Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Sámúẹ́lì 18:1-33

18  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí ka iye àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì fi àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún+ ṣe olórí wọn.  Síwájú sí i, Dáfídì rán ìdá mẹ́ta+ àwọn ènìyàn náà ní ìkáwọ́ Jóábù+ àti ìdá mẹ́ta ní ìkáwọ́ Ábíṣáì+ ọmọkùnrin Seruáyà, arákùnrin Jóábù,+ àti ìdá mẹ́ta ní ìkáwọ́ Ítítáì+ ará Gátì. Nígbà náà ni ọba sọ fún àwọn ènìyàn náà pé: “Èmi fúnra mi yóò bá yín jáde lọ pẹ̀lú láìsí àní-àní.”  Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà sọ pé: “Ìwọ kì yóò jáde lọ,+ nítorí bí a bá tilẹ̀ sá, wọn kì yóò fi ọkàn-àyà wọn sí wa lára;+ bí ìdajì wa bá sì kú, wọn kì yóò fi ọkàn-àyà wọn sí wa lára, nítorí tí ìwọ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá wa;+ wàyí o, yóò sàn bí ìwọ yóò bá wúlò fún wa láti máa fún wa ní ìrànlọ́wọ́+ láti inú ìlú ńlá wá.”  Nítorí náà, ọba sọ fún wọn pé: “Ohun yòówù tí ó bá dára ní ojú yín ni èmi yóò ṣe.”+ Ọba sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè,+ gbogbo àwọn ènìyàn náà sì jáde lọ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún àti ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún.+  Ọba sì ń bá a lọ láti pàṣẹ fún Jóábù àti Ábíṣáì àti Ítítáì, pé: “Ẹ ṣe ọ̀dọ́kùnrin náà Ábúsálómù pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́+ nítorí mi.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì gbọ́ nígbà tí ọba pàṣẹ fún gbogbo àwọn olórí nítorí ọ̀ràn Ábúsálómù.  Àwọn ènìyàn náà sì bá ọ̀nà wọn jáde lọ sí pápá láti pàdé Ísírẹ́lì; ìjà ogun náà sì wá jẹ́ ní igbó Éfúráímù.+  Níkẹyìn, a ṣẹ́gun+ àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì+ níbẹ̀ níwájú àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì, ìfikúpa tí ó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ sì já sí èyí tí ó pọ̀ ní ọjọ́ yẹn, ọ̀kẹ́ kan ènìyàn.  Ìjà ogun tí ó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ sì wá tàn kálẹ̀ dé gbogbo ilẹ̀ tí ojú lè rí. Síwájú sí i, igbó ṣe èyí tí ó pọ̀ ní jíjẹ àwọn ènìyàn náà run ju èyí tí idà ṣe ní jíjẹ wọ́n run ní ọjọ́ yẹn.  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Ábúsálómù bá ara rẹ̀ níwájú àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì. Ìbaaka sì ni Ábúsálómù gùn, ìbaaka náà sì wá sábẹ́ àwọn ẹ̀tun tí ó so kọ́ra lára igi ńlá ràbàtà kan, tí ó fi jẹ́ pé orí rẹ̀ há sórí igi ńlá náà pinpin, ó sì rọ̀ dirodiro láàárín ọ̀run àti ilẹ̀ ayé,+ níwọ̀n bí ìbaaka náà tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ ti kọjá lọ. 10  Nígbà náà ni ọkùnrin kan rí i, ó sì sọ fún Jóábù,+ ó sì wí pé: “Wò ó! Mo rí i tí Ábúsálómù so rọ̀ sórí igi ńlá kan.” 11  Látàrí èyí, Jóábù sọ fún ọkùnrin tí ń sọ fún un pé: “Kíyè sí i, ìwọ rí i, èé sì ti ṣe tí ìwọ kò fi ṣá a balẹ̀ níbẹ̀? Nígbà náà, ì bá ti jẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe tèmi láti fún ọ ní ẹyọ fàdákà mẹ́wàá àti ìgbànú kan.”+ 12  Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà sọ fún Jóábù pé: “Ká ní èmi tilẹ̀ ń wọn ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà ní àtẹ́lẹwọ́ mi, èmi kò ní na ọwọ́ mi jáde lòdì sí ọmọ ọba; nítorí etí-ìgbọ́ wa ni ọba ti pàṣẹ fún ìwọ àti Ábíṣáì àti Ítítáì, pé, ‘Ẹ ṣọ́ ara yín, ẹnì yòówù tí ì báà jẹ́, lórí ọ̀dọ́kùnrin náà, lórí Ábúsálómù.’+ 13  Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ èmi ì bá ti ṣe àdàkadekè sí ọkàn rẹ̀, gbogbo ọ̀ràn náà pàápàá kì bá sì pa mọ́ fún ọba,+ ìwọ fúnra rẹ ì bá sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.” 14  Látàrí èyí, Jóábù fèsì pé: “Má ṣe jẹ́ kí n dá ara mi dúró lọ́nà yìí níwájú rẹ!” Pẹ̀lú ìyẹn, ó kó ọ̀kọ̀ tẹ́ẹ́rẹ́ mẹ́ta sí àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, ó sì tẹ̀ síwájú láti fi wọ́n gún+ ọkàn-àyà Ábúsálómù ní àgúnyọ nígbà tí ó ṣì wà láàyè ní àárín+ igi ńlá náà. 15  Nígbà náà ni àwọn ẹmẹ̀wà mẹ́wàá tí ń ru àwọn ohun ìjà Jóábù sún mọ́ tòsí, wọ́n sì kọlu Ábúsálómù, kí wọ́n lè fi ikú pa á.+ 16  Jóábù fun ìwo+ wàyí, kí àwọn ènìyàn náà lè padà ní lílépa Ísírẹ́lì; nítorí Jóábù ti dá àwọn ènìyàn náà dúró. 17  Níkẹyìn, wọ́n gbé Ábúsálómù sọ sínú igbó, sínú kòtò ńlá kan, wọ́n sì kó òkúta jọ pèlèmọ̀-pelemọ lé e lórí.+ Ní ti gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n sá lọ, olúkúlùkù ọkùnrin, sí ilé rẹ̀. 18  Wàyí o, Ábúsálómù fúnra rẹ̀, nígbà tí ó wà láàyè, ti gbé ọwọ̀n kan, ó sì tẹ̀ síwájú láti gbé e nà ró fún ara rẹ̀,+ èyí tí ó wà ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Rírẹlẹ̀ Ọba,+ nítorí ó sọ pé: “Èmi kò ní ọmọkùnrin láti lè pa orúkọ mi mọ́ ní ìrántí.”+ Nítorí náà, ó fi orúkọ ara rẹ̀ pe ọwọ̀n náà,+ a sì ń bá a lọ láti pè é ní Ohun Ìránnilétí Ábúsálómù títí di òní yìí. 19  Wàyí o, ní ti Áhímáásì+ ọmọkùnrin Sádókù, ó sọ pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n sáré lọ ro ìhìn náà fún ọba, nítorí pé Jèhófà ti ṣe ìdájọ́ fún un láti gbà á lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.”+ 20  Ṣùgbọ́n Jóábù sọ fún un pé: “Ìwọ kì í ṣe amúhìnwá lónìí yìí, ìwọ yóò sì ro ìhìn ní ọjọ́ mìíràn; ṣùgbọ́n lónìí yìí ìwọ kì yóò ro ìhìn, nítorí ìdí náà pé ọmọkùnrin ọba ti kú.”+ 21  Nígbà náà ni Jóábù sọ fún ọmọ Kúṣì pé:+ “Lọ, sọ ohun tí ìwọ rí fún ọba.” Látàrí ìyẹn, ọmọ Kúṣì tẹrí ba fún Jóábù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sáré. 22  Áhímáásì ọmọkùnrin Sádókù tún sọ fún Jóábù wàyí pé: “Nísinsìnyí, jẹ́ kí ohun yòówù tí ó bá fẹ́ ṣẹlẹ̀ kí ó ṣẹlẹ̀, jọ̀wọ́, jẹ́ kí èmi alára pẹ̀lú sáré tọ ọmọ Kúṣì lẹ́yìn.” Bí ó ti wù kí ó rí, Jóábù sọ pé: “Èé ṣe tí ìwọ alára fi ní láti sáré, ọmọkùnrin mi, nígbà tí a kò rí ìhìn kankan fún ọ?” 23  Síbẹ̀, ó sọ pé: “Nísinsìnyí, jẹ́ kí ohun yòówù tí ó bá fẹ́ ṣẹlẹ̀ kí ó ṣẹlẹ̀, jẹ́ kí n sáré.” Nítorí náà, ó sọ fún un pé: “Sáré!” Áhímáásì sì bẹ̀rẹ̀ sí sáré gba ti Àgbègbè,+ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó kọjá ọmọ Kúṣì. 24  Wàyí o, Dáfídì jókòó láàárín ẹnubodè méjèèjì .+ Láàárín àkókò náà, olùṣọ́+ lọ sí òrùlé ẹnubodè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri. Níkẹyìn, ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì rí i, sì wò ó! ọkùnrin kan ń bẹ tí ń sáré ní òun nìkan. 25  Nítorí náà, olùṣọ́ pè, ó sì sọ fún ọba, ọba sì fèsì pé: “Bí ó bá jẹ́ òun nìkan, ìhìn wà ní ẹnu rẹ̀.” Ó sì ń bọ̀, ó ń sún mọ́ tòsí láìsọsẹ̀. 26  Wàyí o, olùṣọ́ rí ọkùnrin mìíràn tí ń sáré. Nítorí náà, olùṣọ́ pe aṣọ́bodè, ó sì sọ pé: “Wò ó! Ọkùnrin mìíràn ń sáré ní òun nìkan!” ọba sì fèsì pé: “Amúhìnwá ni ẹni yìí pẹ̀lú.” 27  Olùṣọ́ sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Mo ń rí i pé ọ̀nà ìgbàsáré ẹni àkọ́kọ́ dà bí ọ̀nà ìgbàsáré+ Áhímáásì+ ọmọkùnrin Sádókù,” ọba sì fèsì pé: “Ènìyàn rere nìyí,+ ìhìn rere+ sì ni ó yẹ kí ó mú wá.” 28  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Áhímáásì pè, ó sì wí fún ọba pé: “Dáadáa ni!” Pẹ̀lú ìyẹn, ó tẹrí ba fún ọba pẹ̀lú ìdojúbolẹ̀. Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Ìbùkún+ ni fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ti fi àwọn ọkùnrin tí ó gbé ọwọ́ wọn sókè sí olúwa mi ọba lé e lọ́wọ́!”+ 29  Bí ó ti wù kí ó ri, ọba sọ pé: “Ṣé àlàáfíà ni ọ̀dọ́kùnrin náà Ábúsálómù wà?” Áhímáásì fèsì pé: “Mo rí arukutu ńláǹlà nígbà tí Jóábù rán ìránṣẹ́ ọba àti ìránṣẹ́ rẹ, èmi kò sì mọ ohun tí ó jẹ́.”+ 30  Nítorí náà, ọba sọ pé: “Bọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́, mú ìdúró rẹ níhìn-ín.” Látàrí ìyẹn, ó bọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́, ó sì dúró jẹ́ẹ́. 31  Ọmọ Kúṣì+ sì rèé tí ń wọlé bọ̀, ọmọ Kúṣì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Kí olúwa mi ọba tẹ́wọ́ gba ìhìn, nítorí Jèhófà ti ṣe ìdájọ́ fún ọ lónìí, láti gbà ọ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí ń dìde sí ọ.”+ 32  Ṣùgbọ́n ọba sọ fún ọmọ Kúṣì pé: “Ṣé dáadáa ni ọ̀dọ́kùnrin náà Ábúsálómù wà?” Ọmọ Kúṣì fèsì pé: “Kí àwọn ọ̀tá olúwa mi ọba àti gbogbo àwọn tí ó dìde sí ọ fún ibi dà bí ọ̀dọ́kùnrin náà.”+ 33  Nígbà náà ni ìyọlẹ́nu bá ọba, ó sì gòkè lọ sí ìyẹ̀wù òrùlé+ lórí ojú ọ̀nà ibodè, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún; ohun tí ó sì sọ nìyí bí ó ti ń rìn lọ: “Ọmọkùnrin mi Ábúsálómù, ọmọkùnrin mi, ọmọkùnrin mi+ Ábúsálómù! Áà ì bá ṣe pé mo ti kú, èmi fúnra mi, dípò ìwọ, Ábúsálómù ọmọkùnrin mi, ọmọkùnrin mi!”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé