Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Sámúẹ́lì 21:1-22

21  Wàyí o, ìyàn+ kan mú ní àwọn ọjọ́ Dáfídì fún ọdún mẹ́ta, láti ọdún dé ọdún; Dáfídì sì tẹ̀ síwájú láti wádìí ọ̀rọ̀ níwájú Jèhófà. Nígbà náà ni Jèhófà sọ pé: “Ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wà lórí Sọ́ọ̀lù àti lórí ilé rẹ̀, nítorí pé ó fi ikú pa àwọn ará Gíbéónì.”+  Nítorí náà, ọba pe àwọn ará Gíbéónì,+ ó sì bá wọn sọ̀rọ̀. (Ó ṣẹlẹ̀ pé, àwọn ará Gíbéónì kì í ṣe ara àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ ara ìyókù nínú àwọn Ámórì;+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì alára sì ti búra fún wọn,+ ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù wá ọ̀nà láti ṣá wọn balẹ̀+ nítorí jíjowú tí ó ń jowú+ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Júdà.)  Dáfídì sì ń bá a lọ láti sọ fún àwọn ará Gíbéónì pé: “Kí ni èmi yóò ṣe fún yín, kí ni èmi yóò sì fi ṣe ètùtù,+ kí ẹ lè súre fún ogún+ Jèhófà dájúdájú?”  Nítorí náà, àwọn ará Gíbéónì sọ fún un pé: “Ọ̀ràn tí ó wà láàárín àwa àti Sọ́ọ̀lù àti agbo ilé rẹ̀ kì í ṣe ọ̀ràn fàdákà tàbí wúrà,+ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe tiwa láti fi ikú pa ọkùnrin kan ní Ísírẹ́lì.” Látàrí ìyẹn, ó sọ pé: “Ohun yòówù tí ẹ bá wí ni èmi yóò ṣe fún yín.”  Látàrí èyí, wọ́n sọ fún ọba pé: “Ọkùnrin tí ó pa wá run pátápátá,+ tí ó sì pète-pèrò+ láti pa wá rẹ́ ráúráú kúrò ní wíwà láàyè títí lọ nínú èyíkéyìí lára ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì,  jẹ́ kí a fi ọkùnrin méje nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún wa;+ àwa yóò sì gbé wọn síta+ síwájú Jèhófà ní Gíbíà+ ti Sọ́ọ̀lù, àyànfẹ́ Jèhófà.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ọba sọ pé: “Èmi fúnra mi yóò fi wọ́n fún yín.”  Bí ó ti wù kí ó rí, ọba ní ìyọ́nú sí Mefibóṣẹ́tì+ ọmọkùnrin Jónátánì ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù ní tìtorí ìbúra+ Jèhófà tí ó wà láàárín wọn, láàárín Dáfídì àti Jónátánì ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù.  Nítorí náà, ọba mú àwọn ọmọkùnrin méjèèjì ti Rísípà+ ọmọbìnrin Áyà tí ó bí fún Sọ́ọ̀lù, Árímónì àti Mefibóṣẹ́tì, àti àwọn ọmọkùnrin márààrún ti Míkálì+ ọmọbìnrin Sọ́ọ̀lù tí ó bí fún Ádíríélì+ ọmọkùnrin Básíláì tí í ṣe Méhólátì.  Nígbà náà ni ó fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn ará Gíbéónì, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti gbé wọn síta lórí òkè ńlá níwájú Jèhófà,+ tí ó fi jẹ́ pé àwọn méjèèje ṣubú pa pọ̀; a sì fi ikú pa wọ́n ní àwọn ọjọ́ àkọ́kọ́ ìkórè, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà bálì.+ 10  Bí ó ti wù kí ó rí, Rísípà ọmọbìnrin Áyà+ mú aṣọ àpò ìdọ̀họ,+ ó sì tẹ́ ẹ fún ara rẹ̀ sórí àpáta náà láti ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè títí omi fi dà sórí wọn láti ọ̀run;+ kò sì jẹ́ kí àwọn ẹ̀dá abìyẹ́+ ojú ọ̀run bà lé wọn ní ọ̀sán tàbí àwọn ẹranko+ inú pápá ní òru. 11  Níkẹyìn, a ròyìn+ fún Dáfídì nípa ohun tí Rísípà ọmọbìnrin Áyà, wáhàrì Sọ́ọ̀lù, ṣe. 12  Nítorí náà, Dáfídì lọ, ó sì kó egungun Sọ́ọ̀lù+ àti egungun Jónátánì ọmọkùnrin rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn onílẹ̀ Jabẹṣi-gílíádì,+ tí ó jí wọn ní ojúde ìlú Bẹti-ṣánì,+ níbi tí àwọn Filísínì gbé wọn kọ́+ sí ní ọjọ́ tí àwọn Filísínì ṣá Sọ́ọ̀lù balẹ̀ ní Gíbóà.+ 13  Ó sì tẹ̀ síwájú láti kó egungun Sọ́ọ̀lù àti egungun Jónátánì ọmọkùnrin rẹ̀ gòkè wá láti ibẹ̀; pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n kó egungun àwọn ọkùrnin tí a gbé síta jọ.+ 14  Nígbà náà ni wọ́n sin egungun Sọ́ọ̀lù àti ti Jónátánì ọmọkùnrin rẹ̀ sí ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì ní Sẹ́là+ ní ibi ìsìnkú Kíṣì+ baba rẹ̀, kí wọ́n lè ṣe gbogbo ohun tí ọba pa láṣẹ. Nítorí náà, Ọlọ́run jẹ́ kí a pàrọwà sí òun nítorí ilẹ̀ náà lẹ́yìn èyí.+ 15  Àwọn Filísínì+ sì tún wá bá Ísírẹ́lì ja ogun. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Dáfídì àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ sọ̀ kalẹ̀, wọ́n sì bá àwọn Filísínì jà; ó sì rẹ Dáfídì. 16  Iṣibi-bénóbù, tí ó jẹ́ ara àwọn tí a bí fún àwọn Réfáímù,+ ẹni tí ìwọ̀n ọ̀kọ̀+ rẹ̀ jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún ṣékélì bàbà, tí ó sì sán idà tuntun, sì ronú nípa ṣíṣá Dáfídì balẹ̀. 17  Ní kíá, Ábíṣáì+ ọmọkùnrin Seruáyà wá ràn án lọ́wọ́,+ ó sì ṣá Filísínì náà balẹ̀, ó sì fi ikú pa á. Ní àkókò yẹn, àwọn ọkùnrin Dáfídì búra fún un, pé: “Ìwọ kì yóò tún bá wa jáde lọ sójú ìjà ogun mọ́,+ kí o má bàa fẹ́ fìtílà+ Ísírẹ́lì pa!”+ 18  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí pé ogun dìde lẹ́ẹ̀kan sí i pẹ̀lú àwọn Filísínì ní Góbù. Nígbà náà ni Síbékáì+ ọmọ Húṣà+ ṣá Sáfì balẹ̀, ẹni tí ó wà lára àwọn tí a bí fún àwọn Réfáímù.+ 19  Ogun sì tún dìde pẹ̀lú àwọn Filísínì ní Góbù, Élíhánánì+ ọmọkùnrin Jaare-órégímù ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù sì ṣá Gòláyátì ará Gátì balẹ̀, ẹni tí ẹ̀rú ọ̀kọ̀ rẹ̀ dà bí ìtì igi àwọn olófì.+ 20  Ogun sì tún dìde ní Gátì,+ nígbà tí ọkùnrin kan báyìí wà tí ó tóbi lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, tí ó ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ mẹ́fà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan, mẹ́rìnlélógún ní iye; òun pẹ̀lú ni a sì bí fún àwọn Réfáímù.+ 21  Ó sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣáátá+ Ísírẹ́lì. Níkẹyìn, Jónátánì+ ọmọkùnrin Ṣíméì,+ arákùnrin Dáfídì, ṣá a balẹ̀. 22  Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ni a bí fún àwọn Réfáímù ní Gátì;+ wọ́n sì wá ṣubú nípa ọwọ́ Dáfídì àti nípa ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé