Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 12:1-6

12  Ó sì dájú pé ìwọ yóò sọ ní ọjọ́ yẹn+ pé: “Èmi yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Jèhófà, nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbínú rẹ ru sí mi, ìbínú rẹ yí padà+ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, o sì bẹ̀rẹ̀ sí tù mí nínú.+  Wò ó! Ọlọ́run ni ìgbàlà mi.+ Èmi yóò ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìbẹ̀rùbojo kankan kì yóò sì bá mi;+ nítorí pé Jáà Jèhófà ni okun mi+ àti agbára ńlá mi,+ òun sì wá ni ìgbàlà mi.”+  Ó dájú pé ayọ̀ ńláǹlà ni ẹ ó fi fa omi láti inú àwọn ìsun ìgbàlà.+  Dájúdájú, ẹ ó sọ ní ọjọ́ yẹn pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà!+ Ẹ ké pe orúkọ rẹ̀.+ Ẹ sọ àwọn ìbánilò rẹ̀ di mímọ̀ láàárín àwọn ènìyàn.+ Ẹ mẹ́nu kàn án pé orúkọ rẹ̀ ni a gbé ga.+  Ẹ kọ orin atunilára sí Jèhófà,+ nítorí pé ó ti ṣe ohun tí ó ta yọ ré kọjá.+ Èyí ni a sọ di mímọ̀ ní gbogbo ilẹ̀ ayé.  “Ké jáde lọ́nà híhan gan-an-ran, kí o sì ké fún ìdùnnú, ìwọ obìnrin olùgbé Síónì, nítorí pé títóbi ni Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì+ láàárín rẹ.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé