Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Sámúẹ́lì 4:1-12

4  Nígbà tí ọmọkùnrin+ Sọ́ọ̀lù gbọ́ pé Ábínérì ti kú ní Hébúrónì,+ nígbà náà ni ọwọ́ rẹ̀ rọ,+ ìyọlẹ́nu sì bá gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì alára.  Ọkùnrin méjì sì wà, olórí àwọn ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí,+ tí ó jẹ́ ti ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù, orúkọ ọ̀kan ń jẹ́ Báánáhì, orúkọ èkejì sì ń jẹ́ Rékábù, àwọn ọmọkùnrin Rímónì ará Béérótì,+ lára àwọn ọmọkùnrin Bẹ́ńjámínì; nítorí pé tẹ́lẹ̀ rí, Béérótì pẹ̀lú, ni a máa ń kà mọ́ ara Bẹ́ńjámínì.  Àwọn ará Béérótì sì bẹ̀rẹ̀ sí fẹsẹ̀ fẹ lọ sí Gítáímù,+ wọ́n sì wá jẹ́ àtìpó níbẹ̀ títí di òní yìí.  Wàyí o, Jónátánì,+ ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù, ní ọmọkùnrin kan tí ó rọ ní ẹsẹ̀.+ Ó jẹ́ ẹni ọdún márùn-ún nígbà tí ìròyìn nípa Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì dé láti Jésíréélì;+ olùṣètọ́jú rẹ̀ sì gbé e, ó sì sá lọ, ṣùgbọ́n ó ṣẹlẹ̀ pé bí obìnrin náà ti ń sá nínú ìbẹ̀rù jì nnìjì nnì láti sá lọ, nígbà náà ni ọmọkùnrin náà ṣubú, ó sì yarọ. Orúkọ rẹ̀ sì ni Mefibóṣẹ́tì.+  Àwọn ọmọkùnrin Rímónì ará Béérótì, Rékábù àti Báánáhì, sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ, wọ́n sì dé ilé Iṣi-bóṣẹ́tì+ ní nǹkan bí ìgbà tí ọjọ́ gbóná, bí ó ti ń sun oorun ọ̀sán.  Sì kíyè sí i, wọ́n wá sí àárín ilé náà bí àwọn ọkùnrin tí ó wá kó àlìkámà, nígbà náà ni wọ́n sì kọlù ú ní inú;+ Rékábù àti Báánáhì+ arákùnrin rẹ̀ sì yọ́ lọ.  Nígbà tí wọ́n wọnú ilé, ó dùbúlẹ̀ sórí àga ìrọ̀gbọ̀kú rẹ̀ nínú yàrá ibùsùn rẹ̀ inú lọ́hùn-ún, nígbà náà ni wọ́n kọlù ú, tí wọ́n sì fi ikú pa á,+ lẹ́yìn èyí tí wọ́n mú orí+ rẹ̀ kúrò, wọ́n sì gbé orí rẹ̀, wọ́n sì rìn ní ojú ọ̀nà tí ó lọ sí Árábà láti òru mọ́jú.  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n gbé orí Iṣi-bóṣẹ́tì+ tọ Dáfídì wá ní Hébúrónì, wọ́n sì sọ fún ọba pé: “Orí Iṣi-bóṣẹ́tì ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù ọ̀tá rẹ+ ẹni tí ó wá ọkàn rẹ+ rèé; ṣùgbọ́n Jèhófà ti gbẹ̀san+ fún olúwa mi ọba lónìí yìí lára Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀.”  Bí ó ti wù kí ó rí, Dáfídì dá Rékábù àti Báánáhì arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin Rímónì ará Béérótì lóhùn, ó sì sọ fún wọn pé: “Bí Jèhófà ẹni tí ó tún ọkàn+ mi rà padà+ kúrò nínú gbogbo wàhálà+ ti ń bẹ,+ 10  nígbà tí ẹnì kan ròyìn fún mi,+ pé, ‘Kíyè sí i, Sọ́ọ̀lù ti kú,’ òun fúnra rẹ̀ ní ojú ara rẹ̀ sì dà bí olùmú ìhìn rere wá, bí ó ti wù kí ó rí, mo dì í mú, mo sì pa+ á ní Síkílágì nígbà tí ó yẹ kí n fún un ní owó ońṣẹ́; 11  mélòómélòó ni ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ nígbà tí àwọn ọkùnrin burúkú+ fúnra wọn ti pa ọkùnrin olódodo nínú ilé ara rẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀? Wàyí o, èmi kì yóò ha béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yín,+ èmi kì yóò ha sì mú yín kúrò ní ilẹ̀ ayé?”+ 12  Pẹ̀lú ìyẹn, Dáfídì pàṣẹ fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin, wọ́n sì pa wọ́n,+ wọ́n sì gé ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn kúrò, wọ́n sì gbé wọn kọ́+ sẹ́bàá odò adágún ní Hébúrónì; wọ́n sì gbé orí Iṣi-bóṣẹ́tì, wọ́n sì sín in sí ibi ìsìnkú Ábínérì ní Hébúrónì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé