Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Tímótì 4:1-22

4  Mo pàṣẹ fún ọ lọ́nà tí ó wúwo rinlẹ̀ níwájú Ọlọ́run àti Kristi Jésù, ẹni tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣèdájọ́+ àwọn alààyè àti òkú,+ àti nípasẹ̀ ìfarahàn+ rẹ̀ àti ìjọba+ rẹ̀,  wàásù ọ̀rọ̀ náà,+ wà lẹ́nu rẹ̀ ní kánjúkánjú ní àsìkò tí ó rọgbọ,+ ní àsìkò tí ó kún fún ìdààmú,+ fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà,+ báni wí kíkankíkan, gbani níyànjú, pẹ̀lú gbogbo ìpamọ́ra+ àti ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.  Nítorí sáà àkókò kan yóò wà, tí wọn kò ní gba ẹ̀kọ́ afúnni-nílera,+ ṣùgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn, wọn yóò kó àwọn olùkọ́ jọ fún ara wọn láti máa rìn wọ́n ní etí;+  wọn yóò sì yí etí wọn kúrò nínú òtítọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé a óò mú wọn yà sínú ìtàn èké.+  Àmọ́ ṣá o, ìwọ, máa pa agbára ìmòye+ rẹ mọ́ nínú ohun gbogbo, jìyà ibi,+ ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere,+ ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́+ rẹ ní kíkún.  Nítorí a ti ń tú mi jáde báyìí bí ọrẹ ẹbọ ohun mímu,+ àkókò yíyẹ fún títú mi sílẹ̀+ sì kù sí dẹ̀dẹ̀.  Mo ti ja ìjà àtàtà náà,+ mo ti sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí,+ mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́.+  Láti àkókò yìí lọ, a ti fi adé òdodo+ pa mọ́ dè mí, èyí tí Olúwa, onídàájọ́+ òdodo, yóò fi san mí lẹ́san+ ní ọjọ́ yẹn,+ síbẹ̀ kì í ṣe fún èmi nìkan, ṣùgbọ́n fún gbogbo àwọn tí ó ti nífẹ̀ẹ́ ìfarahàn rẹ̀ pẹ̀lú.  Sa gbogbo ipá rẹ láti wá sọ́dọ̀ mi láìpẹ́.+ 10  Nítorí Démà+ ti ṣá mi tì nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ ètò+ àwọn nǹkan ìsinsìnyí, ó sì ti lọ sí Tẹsalóníkà; Kírẹ́sẹ́ńsì sí Gálátíà,+ Títù sí Damatíà. 11  Lúùkù nìkan ṣoṣo ni ó wà pẹ̀lú mi. Mú Máàkù, kí o sì mú un wá pẹ̀lú rẹ, nítorí ó wúlò+ fún mi fún iṣẹ́ ìránṣẹ́. 12  Ṣùgbọ́n mo ti rán Tíkíkù+ lọ sí Éfésù. 13  Nígbà tí o bá ń bọ̀, mú aṣọ ìlékè tí mo fi sílẹ̀ ní Tíróásì+ lọ́dọ̀ Kápọ́sì wá, àti àwọn àkájọ ìwé, ní pàtàkì àwọn ìwé awọ. 14  Alẹkisáńdà+ alágbẹ̀dẹ bàbà ṣe mí ní èṣe púpọ̀—Jèhófà yóò san án padà fún un gẹ́gẹ́ bí àwọn iṣẹ́ rẹ̀+ 15  kí ìwọ pẹ̀lú sì máa ṣọ́ra fún un, nítorí tí ó tako àwọn ọ̀rọ̀ wa dé ìwọ̀n tí ó pọ̀ lápọ̀jù. 16  Nínú ìgbèjà mi àkọ́kọ́, kò sí ẹnì kankan tí ó wá síhà ọ̀dọ̀ mi, ṣùgbọ́n gbogbo wọn ṣá mi tì+—kí ó má ṣe di kíkà sí wọn lọ́rùn+ 17  ṣùgbọ́n Olúwa dúró lẹ́bàá mi,+ ó sì fi agbára sínú mi,+ pé nípasẹ̀ mi, kí a lè ṣàṣeparí ìwàásù náà ní kíkún àti kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè lè gbọ́ ọ;+ a sì dá mi nídè kúrò lẹ́nu kìnnìún.+ 18  Olúwa yóò dá mi nídè lọ́wọ́ gbogbo iṣẹ́ burúkú,+ yóò sì gbà mí là fún ìjọba rẹ̀ ti ọ̀run.+ Òun ni kí ògo jẹ́ tirẹ̀ títí láé àti láéláé. Àmín. 19  Bá mi kí Pírísíkà+ àti Ákúílà àti agbo ilé Ónẹ́sífórù.+ 20  Érásítù+ dúró ní Kọ́ríńtì,+ ṣùgbọ́n mo fi Tírófímù+ sílẹ̀ nínú àìsàn ní Mílétù.+ 21  Sa gbogbo ipá rẹ láti dé ṣáájú ìgbà òtútù. Yúbúlọ́sì kí ọ, Púdéńsì àti Línúsì àti Kíláúdíà àti gbogbo àwọn ará ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. 22  Kí Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí o fi hàn.+ Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ wà pẹ̀lú yín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé