Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

3 Jòhánù 1:1-14

 Àgbà ọkùnrin+ sí Gáyọ́sì, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo nífẹ̀ẹ́ ní tòótọ́.+  Olùfẹ́ ọ̀wọ́n,+ mo gbàdúrà pé nínú ohun gbogbo kí ìwọ lè máa láásìkí,+ kí o sì máa ní ìlera,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ọkàn rẹ ti ń láásìkí.+  Nítorí mo yọ̀ gidigidi nígbà tí àwọn ará dé, tí wọ́n sì jẹ́rìí sí òtítọ́ tí ìwọ dì mú, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.+  Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.+  Olùfẹ́ ọ̀wọ́n, iṣẹ́ ìṣòtítọ́ ni ìwọ ń ṣe nínú ohun yòówù tí ìwọ ń ṣe fún àwọn ará,+ pẹ̀lúpẹ̀lù bí wọ́n ti jẹ́ àjèjì,+  àwọn tí ó ti jẹ́rìí sí ìfẹ́ rẹ níwájú ìjọ. Àwọn wọ̀nyí ni kí o jọ̀wọ́ rán lọ ní ọ̀nà wọn lọ́nà tí ó yẹ Ọlọ́run.+  Nítorí pé tìtorí orúkọ rẹ̀ ni wọ́n ṣe jáde lọ, láìgba ohunkóhun+ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè.  Nítorí náà, a wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti gba irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò,+ kí a lè di alábàáṣiṣẹ́pọ̀ nínú òtítọ́.+  Mo kọ̀wé ohun kan sí ìjọ, ṣùgbọ́n Dìótíréfè, ẹni tí ń fẹ́ láti gba ipò àkọ́kọ́+ láàárín wọn, kò fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀+ gba ohunkóhun+ láti ọ̀dọ̀ wa. 10  Ìdí nìyẹn, bí mo bá dé, tí èmi yóò fi rántí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ń bá a lọ ní ṣíṣe,+ tí ó ń fi àwọn ọ̀rọ̀ burúkú wírèégbè nípa wa.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí kò ti ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ gba àwọn ará,+ àwọn tí ó sì ń fẹ́ láti gbà+ wọ́n ni ó ń gbìyànjú láti dí lọ́wọ́+ àti láti tì jáde+ kúrò nínú ìjọ. 11  Olùfẹ́ ọ̀wọ́n, má ṣe jẹ́ aláfarawé ohun búburú, bí kò ṣe ohun rere.+ Ẹni tí ó bá ń ṣe rere pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+ Ẹni tí ó bá ń ṣe búburú kò tíì rí Ọlọ́run.+ 12  Dímẹ́tíríù ti ní ẹ̀rí tí a jẹ́ sí i láti ọ̀dọ̀ gbogbo wọn+ àti nípasẹ̀ òtítọ́ pàápàá. Ní ti tòótọ́, àwa, pẹ̀lú, ń jẹ́rìí,+ ìwọ sì mọ̀ pé òótọ́ ni ẹ̀rí tí àwa ń jẹ́.+ 13  Mo ní ohun púpọ̀ láti kọ̀wé rẹ̀ sí ọ, síbẹ̀ èmi kò fẹ́ láti máa bá a lọ ní fífi yíǹkì àti gègé kọ̀wé sí ọ.+ 14  Ṣùgbọ́n mo ní ìrètí láti rí ọ ní tààràtà, a ó sì sọ̀rọ̀ ní ojúkojú.+ Àlàáfíà fún ọ.+ Àwọn ọ̀rẹ́ kí+ ọ. Bá mi kí+ àwọn ọ̀rẹ́ ní orúkọ-orúkọ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé