Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Sámúẹ́lì 15:1-37

15  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ pé, Ábúsálómù tẹ̀ síwájú láti mú kí a ṣe kẹ̀kẹ́ ẹṣin kan fún ara rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ẹṣin àti pẹ̀lú àádọ́ta ọkùnrin tí ń sáré níwájú rẹ̀.+  Ábúsálómù sì dìde ní kùtùkùtù,+ ó sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ojú ọ̀nà tí ó lọ sí ẹnubodè.+ Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí ọkùnrin èyíkéyìí bá ní ẹjọ́ láti mú tọ ọba wá fún ìdájọ́,+ nígbà náà, Ábúsálómù a pè é, a sì sọ pé: “Ìlú ńlá wo ni ìwọ ti wá?” òun a sì sọ pé: “Ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni ìránṣẹ́ rẹ ti wá.”  Ábúsálómù a sì sọ fún un pé: “Wò ó, ọ̀ràn rẹ dára, ó sì tọ́; ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kankan láti ọ̀dọ̀ ọba tí yóò fetí sí ọ.”+  Ábúsálómù a sì máa bá a lọ láti sọ pé: “Ì bá ṣe pé a yàn mí ṣe onídàájọ́ ní ilẹ̀ yìí,+ pé kí olúkúlùkù ènìyàn tí ó bá ní ẹjọ́ tàbí ìdájọ́ lè tọ̀ mí wá! Nígbà náà, èmi ì bá ṣe ìdájọ́ òdodo fún un dájúdájú.”+  Ó tún ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí ẹnì kan bá sún mọ́ tòsí láti tẹrí ba fún un, òun a na ọwọ́ rẹ̀, a sì rá a mú,+ a sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu.  Ábúsálómù sì ń ṣe irú nǹkan báyìí sí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó bá wọlé tọ ọba wá fún ìdájọ́; Ábúsálómù sì ń jí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì lọ.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní òpin ogójì ọdún pé Ábúsálómù tẹ̀ síwájú láti sọ fún ọba pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n lọ sí Hébúrónì+ lọ san ẹ̀jẹ́ mi tí mo jẹ́ lọ́nà tí ó wúwo rinlẹ̀ fún Jèhófà.+  Nítorí ìránṣẹ́ rẹ jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan tí ó wúwo rinlẹ̀+ nígbà tí mo ń gbé ní Géṣúrì+ ní Síríà pé, ‘Bí Jèhófà yóò bá mú mi padà wá sí Jerúsálẹ́mù láìkùnà, èmi pẹ̀lú yóò ṣe iṣẹ́ ìsìn sí Jèhófà.’”+  Nítorí náà, ọba wí fún un pé: “Máa lọ ní àlàáfíà.”+ Pẹ̀lú ìyẹn, ó dìde, ó sì lọ sí Hébúrónì. 10  Ábúsálómù rán àwọn amí+ sí gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì wàyí pé: “Gbàrà tí ẹ bá gbọ́ ìró ìwo, kí ẹ̀yin pẹ̀lú wí pé, ‘Ábúsálómù ti di ọba+ ní Hébúrónì!’”+ 11  Wàyí o, igba ọkùnrin ti bá Ábúsálómù lọ láti Jerúsálẹ́mù, àwọn tí a pè, tí wọ́n sì ń lọ láìfura,+ wọn kò sì mọ ẹyọ ohun kan. 12  Síwájú sí i, nígbà tí ó rú àwọn ẹbọ náà, Ábúsálómù ránṣẹ́ pe Áhítófẹ́lì+ ará Gílò,+ agbani-nímọ̀ràn Dáfídì,+ láti Gílò ìlú ńlá rẹ̀.+ Tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun+ náà sì túbọ̀ ń le sí i, àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú Ábúsálómù sì ń pọ̀ sí i níye.+ 13  Nígbà tí ó ṣe, amúròyìnwá kan tọ Dáfídì wá, ó wí pé: “Ọkàn-àyà+ àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì ti wà lẹ́yìn Ábúsálómù.” 14  Ní kíá, Dáfídì sọ fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù pé: “Ẹ dìde, ẹ sì jẹ́ kí a fẹsẹ̀ fẹ;+ nítorí kì yóò sí ọ̀nà àsálà fún wa nítorí Ábúsálómù! Ẹ lọ wéré, kí ó má bàa ṣe wéré, kí ó sì bá wa ní ti tòótọ́, kí ó sì mú ohun tí ó burú wá sórí wa, kí ó sì fi ojú idà kọlu ìlú ńlá yìí!”+ 15  Látàrí èyí, àwọn ìránṣẹ́ ọba sọ fún ọba pé: “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí olúwa mi ọba bá yàn, àwa ìránṣẹ́ rẹ rèé.”+ 16  Nítorí náà, ọba jáde lọ pẹ̀lú gbogbo agbo ilé rẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀,+ ọba sì fi obìnrin mẹ́wàá sílẹ̀, àwọn wáhàrì,+ láti máa tọ́jú ilé. 17  Ọba sì ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn náà ní ẹsẹ̀ rẹ̀; wọ́n sì wá dúró ní Bẹti-méhákì. 18  Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì ń sọdá ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀; àti gbogbo àwọn Kérétì àti gbogbo àwọn Pẹ́lẹ́tì+ àti gbogbo àwọn ará Gátì,+ ẹgbẹ̀ta ọkùnrin tí ó tẹ̀ lé e láti Gátì,+ sì ń sọdá níwájú ọba. 19  Nígbà náà ni ọba sọ fún Ítítáì+ ará Gátì pé: “Èé ṣe tí ìwọ alára pẹ̀lú fi ní láti bá wa lọ? Padà,+ kí o sì lọ máa gbé pẹ̀lú ọba; nítorí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ni ọ́, àti pé, ní àfikún sí èyí, ìgbèkùn ni ọ́ láti àgbègbè rẹ. 20  Àná ni ìgbà tí ìwọ dé, èmi yóò ha sì mú kí o máa bá wa rìn káàkiri+ lónìí, láti lọ nígbà tí mo bá ń lọ sí ibikíbi tí mo bá ń lọ? Padà, kí o sì mú àwọn arakùnrin rẹ padà pẹ̀lú rẹ, [kí Jèhófà sì ṣe] inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ àti ìṣeégbẹ́kẹ̀lé+ [sí ọ]!” 21  Ṣùgbọ́n Ítítáì dá ọba lóhùn, ó sì sọ pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ àti bí olúwa mi ọba ti ń bẹ,+ ibi tí olúwa mi ọba bá wà, yálà fún ikú tàbí fún ìyè, ibẹ̀ ni ibi tí ìránṣẹ́ rẹ yóò wà!”+ 22  Látàrí ìyẹn, Dáfídì sọ fún Ítítáì pé: “Lọ, kí o sì sọdá.” Nítorí náà, Ítítáì+ ará Gátì sọdá, àti gbogbo àwọn ọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú àti gbogbo àwọn ọmọ kéékèèké tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀. 23  Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì ń fi ohùn rara sunkún,+ gbogbo àwọn ènìyàn náà sì ń sọdá, ọba sì dúró sẹ́bàá àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kídírónì,+ gbogbo àwọn ènìyàn náà sì ń sọdá ní ojú ọ̀nà gbayawu tí ó lọ sí aginjù. 24  Sádókù+ sì ń bẹ níhìn-ín pẹ̀lú, gbogbo àwọn ọmọ Léfì+ tí ó ru+ àpótí+ májẹ̀mú Ọlọ́run tòótọ́ sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti gbé àpótí Ọlọ́run tòótọ́ kalẹ̀ lẹ́bàá Ábíátárì,+ títí gbogbo àwọn ènìyàn náà fi parí sísọdá láti inú ìlú ńlá náà. 25  Ṣùgbọ́n ọba sọ fún Sádókù pé: “Gbé àpótí+ Ọlọ́run tòótọ́ padà sí ìlú ńlá náà.+ Bí èmi yóò bá rí ojú rere ní ojú Jèhófà, dájúdájú, òun pẹ̀lú yóò mú mi padà wá, yóò sì jẹ́ kí n rí i àti ibi gbígbé rẹ̀.+ 26  Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ohun tí ó wí ni pé, ‘Èmi kò ní inú dídùn sí ọ,’ èmi nìyí, kí ó ṣe sí mi gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti dára ní ojú rẹ̀.”+ 27  Ọba sì ń bá a lọ láti sọ fún Sádókù àlùfáà pé: “Aríran ni ọ́,+ àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Padà sí ìlú ńlá náà ní àlàáfíà, àti Áhímáásì ọmọkùnrin rẹ pẹ̀lú àti Jónátánì+ ọmọkùnrin Ábíátárì, ọmọkùnrin yín méjèèjì , pẹ̀lú yín. 28  Wò ó, èmi yóò rosẹ̀ lẹ́bàá ibi pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́ odò aginjù, títí ọ̀rọ̀ yóò fi ti ọ̀dọ̀ yín wá láti sọ fún mi.”+ 29  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Sádókù àti Ábíátárì gbé àpótí Ọlọ́run tòótọ́ padà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì ń bá a lọ láti gbé níbẹ̀. 30  Dáfídì sì ń gòkè gba ti ìgòkè Àwọn Ólífì,+ ó ń sunkún bí ó ti ń gòkè lọ, ó bo orí rẹ̀;+ ó sì ń rìn lọ láìwọ bàtà, gbogbo àwọn ènìyàn tí ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀ ni olúkúlùkù wọn bo orí wọn, wọ́n sì ń gòkè lọ, wọ́n ń sunkún bí wọ́n ti ń gòkè lọ.+ 31  A sì ròyìn fún Dáfídì pé: “Áhítófẹ́lì alára wà lára àwọn tí ó di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun+ pẹ̀lú Ábúsálómù.”+ Látàrí èyí, Dáfídì sọ pé:+ “Jọ̀wọ́, Jèhófà,+ sọ ìmọ̀ràn Áhítófẹ́lì di ti òmùgọ̀!”+ 32  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí Dáfídì alára dé téńté orí òkè níbi tí àwọn ènìyàn ti máa ń tẹrí ba fún Ọlọ́run tẹ́lẹ̀ rí, kíyè sí i, Húṣáì+ tí í ṣe Áríkì+ rèé tí ó wá pàdé rẹ̀, pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ gbígbọ̀nya àti ìdọ̀tí ní orí rẹ̀.+ 33  Bí ó ti wù kí ó rí, Dáfídì sọ fún un pé: “Ní ti tòótọ́, bí ìwọ bá bá mi sọdá, nígbà náà, ìwọ yóò di ẹrù sí mi lọ́rùn+ dájúdájú. 34  Ṣùgbọ́n bí o bá padà sí ìlú ńlá náà, tí o sì sọ fún Ábúsálómù ní ti tòótọ́ pé, ‘Ìránṣẹ́ rẹ ni mí, ìwọ Ọba. Mo ti máa ń fi ara mi hàn ní ìránṣẹ́ baba rẹ rí, àní èmi, ní àkókò yẹn, ṣùgbọ́n nísinsìnyí àní ìránṣẹ́ rẹ ni mí,’+ nígbà náà, kí o bá mi mú ìmọ̀ràn Áhítófẹ́lì já sí pàbó.+ 35  Sádókù àti Ábíátárì àlùfáà kò ha wà níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ?+ Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, ohun gbogbo tí o bá gbọ́ láti ilé ọba ni kí o sọ fún Sádókù àti Ábíátárì àlùfáà.+ 36  Wò ó! Àwọn ọmọkùnrin wọn méjèèjì wà níbẹ̀ pẹ̀lú wọn, Áhímáásì+ ti Sádókù àti Jónátánì+ ti Ábíátárì; nípasẹ̀ wọn, kí ẹ fi ohun gbogbo tí ẹ bá gbọ́ ránṣẹ́ sí mi.” 37  Nítorí náà, Húṣáì, alábàákẹ́gbẹ́ Dáfídì,+ wá sínú ìlú ńlá náà. Ní ti Ábúsálómù,+ ó tẹ̀ síwájú láti wá sí Jerúsálẹ́mù.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé