Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Sámúẹ́lì 7:1-29

7  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí ọba ń gbé inú ilé tirẹ̀,+ tí Jèhófà fúnra rẹ̀ sì ti fún un ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíká-yíká,+  nígbà náà, ọba sọ fún Nátánì+ wòlíì pé: “Kíyè sí i, nísinsìnyí, èmi ń gbé inú ilé kédárì+ nígbà tí àpótí Ọlọ́run tòótọ́ ń gbé ní àárín àwọn aṣọ àgọ́.”+  Látàrí èyí, Nátánì sọ fún ọba pé: “Ohun gbogbo tí ó bá wà ní ọkàn-àyà rẹ—lọ ṣe é,+ nítorí pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.”  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní òru yẹn pé, ọ̀rọ̀+ Jèhófà tọ Nátánì wá, pé:  “Lọ, kí o sì sọ fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ìwọ fúnra rẹ yóò ha kọ́ ilé fún mi láti máa gbé bí?+  Nítorí èmi kò tíì gbé inú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gòkè wá láti Íjíbítì títí di òní yìí,+ ṣùgbọ́n mo ń bá a lọ ní rírìn+ káàkiri nínú àgọ́+ áti nínú àgọ́ ìjọsìn.+  Ní gbogbo àkókò tí mo fi rìn káàkiri láàárín gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ mo ha ti bá ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì+ tí mo pàṣẹ fún pé kí wọ́n máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, pé, ‘Èé ṣe tí ẹ kò fi kọ́ ilé kédárì fún mi?’”’  Wàyí o, èyí ni ohun tí ìwọ yóò sọ fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: “Èmi ni mo mú ọ kúrò ní ilẹ̀ ìjẹko, kúrò ní títọ agbo ẹran+ lẹ́yìn, kí o lè di aṣáájú+ lórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.  Èmi yóò sì wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí o bá lọ,+ èmi yóò sì ké gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ;+ dájúdájú, èmi yóò sì ṣe orúkọ ńlá+ fún ọ, bí orúkọ àwọn ẹni ńlá tí ń bẹ ní ilẹ̀ ayé. 10  Dájúdájú, èmi yóò yan ibì+ kan kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, èmi yóò sì gbìn+ wọ́n, ní tòótọ́, wọn yóò máa gbé ní ibi tí wọ́n wà, a kì yóò sì yọ wọ́n lẹ́nu mọ́; àwọn ọmọ àìṣòdodo kì yóò sì tún ṣẹ́ wọn níṣẹ̀ẹ́ mọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ìgbà àkọ́kọ́,+ 11  àní láti ọjọ́ tí mo ti fi àwọn onídàájọ́+ sí ipò àṣẹ lórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì; dájúdájú, èmi yóò sì fún ọ ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ.+ “‘“Jèhófà sì ti sọ fún ọ pé, Jèhófà yóò kọ́ ilé+ fún ọ. 12  Nígbà tí àwọn ọjọ́ rẹ bá kún,+ tí ìwọ yóò sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ,+ nígbà náà, èmi yóò gbé irú-ọmọ rẹ dìde lẹ́yìn rẹ dájúdájú, tí yóò jáde wá láti ìhà inú rẹ; ní tòótọ́, èmi yóò fìdí ìjọba+ rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in. 13  Òun ni ẹni tí yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi,+ dájúdájú, èmi yóò fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 14  Èmi fúnra mi yóò di baba rẹ̀,+ òun alára yóò sì di ọmọ mi.+ Nígbà tí ó bá ṣe àìtọ́, dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò fi ọ̀pá+ ènìyàn àti ẹgba àwọn ọmọ Ádámù bá a wí. 15  Ní ti inú rere mi onífẹ̀ẹ́, kì yóò lọ kúrò lára rẹ̀ bí mo ṣe mú un kúrò lára Sọ́ọ̀lù,+ ẹni tí mo mú kúrò ní tìtorí tìrẹ. 16  Ilé rẹ àti ìjọba rẹ yóò sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin dájúdájú fún àkókò tí ó lọ kánrin níwájú rẹ; ìtẹ́ rẹ pàápàá yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún àkókò tí ó lọ kánrin.”’”+ 17  Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí àti gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìran yìí ni Nátánì ṣe sọ fún Dáfídì.+ 18  Látàrí ìyẹn, Dáfídì Ọba wọlé, ó sì jókòó níwájú Jèhófà, ó sì wí pé: “Ta ni èmi,+ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ? Kí sì ni ilé mi tí o fi gbé mi títí dé ìhín yìí? 19  Bí ẹni pé èyí tilẹ̀ jẹ́ ohun kékeré ní ojú rẹ, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, síbẹ̀, o tún sọ̀rọ̀ nípa ilé ìránṣẹ́ rẹ títí lọ dé àkókò ọjọ́ iwájú jíjì nnà; èyí sì ni òfin tí a fún aráyé,+ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.+ 20  Kí sì ni ó tún kù tí Dáfídì lè fi kún un, kí ó sì sọ fún ọ, nígbà tí ìwọ fúnra rẹ mọ ìránṣẹ́ rẹ dáadáa,+ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ? 21  Nítorí ọ̀rọ̀+ rẹ àti ní ìbámu pẹ̀lú ọkàn-àyà+ rẹ ni ìwọ fi ṣe gbogbo ohun ńláǹlà wọ̀nyí láti lè jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ wọ́n.+ 22  Ìdí nìyẹn tí ìwọ fi tóbi jọjọ,+ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ; nítorí kò sí ẹlòmíràn tí ó dà bí rẹ,+ kò sì sí Ọlọ́run kankan bí kò ṣe ìwọ+ láàárín gbogbo àwọn tí a ti fi etí wa gbọ́ nípa wọn. 23  Orílẹ̀-èdè kan wo ní ilẹ̀ ayé sì ni ó dà bí àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì,+ àwọn tí Ọlọ́run lọ tún rà padà fún ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn+ kan àti láti ṣe orúkọ+ kan fún ara rẹ̀ àti láti ṣe àwọn ohun ńláǹlà àti amúnikún-fún-ẹ̀rù fún wọn+—láti lé àwọn orílẹ̀-èdè náà àti àwọn ọlọ́run wọn jáde nítorí àwọn ènìyàn rẹ, tí o ti tún rà padà+ fún ara rẹ láti Íjíbítì? 24  Ìwọ sì tẹ̀ síwájú láti fìdí àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì+ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún ara rẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin; ìwọ fúnra rẹ, Jèhófà, sì di Ọlọ́run wọn.+ 25  “Wàyí o, Jèhófà Ọlọ́run, ọ̀rọ̀ tí o ti sọ nípa ìránṣẹ́ rẹ àti nípa ilé rẹ̀, kí o mú un ṣẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin, kí o sì ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí o ṣe sọ.+ 26  Kí orúkọ rẹ sì di ńlá fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ pé, ‘Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni Ọlọ́run lórí Ísírẹ́lì,’+ kí ilé Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ sì di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in níwájú rẹ.+ 27  Nítorí ìwọ, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti ṣí i payá ní etí ìránṣẹ́ rẹ, pé, ‘Èmi yóò kọ́ ilé fún ọ.’+ Ìdí nìyẹn tí ìránṣẹ́ rẹ fi ṣe ọkàn-àyà gírí láti gba èyí ní àdúra sí ọ.+ 28  Wàyí o, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìwọ ni Ọlọ́run tòótọ́; àti ní ti àwọn ọ̀rọ̀ rẹ, jẹ́ kí wọ́n já sí òtítọ́,+ níwọ̀n bí o ti ṣèlérí oore+ yìí fún ìránṣẹ́ rẹ. 29  Wàyí o, dáwọ́ lé e, kí o sì bù kún+ ilé ìránṣẹ́ rẹ, kí ó lè máa wà nìṣó fún àkókò tí ó lọ kánrin níwájú rẹ;+ nítorí ìwọ fúnra rẹ, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ti ṣèlérí, àti nítorí ìbùkún rẹ, kí a bù kún ilé ìránṣẹ́ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé