Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Sámúẹ́lì 8:1-18

8  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà pé Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá àwọn Filísínì+ balẹ̀, ó sì tẹ̀ wọ́n lórí ba,+ Dáfídì sì gba Metegi-ámà lọ́wọ́ àwọn Filísínì.  Ó sì ń bá a lọ láti ṣá àwọn ọmọ Móábù+ balẹ̀, ó sì fi okùn díwọ̀n wọn, ní mímú kí wọ́n dùbúlẹ̀ sórí ilẹ̀, kí ó lè díwọ̀n okùn méjì láti fi ikú pa wọ́n, àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ okùn láti pa wọ́n mọ́ láàyè;+ àwọn ọmọ Móábù sì wá di ìránṣẹ́ Dáfídì+ láti máa mú owó òde wá.+  Dáfídì sì ń bá a lọ láti ṣá Hadadésà+ ọmọkùnrin Réhóbù ọba Sóbà+ balẹ̀ bí ó ti ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ láti tún dá àkóso rẹ̀ padà ní Odò Yúfírétì.+  Dáfídì sì wá gba ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán ẹlẹ́ṣin àti ọ̀kẹ́ kan àwọn ọkùnrin tí ń fẹsẹ̀ rìn+ lọ́wọ́ rẹ̀; Dáfídì sì tẹ̀ síwájú láti já+ gbogbo àwọn ẹṣin kẹ̀kẹ́+ náà ní pátì, ṣùgbọ́n ó jẹ́ kí ọgọ́rùn-ún ẹṣin kẹ̀kẹ́ ṣẹ́ kù lára wọn.  Nígbà tí Síríà ti Damásíkù+ wá ran Hadadésà ọba Sóbà lọ́wọ́, nígbà náà ni Dáfídì ṣá ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàá ọkùnrin balẹ̀ lára àwọn ará Síríà.+  Síwájú sí i, Dáfídì fi àwọn ẹgbẹ́ ogun+ sí Síríà ti Damásíkù; àwọn ará Síríà sì wá di ìránṣẹ́ Dáfídì láti máa mú owó òde wá.+ Jèhófà sì ń bá a lọ láti gba Dáfídì là ní ibikíbi tí ó bá lọ.+  Síwájú sí i, Dáfídì gba àwọn apata bìrìkìtì+ wúrà tí ó wà lára àwọn ìránṣẹ́ Hadadésà, ó sì kó wọn wá sí Jerúsálẹ́mù.  Dáfídì Ọba sì kó bàbà ní ìwọ̀n púpọ̀ gan-an láti Bétà àti Bérótáì, àwọn ìlú ńlá Hadadésà.+  Wàyí o, Tóì ọba Hámátì+ wá gbọ́ pé Dáfídì ti ṣá gbogbo ẹgbẹ́ ológun Hadadésà balẹ̀.+ 10  Nítorí náà, Tóì rán Jórámù ọmọkùnrin rẹ̀ sí Dáfídì Ọba láti béèrè nípa àlàáfíà+ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ àti láti bá a yọ̀ nítorí òtítọ́ náà pé ó ti bá Hadadésà jà, tí ó sì ṣá a balẹ̀ (nítorí Hadadésà ti di ẹni tí a kọ́ ní iṣẹ́ ogun láti gbéjà ko Tóì); àwọn ohun èlò fàdákà àti àwọn ohun èlò wúrà àti àwọn ohun èlò bàbà sì wà ní ọwọ́ rẹ̀.+ 11  Ìwọ̀nyí pẹ̀lú ni Dáfídì Ọba sọ di mímọ́ fún Jèhófà, pa pọ̀ pẹ̀lú fàdákà àti wúrà tí ó ti sọ di mímọ́ láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti tẹ̀ lórí ba,+ 12  láti ọ̀dọ̀ Síríà àti láti ọ̀dọ̀ Móábù+ àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì àti láti ọ̀dọ̀ àwọn Filísínì+ àti láti ọ̀dọ̀ Ámálékì+ àti láti inú ohun ìfiṣèjẹ Hadadésà ọmọkùnrin Réhóbù ọba Sóbà.+ 13  Dáfídì sì tẹ̀ síwájú láti ṣe orúkọ nígbà tí ó padà dé lẹ́nu ṣíṣá àwọn ọmọ Édómù balẹ̀ ní Àfonífojì Iyọ̀+—ẹgbàásàn-án.+ 14  Ó sì fi àwọn ẹgbẹ́ ogun sí Édómù.+ Gbogbo Édómù ni ó fi àwọn ẹgbẹ́ ogun sí, gbogbo àwọn ọmọ Édómù sì wá di ìránṣẹ́ Dáfídì;+ Jèhófà sì ń bá a nìṣó ní gbígba Dáfídì là ní ibikíbi tí ó bá lọ.+ 15  Dáfídì sì ń bá a nìṣó ní jíjọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì;+ Dáfídì sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìpinnu ìdájọ́ àti òdodo+ fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀.+ 16  Jóábù+ ọmọkùnrin Seruáyà sì ni ó wà lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun; Jèhóṣáfátì+ ọmọkùnrin Áhílúdù sì ni akọ̀wé ìrántí. 17  Sádókù+ ọmọkùnrin Áhítúbù àti Áhímélékì+ ọmọkùnrin Ábíátárì sì ni àlùfáà, Seráyà sì ni akọ̀wé. 18  Bẹnáyà+ ọmọkùnrin Jèhóádà sì ni ó wà lórí àwọn Kérétì+ àti àwọn Pẹ́lẹ́tì.+ Ní ti àwọn ọmọkùnrin Dáfídì, wọ́n di àlùfáà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé