí aginjù, tí ó sì bi ìlú ńlá rẹ̀ pàápàá ṣubú,+ tí kò ṣí ọ̀nà àtilọ sí ilé sílẹ̀ àní fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n rẹ̀?’+ 18  Gbogbo àwọn ọba yòókù ti àwọn orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo wọn, ti dùbúlẹ̀ nínú ògo, olúkúlùkù nínú ilé tirẹ̀.+ 19  Ṣùgbọ́n ní tìrẹ, a ti gbé ọ sọnù láìsí ibi ìsìnkú fún ọ,+ gẹ́gẹ́ bí èéhù tí a ṣe họ́ọ̀ sí, tí a fi àwọn ènìyàn tí a pa bò bí aṣọ, àwọn tí a fi idà gún, tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ bá àwọn òkúta inú kòtò,+ bí òkú tí a tẹ̀ mọ́lẹ̀.+ 20  Ìwọ kì yóò wà ní ìsopọ̀ṣọ̀kan pẹ̀lú wọn nínú sàréè, nítorí pé ìwọ run ilẹ̀ tìrẹ, ìwọ pa àwọn ènìyàn tìrẹ. Fún àkókò tí ó lọ kánrin, a kì yóò dárúkọ ọmọ àwọn aṣebi.+ 21  “Ẹ pèsè búlọ́ọ̀kù ìpẹran sílẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nítorí ìṣìnà àwọn baba ńlá wọn,+ kí wọ́n má bàa dìde, kí wọ́n sì gba ilẹ̀ ayé ní ti tòótọ́, kí wọ́n sì fi àwọn ìlú ńlá kún ojú ilẹ̀ eléso.”+ 22  “Èmi yóò sì dìde sí wọn dájúdájú,”+ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun. “Èmi yóò sì ké orúkọ+ àti àṣẹ́kù àti àtọmọdọ́mọ àti ìran àtẹ̀lé+ kúrò ní Bábílónì,” ni àsọjáde Jèhófà. 23  “Dájúdájú, èmi yóò sọ ọ́ di ohun ìní àwọn òòrẹ̀ àti àwọn adágún omi tí ó kún fún esùsú, èmi yóò sì fi ìgbálẹ̀ ìparẹ́ráúráú gbá a,”+ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun. 24  Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti búra,+ pé: “Dájúdájú, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti gbèrò, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣẹlẹ̀; àti gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pinnu, èyíinì ni yóò ṣẹ,+ 25  kí n lè fọ́ ará Ásíríà náà ní ilẹ̀ mi+ àti pé kí n lè tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá mi;+ àti pé kí àjàgà rẹ̀ lè kúrò lọ́rùn wọn ní ti gidi àti pé kí ẹrù rẹ̀ gan-an lè kúrò ní èjìká wọn.”+ 26  Èyí ni ìpinnu tí a ṣe lòdì sí gbogbo ilẹ̀ ayé, èyí sì ni ọwọ́ tí a nà lòdì sí gbogbo orílẹ̀-èdè. 27  Nítorí pé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tìkára rẹ̀ ti pinnu,+ ta sì ni ó lè sọ ọ́ di asán?+ Ọwọ́ rẹ̀ sì ni èyí tí a nà, ta sì ni ó lè dá a padà?+ 28  Ní ọdún tí Áhásì Ọba kú,+ ọ̀rọ̀ ìkéde yìí wáyé: 29  “Má ṣe yọ̀,+ ìwọ Filísíà,+ ẹnikẹ́ni nínú rẹ, kìkì nítorí pé ọ̀pá ẹni tí ń lù ọ́ ti ṣẹ́.+ Nítorí pé láti inú gbòǹgbò ejò+ ni ejò olóró+ yóò ti jáde wá, èso rẹ̀ yóò sì jẹ́ ejò oníná tí ń fò.+ 30  Ó dájú pé àkọ́bí àwọn ẹni rírẹlẹ̀ yóò jẹun, àwọn òtòṣì alára yóò sì dùbúlẹ̀ nínú ààbò.+ Ìyàn sì ni èmi yóò fi ṣe ikú pa gbòǹgbò rẹ, ohun tí ó bá sì ṣẹ́ kù lára rẹ ni a ó pa.+ 31  Hu, ìwọ ẹnubodè! Ké jáde, ìwọ ìlú ńlá! Gbogbo ọkàn rẹ yóò domi, ìwọ Filísíà! Nítorí èéfín ń bọ̀ láti àríwá, kò sì sí ẹni tí a ó yà sọ́tọ̀ kúrò nínú ọ̀wọ́ ọmọ ogun rẹ̀.”+ 32  Kí sì ni ẹnikẹ́ni yóò sọ láti fi dá àwọn ońṣẹ́+ orílẹ̀-èdè lóhùn? Pé Jèhófà tìkára rẹ̀ ti fi ìpìlẹ̀ Síónì lélẹ̀,+ inú rẹ̀ sì ni àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ lára àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò ti rí ibi ìsádi.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé