Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Sámúẹ́lì 24:1-25

24  Ìbínú Jèhófà sì tún+ wá gbóná sí Ísírẹ́lì, nígbà tí ẹnì kan ru Dáfídì lọ́kàn sókè sí wọn, pé: “Lọ, ka iye+ Ísírẹ́lì àti Júdà.”  Nítorí náà, ọba sọ fún Jóábù+ olórí àwọn ẹgbẹ́ ológun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, rìn kiri jákèjádò gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, láti Dánì dé Bíá-ṣébà,+ kí ẹ sì forúkọ àwọn ènìyàn náà sílẹ̀,+ dájúdájú, èmi yóò sì mọ iye àwọn ènìyàn náà.”+  Ṣùgbọ́n Jóábù sọ fún ọba pé: “Kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tilẹ̀ fi kún àwọn ènìyàn náà ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún iye tí wọ́n jẹ́ nígbà tí ojú olúwa mi ọba ń rí i. Ṣùgbọ́n ní ti olúwa mi ọba, èé ṣe tí ó fi ní inú dídùn sí nǹkan yìí?”+  Níkẹyìn, ọ̀rọ̀ ọba borí+ Jóábù àti àwọn olórí ẹgbẹ́ ológun. Nítorí náà, Jóábù àti àwọn olórí ẹgbẹ́ ológun jáde kúrò níwájú ọba láti forúkọ+ àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì sílẹ̀.  Nígbà náà ni wọ́n sọdá Jọ́dánì, wọ́n sì pabùdó sí Áróérì,+ sí apá ọ̀tún ìlú ńlá tí ó wà ní àárín àfonífojì olójú ọ̀gbàrá, síhà ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Gádì,+ àti sí Jásérì.+  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n wá sí Gílíádì+ àti ilẹ̀ Tatimu-hódíṣì, wọ́n sì ń bá a lọ títí dé Dani-jáánì, wọ́n sì lọ yí ká dé Sídónì.+  Lẹ́yìn náà, wọ́n wá sí odi agbára Tírè+ àti gbogbo ìlú ńlá àwọn Hífì+ àti ti àwọn ọmọ Kénáánì, wọ́n sì wá sí ibi tí ó dópin sí ní Négébù+ ti Júdà ní Bíá-ṣébà.+  Bí wọ́n ṣe rìn kiri jákèjádò gbogbo ilẹ̀ náà nìyẹn, wọ́n sì wá sí Jerúsálẹ́mù ní òpin oṣù mẹ́sàn-án atí ogún ọjọ́.  Wàyí o, Jóábù fi iye ìforúkọsílẹ̀+ àwọn ènìyàn náà fún ọba; Ísírẹ́lì sì jẹ́ ogójì ọ̀kẹ́ àwọn akíkanjú ọkùnrin tí ń fa idà yọ, àwọn ọkùnrin Júdà sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n.+ 10  Ọkàn-àyà Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí nà+ án lẹ́yìn tí ó ti ka iye àwọn ènìyàn náà. Nítorí náà, Dáfídì sọ fún Jèhófà pé: “Mo ti ṣẹ̀+ gidigidi nínú ohun tí mo ti ṣe. Wàyí o, Jèhófà, jọ̀wọ́, jẹ́ kí ìṣìnà ìránṣẹ́ rẹ kọjá lọ;+ nítorí mo ti hùwà òmùgọ̀ gan-an.”+ 11  Nígbà tí Dáfídì sì dìde ní òwúrọ̀, ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Gádì+ wòlíì wá, olùríran+ fún Dáfídì, pé: 12  “Lọ, kí o sì sọ fún Dáfídì pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ohun mẹ́ta ni èmi yóò gbé kà ọ́ lórí.+ Yan ọ̀kan nínú wọn fún ara rẹ, kí èmi lè ṣe é sí ọ.”’”+ 13  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Gádì wọlé lọ bá Dáfídì, ó sì sọ fún un, ó sì wí fún un pé:+ “Ṣé kí ìyàn ọdún méje wá bá ọ ní ilẹ̀ rẹ,+ tàbí oṣù mẹ́ta tí ìwọ yóò fi máa sá níwájú àwọn elénìní rẹ,+ tí wọn yóò sì máa lépa rẹ, tàbí kí àjàkálẹ̀ àrùn ọjọ́ mẹ́ta ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ rẹ?+ Wàyí o, mọ̀ kí o sì wá ohun tí èmi yóò fi fèsì fún Ẹni tí ó rán mi.” 14  Nítorí náà, Dáfídì sọ fún Gádì pé: “Èyí mú wàhálà-ọkàn bá mi gidigidi. Jọ̀wọ́, jẹ́ kí a ṣubú sí ọwọ́ Jèhófà,+ nítorí àánú rẹ̀ pọ̀;+ ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí n ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn.”+ 15  Nígbà náà ni Jèhófà mú àjàkálẹ̀ àrùn+ bá Ísírẹ́lì láti òwúrọ̀ títí di àkókò tí a yàn kalẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ ènìyàn kú+ nínú àwọn ènìyàn náà láti Dánì títí dé Bíá-ṣébà.+ 16  Áńgẹ́lì+ náà sì ń bá a nìṣó ní nína ọwọ́ rẹ̀ jáde sí Jerúsálẹ́mù láti mú ìparun wá bá a; Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́dùn+ nítorí ìyọnu àjálù náà, nítorí náà, ó sọ fún áńgẹ́lì tí ń mú ìparun wá sí àárín àwọn ènìyàn náà pé: “Ó tó! Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ wálẹ̀ wàyí.” Áńgẹ́lì Jèhófà sì wà nítòsí ilẹ̀ ìpakà Áráúnà+ ará Jébúsì.+ 17  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Jèhófà, nígbà tí ó rí áńgẹ́lì tí ń ṣá àwọn ènìyàn balẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Kíyè sí i, èmi ni ó ṣẹ̀, èmi sì ni ó ṣe àìtọ́; ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn wọ̀nyí+—kí ni wọ́n ṣe? Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ wà lára mi+ àti lára ilé baba mi.” 18  Lẹ́yìn náà, Gádì wọlé wá bá Dáfídì ní ọjọ́ yẹn, ó sì wí fún un pé: “Gòkè lọ, gbé pẹpẹ kan kalẹ̀ fún Jèhófà ní ilẹ̀ ìpakà Áráúnà ará Jébúsì.”+ 19  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Gádì gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jèhófà pa láṣẹ.+ 20  Nígbà tí Áráúnà wo ìsàlẹ̀, tí ó sì rí ọba àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń kọjá síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀, ní kíá, Áráúnà jáde lọ, ó sì tẹrí+ ba fún ọba ní dídojúbolẹ̀.+ 21  Lẹ́yìn náà, Áráúnà sọ pé: “Èé ṣe tí olúwa mi ọba fi wá sọ́dọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀?” Látàrí ìyẹn, Dáfídì sọ pé: “Láti ra+ ilẹ̀ ìpakà yìí lọ́wọ́ rẹ fún mímọ pẹpẹ kan fún Jèhófà, kí a lè dáwọ́ òjòjò àrànkálẹ̀+ náà dúró lára àwọn ènìyàn náà.” 22  Ṣùgbọ́n Áráúnà sọ fún Dáfídì pé: “Kí olúwa mi ọba mú un,+ kí ó sì fi ohun tí ó bá dára ní ojú rẹ̀ rúbọ. Wo màlúù fún ọrẹ ẹbọ sísun àti ohun èlò ìpakà àti àwọn ohun èlò tí màlúù ń lò fún igi.+ 23  Ọba, ohun gbogbo ni Áráúnà fi fún ọba.” Áráúnà sì ń bá a lọ láti sọ fún ọba pé: “Kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi ìdùnnú hàn sí ọ.”+ 24  Bí ó ti wù kí ó rí, ọba sọ fún Áráúnà pé: “Rárá, ṣùgbọ́n láìkùnà, èmi yóò rà á lọ́wọ́ rẹ ní iye owó kan;+ èmi kì yóò sì rú àwọn ẹbọ sísun sí Jèhófà Ọlọ́run mi láìná nǹkan kan.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Dáfídì ra+ ilẹ̀ ìpakà náà àti màlúù náà ní àádọ́ta ṣékélì fàdákà. 25  Dáfídì sì tẹ̀ síwájú láti mọ pẹpẹ+ kan síbẹ̀ fún Jèhófà, ó sì rú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀, Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́ kí a pàrọwà+ sí òun nítorí ilẹ̀ náà, tí ó fi jẹ́ pé a dáwọ́ òjòjò àrànkálẹ̀ náà dúró lára Ísírẹ́lì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé