Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Tímótì 3:1-17

3  Ṣùgbọ́n mọ èyí, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,+ àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín.+  Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí,+ aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin,+  aláìní ìfẹ́ni àdánidá,+ aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan,+ afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́,+ aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò,+ aláìní ìfẹ́ ohun rere,+  afinihàn,+ olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga,+ olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run,+  àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run+ ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀;+ yà kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.+  Nítorí láti inú àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin ti ń dìde tí wọ́n ń fi ọgbọ́n wẹ́wẹ́ yọ́ wọnú àwọn agbo ilé,+ tí wọ́n sì ń mú lọ gẹ́gẹ́ bí òǹdè wọn, àwọn aláìlera obìnrin tí ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀ lọ́rùn, tí onírúurú ìfẹ́-ọkàn ń ṣamọ̀nà,+  wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ nígbà gbogbo, síbẹ̀ wọn kò lè dé ojú ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ láé.+  Nísinsìnyí, lọ́nà tí Jánésì àti Jáńbérì+ gbà takò Mósè, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn wọ̀nyí ṣe ń bá a lọ ní títako òtítọ́,+ àwọn ènìyàn tí ó ti dìbàjẹ́ pátápátá nínú èrò inú wọn,+ tí a kò tẹ́wọ́ gbà ní ti ìgbàgbọ́.+  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, wọn kì yóò ní ìtẹ̀síwájú kankan sí i, nítorí tí ìṣiwèrè wọn yóò ṣe kedere gan-an sí gbogbo ènìyàn, àní bí ìṣiwèrè ọkùnrin méjì wọnnì ti ṣe.+ 10  Ṣùgbọ́n ìwọ ti tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ mi pẹ́kípẹ́kí, ipa ọ̀nà ìgbésí ayé mi,+ ète mi, ìgbàgbọ́ mi, ìpamọ́ra mi, ìfẹ́ mi, ìfaradà mi, 11  àwọn inúnibíni mi, àwọn ìjìyà mi, irú àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi ní Áńtíókù,+ ní Íkóníónì,+ ní Lísírà,+ irú àwọn inúnibíni tí mo ti mú mọ́ra; síbẹ̀, Olúwa dá mi nídè nínú gbogbo wọn.+ 12  Ní ti tòótọ́, gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.+ 13  Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù, wọn yóò máa ṣini lọ́nà, a ó sì máa ṣi àwọn pẹ̀lú lọ́nà.+ 14  Àmọ́ ṣá o, ìwọ, máa bá a lọ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́, tí a sì ti yí ọ lérò padà láti gbà gbọ́,+ ní mímọ ọ̀dọ̀ àwọn tí o ti kọ́ wọn+ 15  àti pé láti ìgbà ọmọdé jòjòló+ ni ìwọ ti mọ ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà+ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.+ 16  Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí,+ ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni,+ fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà,+ fún mímú àwọn nǹkan tọ́,+ fún bíbániwí+ nínú òdodo, 17  kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún,+ tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé