Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Tímótì 2:1-26

2  Nítorí náà, ìwọ, ọmọ mi,+ máa bá a nìṣó ní gbígba agbára+ nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ tí ó wà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù,  àwọn nǹkan tí ìwọ sì ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi pẹ̀lú ìtìlẹyìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹlẹ́rìí,+ nǹkan wọ̀nyí ni kí o fi lé àwọn olùṣòtítọ́ lọ́wọ́, tí àwọn, ẹ̀wẹ̀, yóò tóótun tẹ́rùntẹ́rùn láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn.+  Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun+ àtàtà ti Kristi Jésù, kó ipa tìrẹ nínú jíjìyà ibi.+  Kò sí ènìyàn tí ń sìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun+ tí ń kó wọnú àwọn iṣẹ́ òwò ìgbésí ayé,+ kí ó bàa lè jèrè ìtẹ́wọ́gbà ẹni tí ó gbà á síṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun.  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ẹnì kan bá wọ̀jà nínú àwọn eré pàápàá,+ a kì í dé e ládé láìjẹ́ pé ó wọ̀jà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà àfilélẹ̀.  Àgbẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ kára ni ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ jẹ nínú àwọn èso.+  Máa ronú nígbà gbogbo lórí ohun ti mo ń wí; Olúwa yóò fún ọ ní ìfòyemọ̀+ ní ti gidi nínú ohun gbogbo.  Rántí pé a gbé Jésù Kristi dìde kúrò nínú òkú+ àti pé irú-ọmọ Dáfídì+ ni òun jẹ́, ní ìbámu pẹ̀lú ìhìn rere tí mo ń wàásù;+  èyí tí mo ń tìtorí rẹ̀ jìyà ibi gẹ́gẹ́ bí àṣebi títí dé orí àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n.+ Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a kò de ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.+ 10  Ní tìtorí èyí, mo ń bá a lọ ní fífarada ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́,+ kí àwọn pẹ̀lú lè rí ìgbàlà tí ó wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù gbà pa pọ̀ pẹ̀lú ògo àìnípẹ̀kun.+ 11  Àsọjáde náà ṣeé gbíyè lé:+ Ó dájú pé bí a bá jọ kú, a ó jọ wà láàyè pẹ̀lú;+ 12  bí a bá ń bá a lọ ní fífaradà, a ó jọ ṣàkóso pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí ọba;+ bí a bá sẹ́,+ òun pẹ̀lú yóò sẹ́ wa; 13  bí a bá jẹ́ aláìṣòótọ́, òun dúró ní olùṣòtítọ́,+ nítorí kò lè sẹ́ ara rẹ̀. 14  Máa rán wọn létí+ nǹkan wọ̀nyí, ní pípàṣẹ+ fún wọn níwájú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí,+ láti má jà lórí ọ̀rọ̀,+ ohun tí kò wúlò rárá nítorí pé ó máa ń dojú àwọn tí ń fetí sílẹ̀ dé. 15  Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà,+ aṣiṣẹ́+ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú,+ tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.+ 16  Ṣùgbọ́n máa yẹ àwọn òfìfo ọ̀rọ̀ sílẹ̀, tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́;+ nítorí tí wọn yóò tẹ̀ síwájú sí àìṣèfẹ́ Ọlọ́run síwájú àti síwájú,+ 17  ọ̀rọ̀ wọn yóò sì tàn kálẹ̀ bí egbò kíkẹ̀.+ Híméníọ́sì àti Fílétọ́sì wà lára wọn.+ 18  Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí pàápàá ti yapa kúrò nínú òtítọ́,+ wọ́n ń sọ pé àjíǹde ti ṣẹlẹ̀ ná;+ wọ́n sì ń dojú ìgbàgbọ́ àwọn kan dé.+ 19  Láìka gbogbo èyíinì sí, ìpìlẹ̀ lílágbára ti Ọlọ́run dúró sẹpẹ́,+ ó ní èdìdì yìí: “Jèhófà mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀,”+ àti pé: “Kí gbogbo ẹni tí ń pe orúkọ Jèhófà+ kọ àìṣòdodo sílẹ̀ ní àkọ̀tán.”+ 20  Wàyí o, nínú ilé ńlá, kì í ṣe àwọn ohun èlò wúrà àti fàdákà nìkan ni ó wà ṣùgbọ́n ti igi àti ohun èlò amọ̀ pẹ̀lú, àwọn kan sì wà fún ète ọlọ́lá ṣùgbọ́n àwọn mìíràn fún ète tí kò ní ọlá.+ 21  Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá yẹra fún àwọn ti ìkẹyìn yìí, òun yóò jẹ́ ohun èlò fún ète ọlọ́lá, tí a sọ di mímọ́, tí ó wúlò fún ẹni tí ó ni ín, tí a múra sílẹ̀ fún gbogbo iṣẹ́ rere.+ 22  Nítorí náà, sá fún àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn,+ ṣùgbọ́n máa lépa òdodo,+ ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àlàáfíà,+ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ń ké pe Olúwa láti inú ọkàn-àyà tí ó mọ́.+ 23  Síwájú sí i, kọ̀ láti gba bíbéèrè ìbéèrè òmùgọ̀ àti ti àìmọ̀kan,+ ní mímọ̀ pé wọ́n ń mú ìjà wá.+ 24  Ṣùgbọ́n kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà,+ ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn,+ ẹni tí ó tóótun láti kọ́ni,+ tí ń kó ara rẹ̀ ní ìjánu lábẹ́ ibi,+ 25  kí ó máa fún àwọn tí kò ní ìtẹ̀sí ọkàn rere ní ìtọ́ni pẹ̀lú ìwà tútù;+ pé bóyá Ọlọ́run lè fún wọn ní ìrònúpìwàdà+ tí ń ṣamọ̀nà sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́,+ 26  kí wọ́n sì lè padà wá sí agbára ìmòye wọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu kúrò nínú ìdẹkùn+ Èṣù, ní rírí i pé ó ti mú wọn láàyè+ fún ìfẹ́ ẹni yẹn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé