Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Sámúẹ́lì 2:1-32

2  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà pé Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà,+ pé: “Ṣé kí n gòkè lọ sínú ọ̀kan lára àwọn ìlú ńlá Júdà?” Látàrí èyí, Jèhófà sọ fún un pé: “Gòkè lọ.” Dáfídì sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Ibo ni kí n gòkè lọ?” Nígbà náà ni ó sọ fún un pé: “Sí Hébúrónì.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Dáfídì gòkè lọ síbẹ̀ àti àwọn aya rẹ̀ méjèèjì pẹ̀lú, Áhínóámù+ ọmọbìnrin ará Jésíréélì àti Ábígẹ́lì+ aya Nábálì ará Kámẹ́lì.  Dáfídì sì mú àwọn ọkùnrin+ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ gòkè wá, olúkúlùkù pẹ̀lú agbo ilé rẹ̀; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn ìlú ńlá tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Hébúrónì.  Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Júdà+ wá, wọ́n sì fòróró yan+ Dáfídì ṣe ọba níbẹ̀ lórí ilé Júdà.+ Wọ́n sì wá sọ fún Dáfídì, pé: “Àwọn ará Jabẹṣi-gílíádì ni ó sin Sọ́ọ̀lù.”  Nítorí náà, Dáfídì rán àwọn ońṣẹ́ sí àwọn ará Jabẹṣi-gílíádì,+ ó sì wí fún wọn pé: “Kí Jèhófà bù kún yín,+ nítorí pé ẹ ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ yìí sí olúwa yín, sí Sọ́ọ̀lù, ní ti pé ẹ sin ín.+  Wàyí o, kí Jèhófà lo inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ àti ìṣeégbẹ́kẹ̀lé sí yín, èmi pẹ̀lú yóò ṣe oore yìí fún yín nítorí pé ẹ ṣe nǹkan yìí.+  Wàyí o, ẹ jẹ́ kí ọwọ́ yín fún ara rẹ̀ lókun, kí ẹ sì fi ara yín hàn ní akíkanjú ọkùnrin,+ nítorí pé Sọ́ọ̀lù olúwa yín ti kú, èmi gan-an sì ni ẹni tí ilé Júdà fòróró yàn ṣe ọba+ lórí wọn.”  Ní ti Ábínérì+ ọmọkùnrin Nérì, olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó jẹ́ ti Sọ́ọ̀lù, ó mú Iṣi-bóṣẹ́tì,+ ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù, ó sì tẹ̀ síwájú láti mú un sọdá sí Máhánáímù,+  ó sì fi í jẹ ọba lórí Gílíádì+ àti àwọn Ááṣù àti Jésíréélì+ àti lórí Éfúráímù+ àti Bẹ́ńjámínì+ àti lórí Ísírẹ́lì, gbogbo rẹ̀. 10  Ẹni ogójì ọdún ni Iṣi-bóṣẹ́tì, ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù, nígbà tí ó di ọba lórí Ísírẹ́lì, ó sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba fún ọdún méjì . Kì kì ilé Júdà+ ni ó fi ara wọn hàn ní ọmọlẹ́yìn Dáfídì. 11  Iye ọjọ́ tí Dáfídì fi jẹ́ ọba ní Hébúrónì lórí ilé Júdà sì wá jẹ́ ọdún méje àti oṣù mẹ́fà.+ 12  Nígbà tí ó ṣe, Ábínérì ọmọkùnrin Nérì àti àwọn ìránṣẹ́ Iṣi-bóṣẹ́tì, ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù, jáde kúrò ní Máhánáímù+ lọ sí Gíbéónì.+ 13  Ní ti Jóábù+ ọmọkùnrin Seruáyà+ àti àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì, wọ́n jáde lọ, wọ́n sì jọ pàdé lẹ́yìn náà lẹ́bàá odò adágún Gíbéónì; wọ́n sì jókòó, àwọn wọ̀nyí ní ìhà ìhín odò adágún náà àti àwọn wọ̀nyẹn ní ìhà ọ̀hún odò adágún náà. 14  Níkẹyìn, Ábínérì sọ fún Jóábù pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin dìde, kí wọ́n sì wọ̀jà níwájú wa.” Jóábù fèsì pé: “Kí wọ́n dìde.” 15  Nítorí náà, wọ́n dìde, wọ́n sì sọdá ní iye, méjì lá jẹ́ ti Bẹ́ńjámínì àti Iṣi-bóṣẹ́tì,+ ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù, àti méjì lá lára àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì. 16  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rá orí ẹnì kìíní-kejì mú, pẹ̀lú idà olúkúlùkù ní ẹ̀gbẹ́ ẹnì kejì , tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi jọ ṣubú lulẹ̀. Ibẹ̀ yẹn ni a sì wá pè ní Helikati-hásúrímù, èyí tí ó wà ní Gíbéónì.+ 17  Ìjà náà sì wá le dé góńgó ní ọjọ́ náà, níkẹyìn, a ṣẹ́gun Ábínérì+ àti àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì níwájú àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì. 18  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọmọkùnrin Seruáyà+ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wà níbẹ̀, Jóábù+ àti Ábíṣáì+ àti Ásáhélì;+ ẹsẹ̀ Ásáhélì sì yára, bí ọ̀kan nínú àwọn àgbàlàǹgbó+ tí ó wà ní pápá gbalasa. 19  Ásáhélì sì ń lépa Ábínérì, kò sì fẹ́ lọ sí ọ̀tún tàbí sí òsì kúrò ní títẹ̀lé Ábínérì. 20  Níkẹyìn, Ábínérì wo ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ásáhélì, ṣé ìwọ nìyí?” ó dáhùn pé: “Èmi ni.” 21  Nígbà náà ni Ábínérì sọ fún un pé: “Yà bàrá sí ọ̀tún rẹ tàbí sí òsì rẹ, kí o sì gbá ọ̀kan nínú àwọn ọ̀dọ́kùnrin mú gẹ́gẹ́ bí tìrẹ, kí o sì mú ohun tí o bá bọ́+ kúrò lára rẹ̀ ṣe tìrẹ.” Ásáhélì kò sì fẹ́ yí padà kúrò ní títẹ̀lé e. 22  Nítorí náà, Ábínérì tún sọ fún Ásáhélì lẹ́ẹ̀kan sí i pé: “Yí ipa ọ̀nà rẹ padà kúrò ní títẹ̀lé mi. Èé ṣe tí èmi yóò fi ṣá ọ balẹ̀?+ Báwo wá ni èmi yóò ṣe gbé ojú mi sókè sí Jóábù arákùnrin rẹ?” 23  Ṣùgbọ́n ó ń bá a nìṣó ní kíkọ̀ láti yí padà; Ábínérì sì fi ìdí èèkù ọ̀kọ̀ gún un ní inú,+ tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀kọ̀ náà fi jáde ní ẹ̀yìn rẹ̀; ó sì ṣubú sí ibẹ̀, ó sì kú sí ibi tí ó wà. Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbogbo àwọn tí ó dé ibi tí Ásáhélì ṣubú sí tí ó sì kú, a dúró jẹ́ẹ́.+ 24  Jóábù àti Ábíṣáì sì ń lépa Ábínérì. Bí oòrùn ti ń wọ̀, wọ́n dé òkè kékeré Ámà, èyí tí ó wà ní iwájú Gíà lójú ọ̀nà sí aginjù Gíbéónì.+ 25  Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì sì bẹ̀rẹ̀ sí kóra jọpọ̀ sẹ́yìn Ábínérì, wọ́n sì wá jẹ́ àwùjọ ẹgbẹ́ kan, wọ́n sì dúró sórí òkè kékeré kan. 26  Ábínérì sì bẹ̀rẹ̀ sí pe Jóábù pé: “Idà yóò ha máa jẹun+ láìlópin bí? Ìwọ kò ha mọ̀ ní tòótọ́ pé ìkorò ni yóò jẹyọ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín?+ Nígbà náà, yóò ti pẹ́ tó kí o tó sọ fún àwọn ènìyàn náà pé kí wọ́n yí padà kúrò ní títẹ̀lé àwọn arákùnrin wọn?”+ 27  Látàrí ìyẹn, Jóábù sọ pé: “Bí Ọlọ́run tòótọ́ ti ń bẹ,+ ká ní ìwọ kò sọ̀rọ̀ ni,+ nígbà náà, ì bá di òwúrọ̀ kí a tó mú kí àwọn ènìyàn náà fà sẹ́yìn, olúkúlùkù kúrò ní títẹ̀lé arákùnrin rẹ̀.” 28  Wàyí o, Jóábù fun ìwo,+ gbogbo àwọn ènìyàn náà sì dúró, wọn kò sì bá a lọ ní lílépa Ísírẹ́lì mọ́, wọn kò sì tún ìjà náà jà mọ́. 29  Ní ti Ábínérì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀, wọ́n la Árábà+ kọjá ní gbogbo òru yẹn, wọ́n sì sọdá Jọ́dánì,+ wọ́n sì la gbogbo kòtò ọ̀gbàrá kọjá, níkẹyìn, wọ́n wá sí Máhánáímù.+ 30  Ní ti Jóábù, ó yí padà kúrò ní títẹ̀lé Ábínérì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kó gbogbo àwọn ènìyàn náà jọpọ̀. Ọkùnrin mọ́kàndínlógún àti Ásáhélì ni ó sì di àwátì lára àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì. 31  Àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì, ní tiwọn, sì ti ṣá àwọn tí ó jẹ́ ti Bẹ́ńjámínì balẹ̀ àti lára àwọn ọkùnrin Ábínérì—òjì -dín-nírínwó ọkùnrin ni ó kú.+ 32  Wọ́n sì gbé Ásáhélì,+ wọ́n sì sin ín sí ibi ìsìnkú baba rẹ̀,+ èyí tí ó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.+ Nígbà náà ni Jóábù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí rìn lọ láti òru mọ́jú, ojúmọmọ ni ó sì jẹ́ nígbà tí wọ́n dé Hébúrónì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé