Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Sámúẹ́lì 20:1-26

20  Wàyí o, ọkùnrin kan báyìí tí kò dára fún ohunkóhun+ wà níbẹ̀, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣébà,+ ọmọkùnrin Bíkíráì ọmọ Bẹ́ńjámínì; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fun ìwo,+ ó sì sọ pé: “Àwa kò ní ìpín kankan nínú Dáfídì, a kò sì ní ogún kankan nínú ọmọkùnrin Jésè.+ Kí olúkúlùkù lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run rẹ̀,+ ìwọ Ísírẹ́lì!”  Látàrí ìyẹn, gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ kúrò ní títẹ̀lé Dáfídì láti tẹ̀ lé Ṣébà ọmọkùnrin Bíkíráì;+ ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọkùnrin Júdà, wọ́n fà mọ́ ọba wọn láti Jọ́dánì títí dé Jerúsálẹ́mù.+  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Dáfídì wá sí ilé rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù.+ Nígbà náà ni ọba mú àwọn obìnrin mẹ́wàá náà,+ àwọn wáhàrì tí ó fi sílẹ̀ sẹ́yìn láti máa tọ́jú ilé, ó sì fi wọ́n sínú ilé ìsémọ́, ṣùgbọ́n ó ń bá a nìṣó láti máa pèsè oúnjẹ fún wọn. Kò sì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú wọn,+ ṣùgbọ́n a ń bá a lọ ní sísé wọn mọ́ pinpin títí di ọjọ́ tí wọ́n fi kú, nínú ipò opó pẹ̀lú ọkọ tí ń bẹ láàyè.  Ọba sọ fún Ámásà+ wàyí pé: “Pe àwọn ọkùnrin Júdà jọ sọ́dọ̀ mi láàárín ọjọ́ mẹ́ta, kí ìwọ alára sì dúró níhìn-ín.”  Nítorí náà, Ámásà lọ láti pe Júdà jọ; ṣùgbọ́n ó pẹ́ dé ju àkókò tí a dá, tí ó yàn kalẹ̀ fún un.  Nígbà náà ni Dáfídì sọ fún Ábíṣáì+ pé: “Wàyí o, Ṣébà+ ọmọkùnrin Bíkíráì yóò burú fún wa ju Ábúsálómù.+ Kí ìwọ fúnra rẹ mú àwọn ìránṣẹ́+ olúwa rẹ, kí o sì lépa rẹ̀, kí ó má bàa rí àwọn ìlú ńlá olódi fún ara rẹ̀ ní ti tòótọ́, kí ó sì sá lọ lójú wa.”  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ọkùnrin Jóábù+ àti àwọn Kérétì+ àti àwọn Pẹ́lẹ́tì+ àti gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára ńlá jáde tẹ̀ lé e; wọ́n sì jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù láti lépa Ṣébà ọmọkùnrin Bíkíráì.  Wọ́n wà ní tòsí òkúta ńlá tí ó wà ní Gíbéónì,+ Ámásà+ alára sì wá pàdé wọn. Wàyí o, Jóábù di àmùrè, ó wọ ẹ̀wù; ní ara rẹ̀ ni idà kan sì wà tí a sán, tí a so mọ́ ìgbáròkó rẹ̀, nínú àkọ̀ rẹ̀. Òun fúnra rẹ̀ sì jáde wá, idà náà sì yọ.  Jóábù sì tẹ̀ síwájú láti sọ fún Ámásà pé: “Ṣé dáadáa ni o wà, arákùnrin mi?”+ Nígbà náà ni ọwọ́ ọ̀tún Jóábù gbá irùngbọ̀n Ámásà mú kí ó bàa lè fi ẹnu kò ó lẹ́nu.+ 10  Ní ti Ámásà, kò ṣọ́ra fún idà tí ó wà ní ọwọ́ Jóábù; tí ó fi fi idà náà gún un+ ní inú, ìfun rẹ̀ sì tú síta sórí ilẹ̀, kò sì ní láti tún ṣe é sí i. Nítorí náà, ó kú. Jóábù àti Ábíṣáì arákùnrin rẹ̀, ní tiwọn, sì lépa Ṣébà ọmọkùnrin Bíkíráì. 11  Ẹnì kan lára àwọn ọ̀dọ́kùnrin Jóábù sì dúró lẹ́bàá rẹ̀, ó sì ń sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá ní inú dídùn sí Jóábù, ẹnì yòówù tí ó bá sì jẹ́ ti Dáfídì,+ kí ó tẹ̀ lé Jóábù!” 12  Ní gbogbo àkókò náà, Ámásà ń yíràá nínú ẹ̀jẹ̀+ láàárín òpópó. Nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé gbogbo ènìyàn dúró jẹ́ẹ́, nígbà náà, ó gbé Ámásà kúrò ní òpópó lọ sí pápá. Níkẹyìn, ó fi ẹ̀wù bò ó, bí ó ti rí i pé olúkúlùkù ẹni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ń dúró jẹ́ẹ́.+ 13  Gbàrà tí ó gbé e kúrò ní òpópó, olúkúlùkù ọkùnrin kọjá ní títẹ̀lé Jóábù láti lépa Ṣébà+ ọmọkùnrin Bíkíráì. 14  Ṣébà sì la gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì kọjá lọ sí Ébẹ́lì ti Bẹti-máákà.+ Ní ti gbogbo àwọn ọmọ Bíkíráì, nígbà náà, wọ́n péjọ pọ̀, wọ́n sì wọlé tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 15  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dé, wọ́n sì sàga tì í ní Ébẹ́lì ti Bẹti-máákà, wọ́n sì mọ ohun àfiṣe-odi ìsàgatì nà ró ti ìlú ńlá náà,+ níwọ̀n bí ìlú ńlá náà ti wà láàárín ohun àfiṣe-odi. Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú Jóábù sì ń jin ògiri náà lẹ́sẹ̀, láti wó o lulẹ̀. 16  Obìnrin ọlọ́gbọ́n+ kan sì bẹ̀rẹ̀ sí pè láti inú ìlú ńlá náà pé: “Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ fetí sílẹ̀! Ẹ jọ̀wọ́, ẹ sọ fún Jóábù pé, ‘Sún mọ́ tòsí títí dé ìhín, sì jẹ́ kí n bá ọ sọ̀rọ̀.’” 17  Nítorí náà, ó sún mọ́ ọn, nígbà náà, obìnrin náà sì sọ pé: “Ṣé ìwọ ni Jóábù?” ó dáhùn pé: “Èmi ni.” Látàrí èyí, ó sọ fún un pé: “Fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ ẹrúbìnrin rẹ.”+ Ẹ̀wẹ̀, ó sọ pé: “Èmi ń fetí sílẹ̀.” 18  Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Láìsí àní-àní, wọ́n máa ń sọ ní àwọn ìgbà àtijọ́, pé, ‘Kí wọ́n sáà wádìí ní Ébẹ́lì, dájúdájú, bí wọn yóò sì ti fi òpin sí ọ̀ràn náà nìyẹn.’ 19  Èmi dúró fún àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà+ àti àwọn olùṣòtítọ́+ ní Ísírẹ́lì. Ìwọ ń wá ọ̀nà láti fi ikú pa ìlú ńlá+ kan àti ìyá ní Ísírẹ́lì. Èé ṣe tí ìwọ yóò fi gbé ogún+ Jèhófà mì?”+ 20  Jóábù dáhùn, ó sì wí pé: “Kò ṣée ronú kàn rárá níhà ọ̀dọ̀ mi pé èmi yóò gbé mì àti pé èmi yóò fa ìparun. 21  Ọràn náà kò rí bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ọkùnrin kan láti ẹkùn ilẹ̀ àwọn olókè ńláńlá Éfúráímù,+ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣébà+ ọmọkùnrin Bíkíráì, ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí Dáfídì Ọba.+ Ẹ fi òun nìkan lé mi lọ́wọ́,+ èmi yóò sì fi ìlú ńlá yìí sílẹ̀+ dájúdájú.” Nígbà náà ni obìnrin náà sọ fún Jóábù pé: “Wò ó! A ó ju orí+ rẹ̀ sí ọ láti orí ògiri!” 22  Ní kíá, obìnrin náà lọ nínú ọgbọ́n+ rẹ̀ sọ́dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn náà, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti gé orí Ṣébà ọmọkùnrin Bíkíráì kúrò, wọ́n sì jù ú sí Jóábù. Látàrí ìyẹn, ó fun ìwo,+ nítorí náà, a tú wọn ká kúrò ní ìlú ńlá náà, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀; Jóábù alára sì padà sí Jerúsálẹ́mù sọ́dọ̀ ọba. 23  Jóábù sì ni ó wà lórí gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun+ Ísírẹ́lì; Bẹnáyà+ ọmọkùnrin Jèhóádà+ sì wà lórí àwọn Kérétì+ àti lórí àwọn Pẹ́lẹ́tì.+ 24  Ádórámù+ sì ni ó wà lórí àwọn tí a ń fi túláàsì mú sìn nínú òpò àfipámúniṣe; Jèhóṣáfátì+ ọmọkùnrin Áhílúdù sì ni akọ̀wé ìrántí. 25  Ṣéfà+ sì ni akọ̀wé,+ Sádókù+ àti Ábíátárì+ sì ni àlùfáà. 26  Írà ọmọ Jáírì pẹ̀lú sì di àlùfáà+ Dáfídì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé