Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Sámúẹ́lì 3:1-39

3  Ogun tí ó wà láàárín ilé Sọ́ọ̀lù àti ilé Dáfídì sì wá jẹ́ èyí tí a fà gùn lọ títí;+ Dáfídì sì túbọ̀ ń di alágbára,+ ilé Sọ́ọ̀lù sì túbọ̀ ń lọ sílẹ̀ sí i.+  Láàárín àkókò yìí, a bí àwọn ọmọ+ fún Dáfídì ní Hébúrónì,+ àkọ́bí rẹ̀ sì wá jẹ́ Ámínónì+ nípasẹ̀ Áhínóámù+ ọmọbìnrin ará Jésíréélì.  Ìkejì sì ni Kíléábù+ nípasẹ̀ Ábígẹ́lì+ aya Nábálì ará Kámẹ́lì, ìkẹta sì ni Ábúsálómù+ ọmọkùnrin Máákà ọmọbìnrin Tálímáì+ ọba Géṣúrì.  Ìkẹrin sì ni Ádóníjà+ ọmọkùnrin Hágítì,+ ìkarùn-ún sì ni Ṣẹfatáyà+ ọmọkùnrin Ábítálì.  Ìkẹfà sì ni Ítíréámù+ nípasẹ̀ Ẹ́gílà, aya Dáfídì. Ìwọ̀nyí ni àwọn tí a bí fún Dáfídì ní Hébúrónì.  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí ogun tí ó wà láàárín ilé Sọ́ọ̀lù àti ilé Dáfídì ti ń bá a nìṣó, Ábínérì+ alára ń bá a lọ ní fífún ipò rẹ̀ lókun ní ilé Sọ́ọ̀lù.  Wàyí o, Sọ́ọ̀lù ní wáhàrì kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rísípà,+ ọmọbìnrin Áyà.+ Lẹ́yìn náà, Iṣi-bóṣẹ́tì+ sọ fún Ábínérì pé: “Èé ṣe tí o fi ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú wáhàrì+ baba mi?”  Inú sì bí Ábínérì gidigidi+ sí àwọn ọ̀rọ̀ Iṣi-bóṣẹ́tì, ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Ṣé orí ajá+ tí ó jẹ́ ti Júdà ni mí ni? Lónìí, mo ń bá a nìṣó ní ṣíṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí ilé Sọ́ọ̀lù baba rẹ, sí àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, èmi kò sì jẹ́ kí o bá ara rẹ ní ọwọ́ Dáfídì; síbẹ̀, o pè mí wá jíhìn fún ìṣìnà nípa obìnrin lónìí.  Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ṣe sí Ábínérì, bẹ́ẹ̀ ni kí ó sì fi kún un,+ bí kì í bá ṣe pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti búra fún Dáfídì,+ ni èmi yóò ṣe sí i, 10  láti lè ṣí ìjọba náà nípò padà kúrò ní ilé Sọ́ọ̀lù, àti láti fìdí ìtẹ́ Dáfídì múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì àti lórí Júdà láti Dánì dé Bíá-ṣébà.”+ 11  Òun kò sì lè sọ ẹyọ ọ̀rọ̀ kan mọ́ láti fi fèsì fún Ábínérì nítorí tí ó fòyà rẹ̀.+ 12  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ábínérì rán àwọn ońṣẹ́ sí Dáfídì lójú ẹsẹ̀, pé: “Ti ta ni ilẹ̀ náà jẹ́?” ó fi kún un pé: “Bá mi dá májẹ̀mú rẹ, sì wò ó! ọwọ́ mi yóò wà pẹ̀lú rẹ láti yí gbogbo Ísírẹ́lì síhà ọ̀dọ̀ rẹ.”+ 13  Ó fèsì pé: “Ó dára! Èmi alára yóò bá ọ dá májẹ̀mú. Kì kì ohun kan ni ó wà tí mo ń béèrè lọ́wọ́ rẹ, pé, ‘Kí ìwọ má ṣe rí ojú mi+ bí kò ṣe pé kí o kọ́kọ́ mú Míkálì,+ ọmọbìnrin Sọ́ọ̀lù wá, nígbà tí o bá ń bọ̀ láti rí ojú mi.’” 14  Síwájú sí i, Dáfídì rán àwọn ońṣẹ́ sí Iṣi-bóṣẹ́tì,+ ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù, pé: “Fi Míkálì aya mi lé mi lọ́wọ́, ẹni tí mo fi ọgọ́rùn-ún adọ̀dọ́+ àwọn Filísínì fẹ́ fún ara mi.” 15  Nítorí náà, Iṣi-bóṣẹ́tì ránṣẹ́, ó sì gbà á lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀, Pálítíélì+ ọmọkùnrin Láíṣì. 16  Ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ ń bá a rìn nìṣó, ó ń sunkún bí ó ti ń rìn tẹ̀ lé e títí dé Báhúrímù.+ Nígbà náà ni Ábínérì sọ fún un pé: “Máa wá padà lọ!” Látàrí ìyẹn, ó padà. 17  Láàárín àkókò yìí, Ábínérì ti ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì, pé: “Àti ní àná àti tẹ́lẹ̀ rí,+ ẹ ti fi ara yín hàn pé ẹ ń wá Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba lórí yín. 18  Wàyí o, ẹ gbé ìgbésẹ̀, nítorí Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ fún Dáfídì pé, ‘Nípa ọwọ́ Dáfídì+ ìránṣẹ́ mi ni èmi yóò gba àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì là kúrò lọ́wọ́ àwọn Filísínì àti lọ́wọ́ gbogbo ọ̀tá wọn.’” 19  Nígbà náà ni Ábínérì tún sọ̀rọ̀ ní etí Bẹ́ńjámínì,+ lẹ́yìn èyí tí Ábínérì tún lọ sọ gbogbo èyí tí ó dára ní ojú Ísírẹ́lì àti ní ojú gbogbo ilé Bẹ́ńjámínì ní etí Dáfídì ní Hébúrónì. 20  Nígbà tí Ábínérì dé ọ̀dọ̀ Dáfídì ní Hébúrónì, àti ogún ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀, Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí se àsè+ fún Ábínérì àti fún àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀. 21  Nígbà náà ni Ábínérì sọ fún Dáfídì pé: “Jẹ́ kí n dìde, kí n sì lọ kó gbogbo Ísírẹ́lì jọpọ̀ sọ́dọ̀ olúwa mi ọba, kí wọ́n lè bá ọ dá májẹ̀mú, dájúdájú, ìwọ yóò sì di ọba lórí gbogbo èyí tí ọkàn rẹ fà sí.”+ Nítorí náà, Dáfídì rán Ábínérì lọ, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n ní àlàáfíà.+ 22  Sì kíyè sí i, àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì àti Jóábù ń bọ̀ láti ibi ìgbésùnmọ̀mí, ohun ìfiṣèjẹ+ tí wọ́n kó wá pẹ̀lú wọn sì pọ̀ yanturu. Ní ti Ábínérì, òun kò sí lọ́dọ̀ Dáfídì ní Hébúrónì, nítorí ó ti rán an lọ, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ ní àlàáfíà. 23  Jóábù+ àti gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì wọlé, wọ́n sì ròyìn fún Jóábù wàyí, pé: “Ábínérì+ ọmọkùnrin Nérì+ wá sọ́dọ̀ ọba, ó sì tẹ̀ síwájú láti rán an lọ, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ ní àlàáfíà.” 24  Nítorí náà, Jóábù wọlé lọ bá ọba, ó sì wí pé: “Kí ni ìwọ ṣe?+ Wò ó! Ábínérì wá sọ́dọ̀ rẹ. Èé ṣe tí ìwọ fi rán an lọ tí ó fi lọ pẹ̀lú àṣeyọrísírere? 25  Ìwọ mọ Ábínérì ọmọkùnrin Nérì dáadáa, pé láti tàn ọ́ ni ó fi wá, kí ó sì mọ jíjáde lọ rẹ àti wíwọlé rẹ,+ kí ó sì mọ ohun gbogbo tí ìwọ ń ṣe.”+ 26  Pẹ̀lú ìyẹn, Jóábù jáde kúrò lọ́dọ̀ Dáfídì, ó sì rán àwọn ońṣẹ́ tẹ̀ lé Ábínérì, wọ́n sì dá a padà+ nígbà náà láti ibi ìkùdu Sírà; Dáfídì alára kò sì mọ̀ nípa rẹ̀. 27  Nígbà tí Ábínérì padà sí Hébúrónì,+ Jóábù wá mú un lọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nínú ẹnubodè láti bá a sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́.+ Bí ó ti wù kí ó rí, ibẹ̀ ni ó ti kọlù ú ní inú,+ tí ó fi kú nítorí ẹ̀jẹ̀ Ásáhélì+ arákùnrin rẹ̀. 28  Nígbà tí Dáfídì gbọ́ nípa èyí lẹ́yìn ìgbà náà, ó sọ lójú ẹsẹ̀ pé: “Ní ojú ìwòye Jèhófà, èmi àti ìjọba mi jẹ́ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin nípa ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀+ Ábínérì ọmọkùnrin Nérì. 29  Kí ó yí dà sórí+ Jóábù àti sórí gbogbo ilé baba rẹ̀ pátá, kí ọkùnrin tí ó ní àsunjáde+ tàbí tí ó jẹ́ adẹ́tẹ̀+ tàbí ọkùnrin tí ń di ìrànwú ayíbíríbírí mú+ tàbí ẹni tí ń tipa idà ṣubú tàbí ẹni tí ó ṣaláìní oúnjẹ+ má sì di àfẹ́kù ní ilé Jóábù!”+ 30  Ní ti Jóábù àti Ábíṣáì+ arákùnrin rẹ̀, wọ́n pa Ábínérì+ nítorí òtítọ́ náà pé ó fi ikú pa Ásáhélì arákùnrin wọn ní Gíbéónì nínú ìjà ogun.+ 31  Nígbà náà ni Dáfídì sọ fún Jóábù àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Ẹ gbọn ẹ̀wù yín ya,+ ẹ sì so aṣọ àpò ìdọ̀họ+ mọ́ra, kí ẹ sì pohùn réré ẹkún níwájú Ábínérì.” Àní Dáfídì Ọba pàápàá ń rìn lẹ́yìn ìrọ̀gbọ̀kú náà. 32  Wọ́n sì sìnkú Ábínérì ní Hébúrónì; ọba sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì sunkún ní ibi ìsìnkú Ábínérì, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún.+ 33  Ọba sì ń bá a lọ láti sun rárà lórí Ábínérì, ó sì wí pé: “Ó ha yẹ kí Ábínérì kú ikú òpònú+ bí? 34  A kò de ọwọ́ rẹ,+ A kò sì ti ẹsẹ̀ rẹ bọ ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà.+ Gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń ṣubú níwájú àwọn ọmọ àìṣòdodo+ ni ìwọ ṣubú.” Látàrí ìyẹn, gbogbo àwọn ènìyàn náà tún sunkún+ lórí rẹ̀. 35  Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ènìyàn náà wá láti fún Dáfídì ní oúnjẹ+ ìtùnú nígbà tí ọjọ́ yẹn kò tíì kọjá, ṣùgbọ́n Dáfídì búra, pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ṣe sí mi,+ bẹ́ẹ̀ ni kí ó sì fi kún un, bí èmi yóò bá tọ́ oúnjẹ tàbí ohunkóhun wò kí oòrùn tó wọ̀!”+ 36  Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì ṣàkíyèsí, ó sì dára ní ojú wọn. Gẹ́gẹ́ bí ohun gbogbo tí ọba ṣe, ó dára ní ojú gbogbo àwọn ènìyàn náà.+ 37  Gbogbo àwọn ènìyàn náà àti gbogbo Ísírẹ́lì sì wá mọ̀ ní ọjọ́ yẹn pé kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ọba pé kí a ṣe ikú pa Ábínérì ọmọkùnrin Nérì.+ 38  Ọba sì ń bá a lọ láti sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé ọmọ aládé àti ènìyàn ńlá ni ó ṣubú lónìí yìí ní Ísírẹ́lì?+ 39  Èmi sì jẹ́ aláìlera lónìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fòróró yàn+ mí ṣe ọba, àti àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, àwọn ọmọkùnrin Seruáyà,+ ti le koko jù fún mi.+ Kí Jèhófà san án padà fún olùṣe ohun tí ó burú gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú rẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé