Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Tẹsalóníkà 1:1-12

1  Pọ́ọ̀lù àti Sílífánù àti Tímótì+ sí ìjọ àwọn ará Tẹsalóníkà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Baba wa Ọlọ́run àti Jésù Kristi Olúwa:  Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jésù Kristi Olúwa.+  Ó di dandan fún wa láti fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín,+ ẹ̀yin ará, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, nítorí ìgbàgbọ́ yín ń gbèrú+ lọ́nà tí ó peléke, ìfẹ́ yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀ sì ń pọ̀ sí i lẹ́nì kìíní sí ẹnì kejì.+  Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí èyí, àwa fúnra wa ń fi yín yangàn+ láàárín àwọn ìjọ Ọlọ́run nítorí ìfaradà àti ìgbàgbọ́ yín nínú gbogbo inúnibíni yín àti àwọn ìpọ́njú tí ẹ ń mú mọ́ra.+  Èyí jẹ́ ẹ̀rí ìdánilójú ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run,+ tí ń ṣamọ̀nà sí kíkà yín yẹ fún ìjọba Ọlọ́run,+ èyí tí ẹ ń jìyà fún ní tòótọ́.+  Èyí jẹ́ nítorí pé ó jẹ́ òdodo níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti san ìpọ́njú padà fún àwọn tí ń pọ́n yín lójú,+  ṣùgbọ́n, fún ẹ̀yin tí ń ní ìpọ́njú, ìtura pa pọ̀ pẹ̀lú wa nígbà ìṣípayá+ Jésù Olúwa láti ọ̀run tòun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára+  nínú iná tí ń jó fòfò, bí ó tí ń mú ẹ̀san+ wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run+ àti àwọn tí kò ṣègbọràn+ sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.+  Àwọn wọ̀nyí gan-an yóò fara gba ìyà+ ìdájọ́ ìparun àìnípẹ̀kun+ láti iwájú Olúwa àti láti inú ògo okun rẹ̀,+ 10  ní àkókò tí òun bá dé láti di àyìnlógo ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́+ rẹ̀, tí a ó sì bojú wò ó ní ọjọ́ yẹn pẹ̀lú kàyéfì ní ìsopọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí wọ́n lo ìgbàgbọ́, nítorí ẹ̀rí tí a jẹ́ bá ìgbàgbọ́ pàdé láàárín yín. 11  Ní tòótọ́, fún ète yẹn gan-an ni àwa fi ń gbàdúrà nígbà gbogbo nítorí yín, pé kí Ọlọ́run wa lè kà yín yẹ fún ìpè+ rẹ̀, kí ó sì ṣe àṣepé gbogbo ohun tí ó wù ú nínú oore àti iṣẹ́ ìgbàgbọ́ pẹ̀lú agbára; 12  kí a lè yin orúkọ Olúwa wa Jésù lógo nínú yín,+ àti ẹ̀yin ní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ Ọlọ́run wa àti ti Jésù Kristi Olúwa.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé