Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Tẹsalóníkà 3:1-18

3  Lákòótán, ẹ̀yin ará, ẹ máa bá a lọ ní gbígbàdúrà fún wa,+ kí ọ̀rọ̀ Jehofa+ lè máa sáré tete,+ kí a sì máa ṣe é lógo gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti rí pẹ̀lú yín ní tòótọ́;  kí a sì lè dá wa nídè lọ́wọ́ àwọn apanilára àti ènìyàn burúkú,+ nítorí ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo ènìyàn.+  Ṣùgbọ́n olùṣòtítọ́ ni Olúwa, yóò sì fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in, yóò sì pa yín mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.+  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwa ní ìgbọ́kànlé+ nínú Olúwa nípa yín, pé ẹ ń ṣe àwọn ohun tí a pa láṣẹ, ẹ ó sì máa bá a lọ ní ṣíṣe wọ́n.+  Kí Olúwa máa bá a lọ ní fífi àṣeyọrí sí rere darí ọkàn-àyà yín sínú ìfẹ́+ fún Ọlọ́run àti sínú ìfaradà+ fún Kristi.  Wàyí o, a ń pa àṣẹ ìtọ́ni+ fún yín, ẹ̀yin ará, ní orúkọ Jésù Kristi Olúwa, pé kí ẹ fà sẹ́yìn+ kúrò lọ́dọ̀ olúkúlùkù arákùnrin tí ń rìn ségesège,+ tí kì í sì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú àṣà àfilénilọ́wọ́ tí ẹ gbà láti ọ̀dọ̀ wa.+  Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí ẹ gbà fara wé wa,+ nítorí pé àwa kò hùwà lọ́nà ségesège láàárín yín,+  bẹ́ẹ̀ ni a kò jẹ oúnjẹ lọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, nípa òpò àti làálàá+ ní òru àti ní ọ̀sán, a ń ṣiṣẹ́ kí a má bàa gbé ẹrù ìnira tí ń wọni lọ́rùn ka ẹnikẹ́ni nínú yín.+  Kì í ṣe pé a kò ní ọlá àṣẹ,+ ṣùgbọ́n nítorí kí a lè fi ara wa lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ fún yín láti fara wé wa.+ 10  Ní ti tòótọ́, pẹ̀lú, nígbà tí a wà pẹ̀lú yín, a ti máa ń pa àṣẹ ìtọ́ni yìí+ fún yín pé: “Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.”+ 11  Nítorí a gbọ́ pé àwọn kan ń rìn ségesège+ láàárín yín, láìṣiṣẹ́ rárá ṣùgbọ́n tí wọ́n ń tojú bọ ohun tí kò kàn wọ́n.+ 12  Irúfẹ́ àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni a pa àṣẹ ìtọ́ni fún, tí a sì fún ní ọ̀rọ̀ ìyànjú nínú Jésù Kristi Olúwa pé nípa ṣíṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, kí wọ́n máa jẹ oúnjẹ tí àwọn fúnra wọn ṣiṣẹ́ fún.+ 13  Ní tiyín, ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́.+ 14  Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá jẹ́ onígbọràn sí ọ̀rọ̀+ wa nípasẹ̀ lẹ́tà yìí, ẹ sàmì+ sí ẹni yìí, ẹ dẹ́kun bíbá a kẹ́gbẹ́,+ kí ojú lè tì í.+ 15  Síbẹ̀, ẹ má kà á sí ọ̀tá, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní ṣíṣí i létí+ gẹ́gẹ́ bí arákùnrin. 16  Wàyí o, kí Olúwa àlàáfíà fúnra rẹ̀ fún yín ní àlàáfíà nígbà gbogbo ní gbogbo ọ̀nà.+ Kí Olúwa wà pẹ̀lú gbogbo yín. 17  Ìkíni ti èmi Pọ́ọ̀lù nìyí, ní ọwọ́ ara mi,+ èyí tí ó jẹ́ àmì nínú gbogbo lẹ́tà; èyí ni ọ̀nà tí mo gbà ń kọ̀wé. 18  Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ Olúwa wa Jésù Kristi wà pẹ̀lú gbogbo yín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé