Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 13:1-22

13  Ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí Bábílónì,+ èyí tí Aísáyà ọmọkùnrin Émọ́sì+ rí nínú ìran:  “Ẹ gbé àmì àfiyèsí+ sókè lórí òkè ńlá àwọn àpáta dídán borokoto. Ẹ gbé ohùn sókè sí wọn, ẹ ju ọwọ́,+ kí wọ́n lè wá sí ẹnu ọ̀nà àwọn ọ̀tọ̀kùlú.+  Èmi fúnra mi ti pa àṣẹ náà fún àwọn tí mo ti sọ di mímọ́.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, mo ti pe àwọn ẹni alágbára ńlá mi fún fífi ìbínú mi hàn,+ àwọn onítèmi tí ó kún fún ayọ̀ ńláǹlà títayọ.  Fetí sílẹ̀! Ogunlọ́gọ̀ kan ń bẹ ní òkè ńlá, ohun kan tí ó dà bí àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ níye!+ Fetí sílẹ̀! Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ àwọn ìjọba, ti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kóra jọpọ̀!+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ń pe ẹgbẹ́ ọmọ ogun jọ.+  Wọ́n ń bọ̀ láti ilẹ̀ jíjìnnàréré,+ láti ìkángun ọ̀run, Jèhófà àti àwọn ohun ìjà ìdálẹ́bi tí ó ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, láti fọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé bàjẹ́.+  “Ẹ hu,+ nítorí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé!+ Yóò dé gẹ́gẹ́ bí ìfiṣèjẹ láti ọwọ́ Olódùmarè.+  Ìdí nìyẹn tí gbogbo ọwọ́ pàápàá yóò fi rọ jọwọrọ, tí gbogbo ọkàn-àyà ẹni kíkú yóò sì fi domi.+  Ìyọlẹ́nu sì ti bá àwọn ènìyàn.+ Ìsúnkì iṣan àti ìrora ìbímọ ti gbáni mú; wọ́n ní ìrora ìrọbí gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó fẹ́ bímọ.+ Wọ́n ń wo ara wọn pẹ̀lú kàyéfì. Ojú wọn jẹ́ ojú tí a mú gbiná.+  “Wò ó! Àní ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀, ó níkà pẹ̀lú ìbínú kíkan àti pẹ̀lú ìbínú jíjófòfò, láti lè sọ ilẹ̀ náà di ohun ìyàlẹ́nu,+ kí ó sì lè pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ilẹ̀ náà rẹ́ ráúráú kúrò lórí rẹ̀.+ 10  Nítorí pé àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti àwọn àgbájọ ìràwọ̀ Késílì+ wọn pàápàá kì yóò mú kí ìmọ́lẹ̀ wọn kọ mànà; oòrùn yóò ṣókùnkùn nígbà ìjáde lọ rẹ̀ ní ti tòótọ́, òṣùpá pàápàá kì yóò sì mú kí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn. 11  Dájúdájú, èmi yóò mú ìwà búburú tirẹ̀ wọlé wá sórí ilẹ̀ eléso náà,+ àti ìṣìnà tiwọn wá sórí àwọn ẹni burúkú tìkára wọn. Ní ti tòótọ́, èmi yóò mú kí ìgbéraga àwọn oníkùgbù kásẹ̀ nílẹ̀, ìrera àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ sì ni èmi yóò rẹ̀ wálẹ̀.+ 12  Èmi yóò mú kí ẹni kíkú ṣọ̀wọ́n ju wúrà tí a yọ́ mọ́,+ èmi yóò sì mú kí ará ayé ṣọ̀wọ́n ju wúrà Ófírì.+ 13  Ìdí nìyẹn tí èmi yóò fi kó ṣìbáṣìbo bá ọ̀run pàápàá,+ ilẹ̀ ayé yóò sì mì jìgìjìgì kúrò ní ipò rẹ̀ nínú ìbínú kíkan Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun+ àti ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀ jíjófòfò.+ 14  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, bí àgbàlàǹgbó tí a lé lọ àti bí agbo ẹran tí kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò kó wọn jọpọ̀,+ olúkúlùkù wọn yóò yí padà sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tirẹ̀; olúkúlùkù wọn yóò sì sá lọ sí ilẹ̀ tirẹ̀.+ 15  Olúkúlùkù ẹni tí a bá rí ni a óò gún ní àgúnyọ, olúkúlùkù ẹni tí a bá sì mú nínú gbígbálọ náà yóò tipa idà ṣubú;+ 16  àwọn ọmọ wọn gan-an ni a ó sì fọ́ túútúú lójú wọn.+ Ilé wọn ni a óò kó ní ìkógun, aya wọn ni a ó sì fipá bá lò pọ̀.+ 17  “Kíyè sí i, èmi yóò gbé àwọn ará Mídíà dìde sí wọn,+ àwọn tí kò ka fàdákà pàápàá sí nǹkan kan, àwọn tí ó sì jẹ́ pé, ní ti wúrà, wọn kò ní inú dídùn sí i. 18  Ọrun wọn yóò sì fọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin túútúú.+ Wọn kì yóò sì ṣe ojú àánú sí èso ikùn;+ ojú wọn kì yóò káàánú àwọn ọmọ. 19  Bábílónì, ìṣelóge àwọn ìjọba,+ ẹwà ìyangàn àwọn ará Kálídíà,+ yóò sì dà bí ìgbà tí Ọlọ́run bi Sódómù àti Gòmórà ṣubú.+ 20  A kì yóò gbé inú rẹ̀ mọ́ láé,+ bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí mọ́ láti ìran dé ìran.+ Àwọn ará Arébíà kì yóò sì pàgọ́ sí ibẹ̀, àwọn olùṣọ́ àgùntàn kì yóò sì jẹ́ kí agbo ẹran wọn dùbúlẹ̀ sí ibẹ̀. 21  Ibẹ̀ sì ni àwọn olùgbé àwọn ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò dùbúlẹ̀ sí dájúdájú, ilé wọn yóò sì kún fún àwọn òwìwí idì.+ Ibẹ̀ sì ni àwọn ògòǹgò yóò máa gbé, àwọn ẹ̀mí èṣù onírìísí ewúrẹ́ pàápàá yóò sì máa tọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri níbẹ̀.+ 22  Àwọn akátá yóò sì máa hu nínú àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ̀,+ ejò ńlá yóò sì wà nínú àwọn ààfin inú dídùn kíkọyọyọ. Àsìkò rẹ̀ sì ti sún mọ́lé, a kì yóò sì sún àwọn ọjọ́ rẹ̀ pàápàá síwájú.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé