Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Sámúẹ́lì 6:1-23

6  Dáfídì sì tún tẹ̀ síwájú láti kó gbogbo ààyò ọkùnrin Ísírẹ́lì jọ,+ ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀.  Lẹ́yìn náà, Dáfídì àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ dìde, wọ́n sì lọ sí Baale-júdà+ láti gbé àpótí+ Ọlọ́run tòótọ́ gòkè wá láti ibẹ̀, ibi tí a ń fi orúkọ+ kan pè, orúkọ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,+ ẹni tí ń jókòó lórí àwọn kérúbù.+  Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n gbé àpótí Ọlọ́run tòótọ́ sórí kẹ̀kẹ́ tuntun,+ kí wọ́n bàa lè gbé e láti ilé Ábínádábù,+ èyí tí ó wà lórí òkè kékeré; Úsà àti Áhíò,+ àwọn ọmọkùnrin Ábínádábù, sì ń ṣamọ̀nà kẹ̀kẹ́ tuntun náà.  Nítorí náà, wọ́n gbé e láti ilé Ábínádábù, èyí tí ó wà lórí òkè kékeré—pẹ̀lú àpótí Ọlọ́run tòótọ́; Áhíò sì ń rìn níwájú Àpótí náà.  Dáfídì àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì sì ń ṣe ayẹyẹ níwájú Jèhófà pẹ̀lú gbogbo onírúurú ohun èlò orin tí a fi igi júnípà ṣe àti pẹ̀lú háàpù+ àti pẹ̀lú àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín+ àti pẹ̀lú ìlù tanboríìnì+ àti pẹ̀lú sítírọ́mù àti pẹ̀lú aro.+  Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n ń bọ̀ títí dé ilẹ̀ ìpakà Nákónì, Úsà+ sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde wàyí sí àpótí Ọlọ́run tòótọ́, ó sì gbá a mú,+ nítorí tí màlúù náà fẹ́rẹ̀ẹ́ fa ìdojúdé.  Látàrí ìyẹn, ìbínú+ Jèhófà ru sí Úsà, Ọlọ́run tòótọ́ sì ṣá a balẹ̀+ níbẹ̀ nítorí ìwà àìlọ́wọ̀ náà, tí ó fi kú níbẹ̀ nítòsí àpótí Ọlọ́run tòótọ́.+  Dáfídì sì bínú nítorí òtítọ́ náà pé Jèhófà ti ṣe ìyalù nípa gbígbéjà ko Úsà, a sì wá ń pe ibẹ̀ ní Peresi-úsà títí di òní yìí.+  Dáfídì sì fòyà Jèhófà+ ní ọjọ́ yẹn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Báwo ni àpótí Jèhófà yóò ṣe wá sọ́dọ̀ mi?”+ 10  Dáfídì kò sì fẹ́ láti gbé àpótí Jèhófà wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní Ìlú Ńlá Dáfídì.+ Nítorí náà, Dáfídì mú kí a gbé e yà sí ilé Obedi-édómù+ ará Gátì.+ 11  Àpótí Jèhófà sì ń bá a nìṣó ní gbígbé ilé Obedi-édómù ará Gátì fún oṣù mẹ́ta; Jèhófà sì ń bù kún+ Obedi-édómù àti gbogbo agbo ilé rẹ̀.+ 12  Níkẹyìn, a ròyìn fún Dáfídì Ọba, pé: “Jèhófà ti bù kún ilé Obedi-édómù àti gbogbo ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀ ní tìtorí àpótí Ọlọ́run tòótọ́.” Látàrí ìyẹn, Dáfídì tẹ̀ síwájú láti lọ gbé àpótí Ọlọ́run tòótọ́ láti ilé Obedi-édómù gòkè wá sí Ìlú Ńlá Dáfídì pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀.+ 13  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí àwọn olùru+ àpótí Jèhófà rìn síwájú ní ìṣísẹ̀ mẹ́fà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó fi akọ màlúù àti ẹran àbọ́pa rúbọ.+ 14  Dáfídì sì ń fi gbogbo agbára rẹ̀ jó yí ká níwájú Jèhófà, ní gbogbo àkókò náà, Dáfídì sán éfódì+ aṣọ ọ̀gbọ̀. 15  Dáfídì àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì sì ń gbé àpótí+ Jèhófà gòkè bọ̀ pẹ̀lú igbe ìdùnnú+ àti ìró ìwo.+ 16  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí àpótí Jèhófà wọ Ìlú Ńlá Dáfídì, Míkálì,+ ọmọbìnrin Sọ́ọ̀lù, bojú wolẹ̀ lójú fèrèsé, ó sì wá rí Dáfídì Ọba tí ń fò sókè, tí ó sì ń jó yí ká níwájú Jèhófà; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ńbẹ́lú+ rẹ̀ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.+ 17  Nítorí náà, wọ́n gbé àpótí Jèhófà wọlé wá, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sí àyè rẹ̀ nínú àgọ́ tí Dáfídì pa fún un;+ lẹ́yìn èyí tí Dáfídì rú àwọn ẹbọ sísun+ àti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀+ níwájú Jèhófà. 18  Nígbà tí Dáfídì parí rírú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ náà, nígbà náà ni ó súre+ fún àwọn ènìyàn náà ní orúkọ Jèhófà+ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun. 19  Síwájú sí i, ó pín+ ìṣù búrẹ́dì onírìísí òrùka àti ìṣù èso déètì àti ìṣù èso àjàrà gbígbẹ+ fún olúkúlùkù, fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, fún gbogbo ogunlọ́gọ̀ Ísírẹ́lì, àti ọkùnrin àti obìnrin, lẹ́yìn èyí tí gbogbo àwọn ènìyàn náà lọ, olúkúlùkù, sí ilé tirẹ̀. 20  Wàyí o, Dáfídì padà láti súre fún agbo ilé+ tirẹ̀, Míkálì,+ ọmọbìnrin Sọ́ọ̀lù, sì jáde wá láti pàdé Dáfídì, nígbà náà ni ó sọ pé: “Ẹ wo bí ọba Ísírẹ́lì ti ṣe ara rẹ̀ lógo tó lónìí+ nígbà tí ó tú ara rẹ̀ sí ìhòòhò lónìí ní ojú àwọn ẹrúbìnrin ìránṣẹ́ rẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn akúrí ṣe ń tú ara rẹ̀ sí ìhòòhò pátápátá!”+ 21  Látàrí èyí, Dáfídì sọ fún Míkálì pé: “Iwájú Jèhófà ni, ẹni tí ó yàn mi dípò baba rẹ àti gbogbo agbo ilé rẹ̀ láti fi mí sí ipò àṣẹ+ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú lórí Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn Jèhófà, dájúdájú, èmi yóò sì ṣe ayẹyẹ níwájú Jèhófà.+ 22  Èmi yóò tilẹ̀ túbọ̀ sọ ara mi di ẹni tí a kò fi bẹ́ẹ̀ kà sí ju èyí,+ dájúdájú, èmi yóò sì di ẹni rírẹlẹ̀ ní ojú ara mi; àwọn ẹrúbìnrin tí o sì mẹ́nu kàn, àwọn ni èmi ti pinnu láti fi ṣe ara mi lógo.”+ 23  Nítorí náà, ní ti Míkálì,+ ọmọbìnrin Sọ́ọ̀lù, kò sì wá ní ọmọ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé