Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Sámúẹ́lì 5:1-25

5  Nígbà tí ó ṣe, gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì wá sọ́dọ̀ Dáfídì+ ní Hébúrónì,+ wọ́n sì wí pé: “Wò ó! Egungun rẹ àti ẹran ara rẹ ni àwa fúnra wa jẹ́.+  Àti ní àná àti tẹ́lẹ̀ rí+ nígbà tí Sọ́ọ̀lù ṣì jẹ́ ọba lórí wa, ìwọ fúnra rẹ di ẹni tí ń mú Ísírẹ́lì jáde, tí ó sì ń mú un wọlé.+ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ọ pé, ‘Ìwọ ni yóò máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn+ àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, ìwọ sì ni yóò di aṣáájú+ lórí Ísírẹ́lì.’”  Nítorí náà, gbogbo àwọn àgbà ọkùnrin+ Ísírẹ́lì wá sọ́dọ̀ ọba ní Hébúrónì, Dáfídì Ọba sì bá wọn dá májẹ̀mú+ ní Hébúrónì níwájú Jèhófà; lẹ́yìn èyí tí wọ́n fòróró yan+ Dáfídì ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì.+  Ẹni ọgbọ̀n ọdún ni Dáfídì nígbà tí ó di ọba. Ogójì ọdún+ ni ó fi ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba.  Ní Hébúrónì, ó ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí Júdà fún ọdún méje àti oṣù mẹ́fà;+ àti ní Jerúsálẹ́mù,+ ó ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba fún ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n lórí gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà.  Nítorí náà, ọba àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù láti gbéjà ko àwọn ará Jébúsì+ tí ń gbé ilẹ̀ náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Dáfídì pé: “Ìwọ kì yóò wọ ìhín, ṣùgbọ́n àwọn afọ́jú àti àwọn arọ ni yóò dá ọ padà+ dájúdájú,” wọ́n ronú pé: “Dáfídì kì yóò wọ ìhín.”  Síbẹ̀síbẹ̀, Dáfídì tẹ̀ síwájú láti gba ibi odi agbára Síónì,+ èyíinì ni, Ìlú Ńlá Dáfídì.+  Nítorí náà, Dáfídì sọ ní ọjọ́ yẹn pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọlu àwọn ará Jébúsì,+ kí ó gba ti ibi ihò omi+ kan àwọn arọ àti àwọn afọ́jú lára, àwọn tí ọkàn Dáfídì kórìíra!” Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi sọ pé: “Àwọn afọ́jú àti àwọn arọ kì yóò wọ ilé.”  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé inú ibi odi agbára náà, a sì wá pè é ní Ìlú Ńlá Dáfídì; Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́lé yíká-yíká láti Òkìtì+ wá àti sínú. 10  Bí Dáfídì ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i ṣáá+ nìyẹn, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun+ sì wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 11  Hírámù+ ọba Tírè sì tẹ̀ síwájú láti rán àwọn ońṣẹ́+ sí Dáfídì, àti àwọn igi kédárì+ àti àwọn oníṣẹ́ igi àti àwọn oníṣẹ́ òkúta pẹ̀lú fún àwọn ògiri, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé fún Dáfídì.+ 12  Dáfídì sì wá mọ̀ pé Jèhófà ti fìdí òun múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in gẹ́gẹ́ bí ọba lórí Ísírẹ́lì,+ àti pé ó ti gbé ìjọba òun ga+ nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì.+ 13  Láàárín àkókò yìí, Dáfídì ń bá a lọ láti fẹ́ àwọn wáhàrì+ àti aya+ púpọ̀ sí i láti Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn tí ó ti dé láti Hébúrónì; a sì ń bá a lọ ní bíbí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin púpọ̀ sí i fún Dáfídì. 14  Ìwọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn tí a bí fún un ní Jerúsálẹ́mù: Ṣámúà+ àti Ṣóbábù+ àti Nátánì+ àti Sólómọ́nì,+ 15  àti Íbárì àti Élíṣúà+ àti Néfégì+ àti Jáfíà,+ 16  àti Élíṣámà+ àti Élíádà àti Élífélétì.+ 17  Àwọn Filísínì sì wá gbọ́ pé wọ́n ti fòróró yan Dáfídì ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì.+ Látàrí ìyẹn, gbogbo àwọn Filísínì gòkè wá láti wá Dáfídì. Nígbà tí Dáfídì gbọ́ nípa rẹ̀, nígbà náà ni ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ibi tí ó nira láti dé.+ 18  Àwọn Filísínì, ní tiwọn, sì wọlé wá, wọ́n sì ń rìn káàkiri pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Réfáímù.+ 19  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí wádìí+ lọ́dọ̀ Jèhófà, pé: “Ṣé kí n gòkè lọ gbéjà ko àwọn Filísínì? Ìwọ yóò ha fi wọ́n lé mi lọ́wọ́?” Látàrí èyí, Jèhófà sọ fún Dáfídì pé: “Gòkè lọ, nítorí láìkùnà, èmi yóò fi àwọn Filísínì lé ọ lọ́wọ́.”+ 20  Nítorí náà, Dáfídì wá sí Baali-pérásímù,+ Dáfídì sì ṣá wọn balẹ̀ níbẹ̀. Látàrí ìyẹn, ó wí pé: “Jèhófà ti ya lu àwọn ọ̀tá+ mi níwájú mi, bí àlàfo tí omi ṣe.” Ìdí nìyẹn tí ó fi pe orúkọ ibẹ̀ yẹn ní Baali-pérásímù.+ 21  Nítorí náà, wọ́n fi àwọn òrìṣà+ wọn sílẹ̀ níbẹ̀, nítorí náà, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ kó wọn lọ.+ 22  Lẹ́yìn náà, àwọn Filísínì tún gòkè wá,+ wọ́n sì rìn káàkiri pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Réfáímù.+ 23  Látàrí ìyẹn, Dáfídì wádìí+ lọ́dọ̀ Jèhófà, ṣùgbọ́n ó wí pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ gòkè lọ. Lọ yí ká sí ìhà ẹ̀yìn wọn, kí o sì wá gbéjà kò wọ́n ní iwájú àwọn igi bákà.+ 24  Sì jẹ́ kí ó ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí o bá gbọ́ ìró ìrìn lórí àwọn igi bákà, ní àkókò yẹn, kí o gbé ìgbésẹ̀ pẹ̀lú ìpinnu,+ nítorí pé ní àkókò yẹn, Jèhófà yóò ti jáde lọ níwájú rẹ láti ṣá ibùdó àwọn Filísínì balẹ̀.”+ 25  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Dáfídì ṣe bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún un gan-an,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá àwọn Filísínì balẹ̀+ láti Gébà+ títí dé Gésérì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé