Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Tẹsalóníkà 2:1-17

2  Àmọ́ ṣá o, ẹ̀yin ará, nípa wíwàníhìn-ín+ Olúwa wa Jésù Kristi àti kíkó wa jọpọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀,+ àwa béèrè lọ́wọ́ yín  kí ẹ má ṣe tètè mì kúrò nínú ìmọnúúrò yín tàbí kí a ru yín sókè yálà nípasẹ̀ àgbéjáde onímìísí+ tàbí nípasẹ̀ ìhìn iṣẹ́ àfẹnusọ+ tàbí nípasẹ̀ lẹ́tà+ kan bí ẹni pé láti ọ̀dọ̀ wa, tí ń wí pé ọjọ́+ Jèhófà ti dé.  Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan sún yín dẹ́ṣẹ̀ lọ́nà èyíkéyìí, nítorí kì yóò dé láìjẹ́ pé ìpẹ̀yìndà+ kọ́kọ́ dé, tí a sì ṣí ọkùnrin oníwà àìlófin+ payá,+ ọmọ ìparun.+  Ó ti gbára dì nínú ìṣòdìsíni,+ ó sì gbé ara rẹ̀ sókè sórí gbogbo ẹni tí a ń pè ní “ọlọ́run” tàbí ohun tí a ń fún ní ọ̀wọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jókòó nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run Náà, tí ó ń fi ara rẹ̀ hàn ní gbangba pé òun jẹ́ ọlọ́run kan.+  Ẹ kò ha rántí pé, nígbà tí mo ṣì wà pẹ̀lú yín, mo máa ń sọ+ nǹkan wọ̀nyí fún yín?  Àti nítorí náà nísinsìnyí ẹ mọ ohun+ tí ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣèdíwọ́,+ pé kí a lè ṣí i payá ní àkókò tirẹ̀ yíyẹ.+  Lóòótọ́, ohun ìjìnlẹ̀ ìwà àìlófin yìí ti wà lẹ́nu iṣẹ́ nísinsìnyí;+ ṣùgbọ́n kìkì títí di ìgbà tí ẹni tí ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣèdíwọ́ nísinsìnyí gan-an bá kúrò lójú ọ̀nà.+  Ní tòótọ́, nígbà náà ni a óò ṣí aláìlófin náà payá, ẹni tí Jésù Olúwa yóò fi ẹ̀mí ẹnu+ rẹ̀ pa, tí yóò sì sọ di asán nípasẹ̀ ìfarahàn+ wíwàníhìn-ín+ rẹ̀.  Ṣùgbọ́n wíwàníhìn-ín aláìlófin náà jẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìṣiṣẹ́+ Sátánì pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ agbára àti àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn àmì àgbàyanu irọ́+ 10  àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀tàn+ àìṣòdodo fún àwọn tí ń ṣègbé,+ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san iṣẹ́ nítorí pé wọn kò tẹ́wọ́ gba ìfẹ́+ òtítọ́ kí a bàa lè gbà wọ́n là.+ 11  Nítorí náà, ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí ìṣiṣẹ́ ìṣìnà tọ̀ wọ́n lọ, kí wọ́n bàa lè gba irọ́ gbọ́,+ 12  kí a bàa lè dá gbogbo wọn lẹ́jọ́ nítorí tí wọn kò gba òtítọ́+ gbọ́ ṣùgbọ́n wọ́n ní ìdùnnú nínú àìṣòdodo.+ 13  Àmọ́ ṣá o, di dandan fún wa láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ẹ̀yin ará tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́, nítorí pé Ọlọ́run yàn yín+ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ fún ìgbàlà nípa fífi ẹ̀mí+ sọ yín di mímọ́+ àti nípa ìgbàgbọ́ yín nínú òtítọ́.+ 14  Ìpín yìí gan-an ni òun pè yín sí nípasẹ̀ ìhìn rere tí àwa ń polongo,+ fún ète gbígba ògo Olúwa wa Jésù Kristi.+ 15  Nítorí bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ará, ẹ dúró gbọn-in gbọn-in,+ kí ẹ sì di àwọn àṣà àfilénilọ́wọ́+ tí a kọ́ yín mú láìjáwọ́, yálà ó jẹ́ nípasẹ̀ ìhìn iṣẹ́ àfẹnusọ tàbí nípasẹ̀ lẹ́tà wa. 16  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí Olúwa wa Jésù Kristi fúnra rẹ̀ àti Baba wa Ọlọ́run, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́+ wa, tí ó sì fúnni ní ìtùnú àìnípẹ̀kun àti ìrètí+ rere nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, 17  tu ọkàn-àyà yín nínú, kí ó sì fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo iṣẹ́ rere àti ọ̀rọ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé