Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 1:1-31

1  Ìran+ Aísáyà+ ọmọkùnrin Émọ́sì, èyí tí ó rí nípa Júdà àti Jerúsálẹ́mù ní àwọn ọjọ́ Ùsáyà,+ Jótámù,+ Áhásì+ àti Hesekáyà,+ àwọn ọba Júdà:+  Ẹ gbọ́,+ ẹ̀yin ọ̀run, sì fi etí sílẹ̀, ìwọ ilẹ̀ ayé, nítorí Jèhófà tìkára rẹ̀ ti sọ pé: “Èmi ti tọ́ àwọn ọmọ, mo sì ti tọ́jú wọn dàgbà,+ ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn ti dìtẹ̀ sí mi.+  Akọ màlúù mọ ẹni tí ó ra òun dunjú, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ ẹran olúwa òun; Ísírẹ́lì alára kò mọ̀,+ àwọn ènìyàn mi kò hùwà lọ́nà òye.”+  Ègbé ni fún orílẹ̀-èdè tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀,+ àwọn ènìyàn tí ìṣìnà ti wọ̀ lọ́rùn, irú-ọmọ tí ń ṣebi,+ àwọn apanirun ọmọ!+ Wọ́n ti fi Jèhófà sílẹ̀,+ wọ́n ti hùwà àìlọ́wọ̀+ sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, wọ́n ti yí padà sẹ́yìn.+  Ibo ni ó tún kù tí a ó ti lù yín,+ ní ti pé ẹ túbọ̀ ń dìtẹ̀ sí i?+ Gbogbo orí wà ní ipò àìsàn, gbogbo ọkàn-àyà sì jẹ́ ahẹrẹpẹ.+  Láti àtẹ́lẹsẹ̀ àní dé orí, kò sí ibì kankan nínú rẹ̀ tí ó dá ṣáṣá.+ Àwọn ọgbẹ́ àti ara bíbó àti ojú ibi tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ nà—a kò mọ́ wọn tàbí kí a dì wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi òróró tù wọ́n lójú.+  Ilẹ̀ yín jẹ́ ahoro,+ a fi iná sun àwọn ìlú ńlá yín;+ ilẹ̀ yín—àwọn àjèjì+ ń jẹ ẹ́+ ní iwájú yín gan-an, ahoro náà sì dà bí ìbìṣubú láti ọwọ́ àwọn àjèjì.+  Ọmọbìnrin Síónì+ ni a sì fi sílẹ̀ bí àtíbàbà inú ọgbà àjàrà, bí ahéré alóre inú àwọn pápá apálá, bí ìlú ńlá tí a sénà rẹ̀.+  Bí kò ṣe pé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ṣẹ́ kìkì àwọn olùlàájá díẹ̀ kù sílẹ̀ fún wa,+ àwa ì bá ti dà bí Sódómù gan-an, à bá ti jọ Gòmórà pàápàá.+ 10  Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà,+ ẹ̀yin apàṣẹwàá+ Sódómù.+ Ẹ fi etí sí òfin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn Gòmórà. 11  “Àǹfààní kí ni ògìdìgbó àwọn ẹbọ yín jẹ́ fún mi?” ni Jèhófà wí. “Odindi ọrẹ ẹbọ sísun+ ti àgbò+ àti ọ̀rá àwọn ẹran tí a bọ́ dáadáa+ ti tó mi gẹ́ẹ́; èmi kò sì ní inú dídùn+ sí ẹ̀jẹ̀+ àwọn ẹgbọrọ akọ màlúù àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn àti òbúkọ.+ 12  Nígbà tí ẹ ń wọlé wá láti rí ojú mi,+ ta ni ó béèrè èyí lọ́wọ́ yín, láti máa tẹ àgbàlá mi?+ 13  Ẹ ṣíwọ́ mímú àwọn ọrẹ ẹbọ ọkà tí kò ní láárí wá.+ Tùràrí—ó jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí fún mi.+ Òṣùpá tuntun+ àti sábáàtì,+ pípe àpéjọpọ̀+—èmi kò lè fara da lílo agbára abàmì+ pa pọ̀ pẹ̀lú àpéjọ ọ̀wọ̀. 14  Ọkàn mi kórìíra àwọn òṣùpá tuntun yín àti àwọn àkókò àjọyọ̀ yín.+ Wọ́n ti di ẹrù ìnira fún mi;+ rírù wọ́n ti sú mi.+ 15  Nígbà tí ẹ bá sì tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ yín,+ èmi yóò fi ojú mi pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ yín.+ Bí ẹ tilẹ̀ gba àdúrà púpọ̀,+ èmi kò ní fetí sílẹ̀;+ àní ọwọ́ yín kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀.+ 16  Ẹ wẹ̀;+ ẹ jẹ́ kí ara yín mọ́;+ ẹ mú búburú ìbánilò yín kúrò ní iwájú mi;+ ẹ ṣíwọ́ ṣíṣe búburú.+ 17  Ẹ kọ́ ṣíṣe rere;+ ẹ wá ìdájọ́ òdodo;+ ẹ tún ojú ìwòye aninilára ṣe;+ ẹ ṣe ìdájọ́ ọmọdékùnrin aláìníbaba;+ ẹ gba ẹjọ́ opó rò.”+ 18  “Ẹ wá, nísinsìnyí, ẹ sì jẹ́ kí a mú àwọn ọ̀ràn tọ́ láàárín wa,” ni Jèhófà wí.+ “Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò, a ó sọ wọ́n di funfun gẹ́gẹ́ bí ìrì dídì;+ bí wọ́n tilẹ̀ pupa bí aṣọ pípọ́ndòdò, wọn yóò dà bí irun àgùntàn gẹ́lẹ́. 19  Bí ẹ bá fi ẹ̀mí ìmúratán hàn, tí ẹ sì fetí sílẹ̀, ẹ ó jẹ ohun rere ilẹ̀ náà.+ 20  Ṣùgbọ́n bí ẹ bá kọ̀,+ tí ẹ sì jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ní ti gidi, idà ni a ó fi jẹ yín run; nítorí pé ẹnu Jèhófà gan-an ti sọ ọ́.”+ 21  Ẹ wo bí ìlú ìṣòtítọ́+ ti di kárùwà!+ Ó kún fún ìdájọ́ òdodo rí;+ òdodo ti máa ń wọ̀ sí inú rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí,+ ṣùgbọ́n nísinsìnyí ó kún fún àwọn òṣìkàpànìyàn.+ 22  Fàdákà rẹ pàápàá ti di ìdàrọ́.+ A ti fi omi ṣe àdàlù ọtí bíà àlìkámà rẹ.+ 23  Àwọn ọmọ aládé rẹ jẹ́ alágídí àti alájọṣe pẹ̀lú àwọn olè.+ Gbogbo wọn jẹ́ olùfẹ́ àbẹ̀tẹ́lẹ̀+ àti olùlépa àwọn ẹ̀bùn.+ Wọn kì í ṣe ìdájọ́ ọmọdékùnrin aláìníbaba; ẹjọ́ opó pàápàá ni wọn kì í sì í gbà wọlé.+ 24  Nítorí náà, àsọjáde Olúwa tòótọ́, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ẹni Alágbára Ísírẹ́lì,+ ni pé: “Àháà! Èmi yóò mú ìtura bá ara mi kúrò lọ́wọ́ àwọn elénìní mi, dájúdájú, èmi yóò gbẹ̀san+ ara mi lára àwọn ọ̀tá mi.+ 25  Ṣe ni èmi yóò sì yí ọwọ́ mi padà sára rẹ, èmi yóò sì yọ́ ìdàrọ́ rẹ dànù bí ẹni pé pẹ̀lú ọṣẹ ìfọṣọ, èmi yóò sì mú gbogbo ohun ìdọ̀tí rẹ kúrò.+ 26  Èmi yóò sì tún mú àwọn onídàájọ́ padà wá fún ọ gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà àkọ́kọ́, àti àwọn agbani-nímọ̀ràn wá fún ọ gẹ́gẹ́ bí ti ìbẹ̀rẹ̀.+ Lẹ́yìn èyí, a óò máa pè ọ́ ní Ìlú Ńlá Òdodo, Ìlú Ìṣòtítọ́.+ 27  Ìdájọ́ òdodo ni a ó fi tún Síónì fúnra rẹ̀ rà padà,+ a ó sì fi òdodo+ ṣe ìràpadà àwọn tí ń padà bọ̀ lára àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀. 28  Ìfọ́yángá àwọn adìtẹ̀ àti ti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò sì jẹ́ lẹ́ẹ̀kan náà,+ àwọn tí ó fi Jèhófà sílẹ̀ yóò sì wá sí òpin wọn.+ 29  Nítorí ìtìjú yóò bá wọn ní ti àwọn igi ràbàtà tí ojú yín wọ̀,+ ẹ ó sì tẹ́ nítorí àwọn ọgbà tí ẹ ti yàn.+ 30  Nítorí ẹ ó dà bí igi ńlá tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé ti ń rọ,+ àti bí ọgbà tí kò ní omi. 31  Dájúdájú, ọkùnrin tí ó ní okun inú yóò di èétú okùn,+ àmújáde ìgbòkègbodò rẹ̀ yóò sì di ìtapàrà kan; dájúdájú, àwọn méjèèjì yóò jóná lẹ́ẹ̀kan náà, láìsí ẹnì kankan tí yóò pa iná náà.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé