Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Sámúẹ́lì 22:1-51

22  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ọ̀rọ̀ orin yìí+ fún Jèhófà ní ọjọ́ tí Jèhófà dá a nídè kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá+ rẹ̀ àti kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ Sọ́ọ̀lù;+  ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Jèhófà ni àpáta gàǹgà+ mi àti odi agbára+ mi àti Olùpèsè àsálà fún mi.+  Ọlọ́run mi ni àpáta mi.+ Èmi yóò sá di í, Apata+ mi àti ìwo+ ìgbàlà mi, ibi gíga ààbò mi,+ Àti ibi ìsásí mi,+ Olùgbàlà mi;+ ìwọ gbà mí là kúrò nínú ìwà ipá.+  Jèhófà, ẹni tí ó yẹ fún ìyìn,+ ni èmi yóò ké pè, A ó sì gbà mí là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.+  Nítorí àwọn ìgbì aṣekúpani tí ń fọ́n ká di ìfóófòó ká mi mọ́;+ Ìkún omi ayaluni lójijì ti àwọn ènìyàn tí kò dára fún ohunkóhun wà tí ń kó ìpayà bá mi ṣáá.+  Àwọn ìjàrá Ṣìọ́ọ̀lù yí mi ká;+ Àwọn ìdẹkùn ikú kò mí lójú.+  Mo ń ké pe Jèhófà ṣáá nínú wàhálà mi,+ Mo sì ń pe Ọlọ́run mi.+ Nígbà náà, ó gbọ́ ohùn mi láti inú tẹ́ńpìlì rẹ̀,+ Pẹ̀lú igbe mi fún ìrànlọ́wọ́ ní etí rẹ̀.+  Ilẹ̀ ayé sì bẹ̀rẹ̀ sí mì síwá-sẹ́yìn, ó sì mì jì gìjì gì;+ Ṣìbáṣìbo bá àwọn ìpìlẹ̀ ọ̀run,+ Wọ́n sì ń mì síwá-sẹ́yìn nítorí pé a ti mú un bínú.+  Èéfín gòkè lọ láti ihò imú rẹ̀, iná láti ẹnu rẹ̀ sì ń jẹ run nìṣó;+ Àwọn ẹyín iná sì ń jó láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.+ 10  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ ọ̀run wálẹ̀, ó sì sọ̀ kalẹ̀;+ Ìṣúdùdù nínípọn sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.+ 11  Ó sì ń gun kérúbù+ bọ̀, ó sì ń fò bọ̀; Ó sì di rírí lórí àwọn ìyẹ́ apá ẹ̀mí kan.+ 12  Nígbà náà ni ó fi òkùnkùn yí ara rẹ̀ ká gẹ́gẹ́ bí àwọn àtíbàbà,+ Omi ṣíṣú, àwọsánmà nínípọn.+ 13  Láti inú ìtànyòò tí ó wà ní iwájú rẹ̀ ni ẹyín iná ti ń jó.+ 14  Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí sán ààrá láti ọ̀run,+ Ẹni Gíga Jù Lọ sì bẹ̀rẹ̀ sí fọ ohùn rẹ̀ jáde.+ 15  Ó sì ń rán àwọn ọfà jáde ṣáá, kí ó lè tú wọn ká;+ Mànàmáná, kí ó lè kó wọn sínú ìdàrúdàpọ̀.+ 16  Ojú ìṣàn omi òkun sì di rírí,+ Àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ eléso+ di títú síta, Nípa ìbáwí mímúná Jèhófà, láti inú ìtújáde èémí ihò imú rẹ̀.+ 17  Ó ń ránṣẹ́ láti ibi gíga lókè, ó ń mú mi,+ Ó ń fà mí jáde kúrò nínú omi púpọ̀.+ 18  Ó ń dá mi nídè kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,+ Kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi; nítorí pé wọ́n lágbára jù mí.+ 19  Wọ́n ń kò mí lójú ṣáá ní ọjọ́ àjálù mi,+ Ṣùgbọ́n Jèhófà di ìtìlẹyìn mi.+ 20  Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú mi jáde sí ibi aláyè gbígbòòrò;+ Ó ń gbà mí sílẹ̀, nítorí pé ó ní inú dídùn sí mi.+ 21  Jèhófà san mí lẹ́san gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;+ Ó san án padà fún mi gẹ́gẹ́ bí ìmọ́tónítóní ọwọ́ mi.+ 22  Nítorí mo ti pa àwọn ọ̀nà Jèhófà mọ́,+ Èmi kò sì fi Ọlọ́run mi sílẹ̀ lọ́nà burúkú.+ 23  Nítorí gbogbo ìpinnu ìdájọ́+ rẹ̀ wà ní iwájú mi; Àti ní ti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀, èmi kì yóò yapa kúrò nínú wọn.+ 24  Èmi yóò sì fi ara mi hàn ní aláìní-àléébù+ sí i, Dájúdájú, èmi yóò sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ìṣìnà níhà ọ̀dọ̀ mi.+ 25  Kí Jèhófà sì san án padà fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,+ Gẹ́gẹ́ bí ìmọ́tónítóní mi ní iwájú rẹ̀.+ 26  Ìwọ yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin;+ Ìwọ yóò bá aláìní-àléébù, alágbára ńlá lò lọ́nà àìlálèébù;+ 27  Sí ẹni tí ó mọ́, ìwọ yóò fi ara rẹ hàn ní ẹni tí ó mọ́;+ Sí oníwà wíwọ́, ìwọ yóò ṣe bí ọ̀dẹ̀.+ 28  Àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ìwọ yóò sì gbà là;+ Ṣùgbọ́n ojú rẹ lòdì sí àwọn onírera, kí o lè rẹ̀ wọ́n wálẹ̀.+ 29  Nítorí ìwọ ni fìtílà mi, Jèhófà,+ Jèhófà sì ni ó mú kí òkùnkùn mi mọ́lẹ̀.+ 30  Nítorí nípasẹ̀ rẹ, mo lè sáré ní ìgbéjàko ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí;+ Nípasẹ̀ Ọlọ́run mi, mo lè gun ògiri.+ 31  Ní ti Ọlọ́run tòótọ́, pípé ni ọ̀nà rẹ̀;+ Àsọjáde Jèhófà jẹ́ èyí tí a yọ́ mọ́.+ Apata ni ó jẹ́ fún gbogbo àwọn tí ń sá di í.+ 32  Nítorí pé ta ni Ọlọ́run, yàtọ̀ sí Jèhófà,+ Ta sì ni àpáta, yàtọ̀ sí Ọlọ́run wa?+ 33  Ọlọ́run tòótọ́ ni odi agbára mi tí ó lókun,+ Òun yóò sì mú kí ọ̀nà mi jẹ́ pípé,+ 34  Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ti egbin;+ Ó sì mú mi dúró sórí àwọn ibi tí ó ga fún mi.+ 35  Ó ń kọ́ ọwọ́ mi fún ogun;+ Apá mi sì ti tẹ ọrun bàbà.+ 36  Ìwọ yóò sì fún mi ní apata ìgbàlà rẹ,+ Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rẹ sì ni ó sọ mí di ńlá.+ 37  Ìwọ yóò ṣe àyè tí ó tóbi tó fún àwọn ìṣísẹ̀ mi lábẹ́ mi;+ Dájúdájú, ọrùn ẹsẹ̀ mi kì yóò gbò yèpéyèpé.+ 38  Ṣe ni èmi yóò lépa àwọn ọ̀tá mi, kí n lè pa wọ́n rẹ́ ráúráú, Èmi kì yóò sì padà, títí wọn yóò fi pa run pátápátá.+ 39  Èmi yóò sì pa wọ́n run pátápátá, èmi yóò sì ṣẹ́ wọn sí wẹ́wẹ́,+ kí wọ́n má bàa dìde mọ́;+ Wọn yóò sì ṣubú lábẹ́ ẹsẹ̀ mi.+ 40  Ìwọ yóò sì fi ìmí dì mí lámùrè fún ìjà ogun;+ Ìwọ yóò mú kí àwọn tí ó dìde sí mi wó lulẹ̀ lábẹ́ mi.+ 41  Àti ní ti àwọn ọ̀tá mi, ìwọ yóò fún mi ní ẹ̀yìn ọrùn [wọn] dájúdájú;+ Àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà gbígbóná janjan—èmi yóò pa wọ́n lẹ́nu mọ́ pẹ̀lú.+ 42  Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò sí olùgbàlà kankan;+ Sí Jèhófà, ṣùgbọ́n kò dá wọn lóhùn ní ti tòótọ́.+ 43  Èmi yóò sì gún wọn kúnná bí ekuru ilẹ̀;+ Bí ẹrẹ̀ ojú pópó ni èmi yóò lọ̀ wọ́n lúúlúú; Èmi yóò lù wọ́n di pẹrẹsẹ. 44  Ìwọ yóò sì pèsè àsálà fún mi kúrò lọ́wọ́ àléébù wíwá àwọn ènìyàn mi.+ Ìwọ yóò fi ìṣọ́ ṣọ́ mi kí n lè jẹ́ olórí àwọn orílẹ̀-èdè;+ Àwọn ènìyàn tí èmi kò mọ̀—wọn yóò sìn mí.+ 45  Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè alára yóò wá fi ìwárìrì tẹrí ba fún mi;+ Àwọn etí yóò jẹ́ onígbọràn láti gbọ́ mi.+ 46  Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè alára yóò pòórá, Wọn yóò sì fi ìwárìrì jáde wá láti inú odi ààbò wọn.+ 47  Jèhófà ń bẹ;+ ìbùkún sì ni fún Àpáta mi;+ Kí a sì gbé Ọlọ́run àpáta ìgbàlà mi ga.+ 48  Ọlọ́run tòótọ́ ni Olùpèsè ìgbẹ̀san fún mi+ Àti Ẹni tí ń rẹ àwọn ènìyàn sílẹ̀ lábẹ́ mi,+ 49  Àti Ẹni tí ń mú mi jáde kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.+ Ìwọ yóò sì gbé mi lékè àwọn tí ń dìde sí mi;+ Ìwọ yóò dá mi nídè kúrò lọ́wọ́ ènìyàn oníwà ipá.+ 50  Ìdí nìyẹn tí èmi yóò fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Jèhófà, láàárín àwọn orílẹ̀-èdè;+ Èmi yóò sì kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ:+ 51  Ẹni tí ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìgbàlà ńlá fún ọba rẹ̀,+ Tí ó sì ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí ẹni àmì òróró rẹ̀,+ Sí Dáfídì àti sí irú-ọmọ rẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé