Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Sámúẹ́lì 17:1-29

17  Áhítófẹ́lì sì tẹ̀ síwájú láti sọ fún Ábúsálómù pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n yan ẹgbẹ̀rún méjì lá ọkùnrin, kí n sì dìde, kí n sì lépa Dáfídì ní òru òní.+  Èmi yóò sì dé bá a nígbà tí àárẹ̀ ti mú un, tí ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sì ti rọ,+ èmi yóò sì kó o sínú ìwárìrì dájúdájú; gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ yóò sì ní láti sá lọ, èmi yóò sì ṣá ọba nìkan balẹ̀+ dájúdájú.  Sì jẹ́ kí n kó gbogbo àwọn ènìyàn náà padà wá sọ́dọ̀ rẹ. Dọ́gba-dọ́gba ni pípadà gbogbo wọ́n já sí pẹ̀lú ọkùnrin tí ìwọ ń wá; gbogbo àwọn ènìyàn náà yóò sì wà ní àlàáfíà.”  Wẹ́kú sì ni ọ̀rọ̀ náà ṣe lójú Ábúsálómù+ àti lójú gbogbo àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì.  Bí ó ti wù kí ó rí, Ábúsálómù sọ pé: “Jọ̀wọ́, pe Húṣáì+ tí í ṣe Áríkì pẹ̀lú, kí a sì gbọ́ ohun tí ń bẹ ní ẹnu rẹ̀, àní tirẹ̀ pàápàá.”  Nítorí náà, Húṣáì wọlé tọ Ábúsálómù wá. Nígbà náà ni Ábúsálómù sọ fún un pé: “Báyìí-báyìí ni Áhítófẹ́lì sọ. Ṣé kí a gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ìwọ alára sọ̀rọ̀.”  Látàrí èyí, Húṣáì sọ fún Ábúsálómù pé: “Ìmọ̀ràn tí Áhítófẹ́lì gbà kò dára lọ́tẹ̀ yìí!”+  Húṣáì sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Ìwọ alára mọ baba rẹ dáadáa àti àwọn ọkùnrin rẹ̀, pé wọ́n jẹ́ alágbára ńlá,+ wọ́n sì korò ní ọkàn,+ gẹ́gẹ́ bí abo béárì tí ó ti pàdánù àwọn ọmọ rẹ̀ ní pápá;+ jagunjagun+ sì ni baba rẹ, òun kì yóò sì sùn mọ́jú lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn náà.  Wò ó! Nísinsìnyí, ó fara pa mọ́+ sí ọ̀kan nínú àwọn ibi jíjin kòtò tàbí sí ọ̀kan nínú àwọn ibi mìíràn; yóò sì ṣẹlẹ̀ dájúdájú pé, gbàrà tí ó bá rọ́ lù wọ́n ní ìbẹ̀rẹ̀, ẹni tí ó bá gbọ́ nípa rẹ̀, dájúdájú, yóò wá gbọ́, yóò sì sọ pé, ‘A ti ṣẹ́gun àwọn ènìyàn tí ń tọ Ábúsálómù lẹ́yìn!’ 10  Àti ọkùnrin akíkanjú pàápàá tí ọkàn-àyà rẹ̀ dà bí ọkàn-àyà kìnnìún+ ni ó dájú pé òun fúnra rẹ̀ yóò rọ̀ nínú àìlera;+ nítorí gbogbo Ísírẹ́lì mọ̀ pé alágbára ńlá+ ni baba rẹ, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ọkùnrin akíkanjú tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 11  Èmi fúnra mi dámọ̀ràn pé: Jẹ́ kí a kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ sọ́dọ̀ rẹ láìsí àní-àní, láti Dánì títí dé Bíá-ṣébà,+ gẹ́gẹ́ bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà lẹ́bàá òkun nítorí jíjẹ́ ògìdìgbó,+ kí ìwọ tìkára rẹ sì lọ sínú ìjà náà.+ 12  Àwa yóò sì wá gbéjà kò ó ní ọ̀kan nínú àwọn ibi tí ó dájú pé a ó ti rí i,+ àwa fúnra wa yóò sì dé bá a gan-an gẹ́gẹ́ bí ìrì+ ti ń sẹ̀ sórí ilẹ̀; dájúdájú, àní ẹnì kan ṣoṣo kì yóò ṣẹ́ kù lára òun àti gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀. 13  Bí ó bá sì jẹ́ ìlú ńlá kan ni ó fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ, gbogbo Ísírẹ́lì yóò sì kó ìjàrá lọ sí ìlú ńlá yẹn, a ó sì wọ́ ọ lọ sí àfonífojì olójú ọ̀gbàrá dájúdájú, títí a kì yóò fi rí àní òkúta róbótó kan níbẹ̀.”+ 14  Nígbà náà ni Ábúsálómù àti gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì sọ pé: “Ìmọ̀ràn Húṣáì tí í ṣe Áríkì sàn ju+ ìmọ̀ràn Áhítófẹ́lì!” Jèhófà fúnra rẹ̀ sì ti pàṣẹ+ pé kí ìmọ̀ràn+ Áhítófẹ́lì já sí pàbó, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dára,+ kí Jèhófà bàa lè mú ìyọnu àjálù+ wá sórí Ábúsálómù. 15  Lẹ́yìn náà, Húṣáì sọ fún Sádókù+ àti Ábíátárì àlùfáà pé: “Báyìí-báyìí ni bí Áhítófẹ́lì ṣe gba Ábúsálómù àti àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì nímọ̀ràn; báyìí-báyìí sì ni bí èmi alára ṣe gbà wọ́n nímọ̀ràn. 16  Sì ránṣẹ́ pẹ̀lú ìyára kánkán nísinsìnyí, kí o sì sọ fún Dáfídì,+ pé, ‘Má wọ̀ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ ti aginjù ní òru òní, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ìwọ pẹ̀lú sọdá láìkùnà,+ kí a má bàa gbé ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ mì.’”+ 17  Níwọ̀n bí Jónátánì+ àti Áhímáásì+ ti ń dúró ní Ẹ́ń-rógélì,+ ìránṣẹ́bìnrin kan lọ, ó sì sọ fún wọn. Nítorí náà, àwọn fúnra wọn lọ, níwọ̀n bí wọ́n ti ní láti sọ fún Dáfídì Ọba; nítorí wọn kò lè yọjú sí ìlú ńlá náà. 18  Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀dọ́kùnrin kan rí wọn, ó sì sọ fún Ábúsálómù. Nítorí náà, àwọn méjèèjì fi ìyára kánkán lọ, wọ́n sì dé ilé ọkùnrin kan ní Báhúrímù,+ ẹni tí ó ní kànga ní àgbàlá rẹ̀; wọ́n sì sọ̀ kalẹ̀ sínú rẹ̀. 19  Lẹ́yìn ìyẹn, obìnrin rẹ̀ mú àtabojú kan, ó sì nà án bo ojú kànga náà, ó sì kó ọkà tí a ti pa jọ sórí rẹ̀ gègèrè;+ ohun kan kò sì di mímọ̀ nípa rẹ̀. 20  Àwọn ìránṣẹ́ Ábúsálómù wá sí ọ̀dọ̀ obìnrin náà wàyí ní ilé rẹ̀, wọ́n sì sọ pé: “Ibo ni Áhímáásì àti Jónátánì wà?” Látàrí èyí, obìnrin náà sọ fún wọn pé: “Wọ́n kọjá lọ láti ìhín sí ibi omi.”+ Nígbà náà ni wọ́n ń bá a nìṣó ní wíwá wọn kiri, wọn kò sì rí wọn,+ nítorí náà, wọ́n padà sí Jerúsálẹ́mù. 21  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn lílọ kúrò wọn pé, wọ́n gòkè kúrò nínú kànga, wọ́n sì lọ, wọ́n sì sọ fún Dáfídì Ọba, wọ́n sì wí fún Dáfídì pé: “Ẹ dìde, kí ẹ sì fi ìyára kánkán ré omi kọjá; nítorí báyìí ni bí Áhítófẹ́lì ṣe gbani nímọ̀ràn+ sí yín.” 22  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Dáfídì dìde àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ bákan náà, wọ́n sì ń bá a nìṣó ní sísọdá Jọ́dánì títí ilẹ̀ òwúrọ̀ fi mọ́,+ títí kò fi sí ẹyọ ẹnì kan tí ó kù tí kò tíì ré Jọ́dánì kọjá. 23  Ní ti Áhítófẹ́lì, ó rí i pé a kò gbé ìgbésẹ̀ lórí ìmọ̀ràn òun,+ ó sì tẹ̀ síwájú láti di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì, ó sì dìde, ó sì lọ sí ilé rẹ̀ ní ìlú ńlá rẹ̀.+ Nígbà náà ni ó pa àṣẹ fún agbo ilé rẹ̀,+ ó sì fún ara rẹ̀ lọ́rùn,+ ó sì tipa bẹ́ẹ̀ kú.+ Bẹ́ẹ̀ ni a sin ín+ sí ibi ìsìnkú àwọn baba ńlá rẹ̀. 24  Ní ti Dáfídì, ó wá sí Máhánáímù,+ Ábúsálómù alára sì sọdá Jọ́dánì, òun àti gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀. 25  Ámásà+ sì ni ẹni tí Ábúsálómù fi sí ipò Jóábù+ lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun; Ámásà sì jẹ́ ọmọkùnrin ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ítírà+ tí í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, ẹni tí ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú Ábígẹ́lì+ ọmọbìnrin Náháṣì, arábìnrin Seruáyà, ìyá Jóábù. 26  Ísírẹ́lì àti Ábúsálómù sì bẹ̀rẹ̀ sí dó sí ilẹ̀ Gílíádì.+ 27  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Dáfídì wá sí Máhánáímù, Ṣóbì ọmọkùnrin Náháṣì láti Rábà+ ti àwọn ọmọkùnrin Ámónì,+ àti Mákírù+ ọmọkùnrin Ámíélì+ láti Lo-débárì, àti Básíláì+ ọmọ Gílíádì láti Rógélímù+ 28  kó àwọn ibùsùn wá àti bàsíà àti ohun èlò amọ̀kòkò, àti àlìkámà àti ọkà bálì àti ìyẹ̀fun+ àti àyangbẹ ọkà+ àti ẹ̀wà pàkálà+ àti ẹ̀wà lẹ́ńtìlì+ àti ẹ̀gbẹ ọkà; 29  àti oyin+ àti bọ́tà+ àti àgùntàn àti ìkẹ̀tẹ́ wàrà màlúù ni wọ́n kó wá fún Dáfídì àti fún àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ láti jẹ,+ nítorí wọ́n sọ pé: “Ebi ń pa àwọn ènìyàn náà, ó sì rẹ̀ wọ́n, òùngbẹ sì ń gbẹ wọ́n ní aginjù.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé