Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Sámúẹ́lì 16:1-23

16  Nígbà tí Dáfídì alára ti sọdá téńté orí òkè+ náà díẹ̀, Síbà+ ẹmẹ̀wà Mefibóṣẹ́tì+ wà níbẹ̀ láti pàdé rẹ̀ pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ méjì tí a dì ní gàárì, igba ìṣù búrẹ́dì+ àti ọgọ́rùn-ún ìṣù èso àjàrà gbígbẹ+ àti ọgọ́rùn-ún ẹrù èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn+ àti ìṣà wáìnì títóbi+ sì wà lórí wọn.  Nígbà náà ni ọba sọ fún Síbà pé: “Kí ni nǹkan wọ̀nyí túmọ̀ sí níhà ọ̀dọ̀ rẹ?”+ Síbà fèsì pé: “Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà wà fún agbo ilé ọba láti gùn, búrẹ́dì àti ẹrù èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn sì wà fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin+ láti jẹ, wáìnì sì wà fún ẹni tí àárẹ̀ ti mú+ ní aginjù+ láti mu.”  Ọba sọ wàyí pé: “Ibo sì ni ọmọkùnrin ọ̀gá rẹ wà?”+ Látàrí èyí, Síbà sọ fún ọba pé: “Ó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù; nítorí ó sọ pé, ‘Lónìí, ilé Ísírẹ́lì yóò fún mi ní ìṣàkóso ọba ti baba mi padà.’”+  Ọba wá sọ fún Síbà pé: “Wò ó! Ohun gbogbo tí í ṣe ti Mefibóṣẹ́tì jẹ́ tìrẹ.”+ Látàrí ìyẹn, Síbà sọ pé: “Mo tẹrí ba.+ Jẹ́ kí n rí ojú rere ní ojú rẹ, olúwa mi ọba.”  Dáfídì ọba sì ń bọ̀ títí dé Báhúrímù,+ sì wò ó! ọkùnrin kan láti ìdílé Sọ́ọ̀lù ń jáde bọ̀ láti ibẹ̀, orúkọ rẹ̀ sì ni Ṣíméì,+ ọmọkùnrin Gérà, ó ń jáde bọ̀, ó sì ń pe ibi sọ̀ kalẹ̀ bí ó ti ń jáde bọ̀.+  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ òkúta sí Dáfídì àti sí gbogbo ìránṣẹ́ Dáfídì ọba; gbogbo àwọn ènìyàn náà àti gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára ńlá sì wà ní ọ̀tún rẹ̀ àti ní òsì rẹ̀.  Ohun tí Ṣíméì sì wí nìyí bí ó ti ń pe ibi sọ̀ kalẹ̀: “Jáde, jáde, ìwọ ajẹ̀bi ẹ̀jẹ̀+ àti aláìdára fún ohunkóhun yìí!+  Jèhófà ti mú gbogbo ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ fún ilé Sọ́ọ̀lù ní ipò ẹni tí ìwọ ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba padà wá sórí rẹ; Jèhófà sì fi ipò ọba náà lé ọwọ́ Ábúsálómù ọmọkùnrin rẹ. Ìwọ sì rèé nínú ìyọnu àjálù rẹ, nítorí pé ajẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ni ọ́!”+  Níkẹyìn, Ábíṣáì ọmọkùnrin Seruáyà+ sọ fún ọba pé: “Èé ṣe tí òkú ajá+ yìí yóò fi máa pe ibi wá sórí olúwa mi ọba?+ Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n sọdá lọ, kí n sì mú orí rẹ̀ kúrò.”+ 10  Ṣùgbọ́n ọba sọ pé: “Kí ní pa tèmi tiyín pọ̀,+ ẹ̀yin ọmọ Seruáyà?+ Ẹ jẹ́ kí ó máa pe ibi sọ̀ kalẹ̀,+ nítorí pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ti sọ fún un pé,+ ‘Pe ibi wá sórí Dáfídì!’ Nítorí náà, ta ni yóò sọ pé, ‘Èé ṣe tí ìwọ fi ṣe bẹ́ẹ̀?’”+ 11  Dáfídì sì ń bá a lọ láti sọ fún Ábíṣáì àti gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Kíyè sí i, ọmọkùnrin mi, ẹni tí ó jáde wá láti ìhà inú mi, ń wá ọkàn mi;+ mélòómélòó nísinsìnyí ni ọmọ Bẹ́ńjámínì kan!+ Ẹ jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́, kí ó lè pe ibi sọ̀ kalẹ̀, nítorí pé Jèhófà ti sọ bẹ́ẹ̀ fún un! 12  Bóyá Jèhófà yóò fi ojú rẹ̀ rí i,+ ní ti tòótọ́, Jèhófà yóò sì mú ire padà bọ̀ sípò fún mi dípò ìfiré rẹ̀ lónìí yìí.”+ 13  Pẹ̀lú ìyẹn, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ ń lọ ní ojú ọ̀nà, bí Ṣíméì ti ń rìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè ńlá náà, ó ń rìn ní ọ̀gangan ìhà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, kí ó lè máa pe ibi sọ̀ kalẹ̀;+ ó sì ń bá a nìṣó ní sísọ òkúta bí ó ti wà ní ọ̀gangan ìhà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ó sì fọ́n ọ̀pọ̀ ekuru.+ 14  Níkẹyìn, ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ dé tàárẹ̀-tàárẹ̀. Nítorí náà, wọn tu ara wọn lára níbẹ̀.+ 15  Ní ti Ábúsálómù àti gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì, wọ́n wọ Jerúsálẹ́mù;+ Áhítófẹ́lì+ sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 16  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Húṣáì+ tí í ṣe Áríkì,+ alábàákẹ́gbẹ́ Dáfídì,+ wọlé tọ Ábúsálómù wá, Húṣáì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Ábúsálómù pé: “Kí ọba kí ó pẹ́!+ Kí ọba kí ó pẹ́!” 17  Látàrí èyí, Ábúsálómù sọ fún Húṣáì pé: “Inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ sí alábàákẹ́gbẹ́ rẹ nìyí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Èé ṣe tí ìwọ kò fi bá alábàákẹ́gbẹ́ rẹ lọ?”+ 18  Nítorí náà, Húṣáì sọ fún Ábúsálómù pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́; ṣùgbọ́n ẹni tí Jèhófà àti àwọn ènìyàn yìí pẹ̀lú àti gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì bá yàn, tirẹ̀ ni èmi yóò jẹ́, òun ni èmi yóò sì máa bá gbé. 19  Èmi yóò sì sọ ní ìgbà kejì pé, Ta ni èmi alára yóò sìn? Kì í ha ṣe níwájú ọmọkùnrin rẹ̀? Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ṣe sìn níwájú baba rẹ, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe níwájú rẹ.”+ 20  Lẹ́yìn náà, Ábúsálómù sọ fún Áhítófẹ́lì pé: “Ẹ mú ìmọ̀ràn wá níhà ọ̀dọ̀ yín.+ Kí ni àwa yóò ṣe?” 21  Nígbà náà ni Áhítófẹ́lì sọ fún Ábúsálómù pé: “Ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn wáhàrì baba rẹ,+ àwọn tí ó fi sílẹ̀ sẹ́yìn láti máa tọ́jú ilé.+ Dájúdájú, gbogbo Ísírẹ́lì yóò sì gbọ́ pé o ti sọ ara rẹ di òórùn burúkú+ sí baba rẹ,+ ọwọ́+ gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ yóò sì lágbára dájúdájú.” 22  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n pa àgọ́ kan fún Ábúsálómù lórí òrùlé,+ Ábúsálómù sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn wáhàrì baba rẹ̀+ ní ìṣojú gbogbo Ísírẹ́lì.+ 23  Ìmọ̀ràn Áhítófẹ́lì, èyí tí ó máa ń gbani ní ọjọ́ wọnnì, sì rí gan-an gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn bá wádìí nípa ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́. Bí gbogbo ìmọ̀ràn+ Áhítófẹ́lì+ ti rí nìyẹn fún Dáfídì àti fún Ábúsálómù.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé