Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Tímótì 1:1-18

1  Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì Kristi Jésù nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run+ ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí ìyè+ tí ó wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù,+  sí Tímótì, olùfẹ́ ọ̀wọ́n ọmọ:+ Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, àánú, àlàáfíà wà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Kristi Jésù Olúwa wa.+  Mo kún fún ìmoore sí Ọlọ́run, ẹni tí mo ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀+ fún gẹ́gẹ́ bí àwọn baba ńlá+ mi ti ṣe àti pẹ̀lú ẹ̀rí-ọkàn+ tí ó mọ́, pé èmi kò ṣíwọ́ rí ní rírántí rẹ nínú àwọn ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀+ mi, lóru àti lọ́sàn-án  aáyun ń yun mi láti rí ọ,+ bí mo ti ń rántí omijé rẹ, kí n lè kún fún ìdùnnú.  Nítorí tí mo rántí ìgbàgbọ́+ tí ó wà nínú rẹ láìsí àgàbàgebè+ kankan, èyí tí ó kọ́kọ́ wà nínú ìyá rẹ àgbà Lọ́ìsì àti ìyá rẹ Yùníìsì, ṣùgbọ́n èyí tí mo ní ìgbọ́kànlé pé ó wà nínú rẹ pẹ̀lú.  Fún ìdí yìí gan-an ni mo ṣe ń rán ọ létí láti máa rú sókè bí iná,+ ẹ̀bùn+ Ọlọ́run tí ń bẹ nínú rẹ nípasẹ̀ gbígbé ọwọ́ mi lé ọ.+  Nítorí kì í ṣe ẹ̀mí ojo+ ni Ọlọ́run fún wa bí kò ṣe ti agbára+ àti ti ìfẹ́ àti ti ìyèkooro èrò inú.+  Nítorí náà. má tijú ẹ̀rí nípa Olúwa wa,+ tàbí èmi ẹlẹ́wọ̀n nítorí rẹ̀,+ ṣùgbọ́n kó ipa tirẹ nínú jíjìyà+ ibi fún ìhìn rere ní ìbámu pẹ̀lú agbára Ọlọ́run.+  Ó gbà wá là,+ ó sì fi ìpè mímọ́+ pè wá, kì í ṣe nítorí àwọn iṣẹ́ wa,+ ṣùgbọ́n nítorí ète àti inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tirẹ̀. Tipẹ́tipẹ́+ ni a ti fi èyí fún wa ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù, 10  ṣùgbọ́n nísinsìnyí a ti jẹ́ kí ó hàn gbangba-gbàǹgbà nípasẹ̀ ìfarahàn+ Olùgbàlà wa, Kristi Jésù, ẹni tí ó ti fi òpin sí ikú+ ṣùgbọ́n tí ó ti tan ìmọ́lẹ̀+ sórí ìyè+ àti àìdíbàjẹ́+ nípasẹ̀ ìhìn rere,+ 11  èyí tí a torí rẹ̀ yàn mí ṣe oníwàásù àti àpọ́sítélì àti olùkọ́.+ 12  Fún ìdí yìí gan-an ni èmi pẹ̀lú ṣe ń jìyà+ nǹkan wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ojú kò tì mí.+ Nítorí tí mo mọ ẹni tí èmi ti gbà gbọ́, mo sì ní ìgbọ́kànlé pé ó lè ṣọ́+ ohun tí mo tò jọ ní ìtọ́júpamọ́ sọ́dọ̀ rẹ̀ títí di ọjọ́ náà.+ 13  Máa di àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera+ tí ìwọ gbọ́ lọ́dọ̀ mi mú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ó wà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.+ 14  Ohun ìtọ́júpamọ́+ àtàtà yìí ni kí o ṣọ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ tí ń gbé inú wa.+ 15  Ìwọ mọ èyí, pé gbogbo ènìyàn ní agbègbè Éṣíà+ yí padà kúrò lọ́dọ̀ mi.+ Fíjẹ́lọ́sì àti Hẹmojẹ́nísì wà lára àwọn wọ̀nyí. 16  Kí Olúwa yọ̀ǹda àánú fún agbo ilé Ónẹ́sífórù,+ nítorí pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó ti mú ìtura wá bá mi,+ kò sì tijú àwọn ẹ̀wọ̀n mi.+ 17  Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí ó wà ní Róòmù, ó fi taápọn-taápọn wá mi, ó sì rí mi.+ 18  Kí Olúwa yọ̀ǹda fún un láti rí àánú+ lọ́dọ̀ Jèhófà ní ọjọ́ yẹn.+ Gbogbo iṣẹ́ ìsìn tí ó sì ṣe ní Éfésù ni ìwọ mọ̀ dáadáa.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé