Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Sámúẹ́lì 13:1-39

13  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ pé, Ábúsálómù+ ọmọkùnrin Dáfídì ní arábìnrin kan tí ó lẹ́wà, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Támárì,+ Ámínónì+ ọmọkùnrin Dáfídì sì kó sínú ìfẹ́+ fún un.  Ó sì mú wàhálà-ọkàn bá Ámínónì tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣàìsàn+ ní tìtorí Támárì arábìnrin rẹ̀, nítorí pé wúńdíá ni, ó sì ṣòro ní ojú+ Ámínónì láti ṣe ohunkóhun sí i.+  Wàyí o, Ámínónì ní alábàákẹ́gbẹ́ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhónádábù,+ ọmọkùnrin Ṣímẹ́à,+ arákùnrin Dáfídì; Jèhónádábù sì ṣe ọlọ́gbọ́n gidigidi.  Nítorí náà, ó sọ fún un pé: “Èé ṣe tí ara ìwọ, ọmọkùnrin ọba, fi ń lọ́ kọ́íkọ́í tó yìí, ní òròòwúrọ̀? Ìwọ kì yóò ha sọ fún mi bí?”+ Látàrí èyí, Ámínónì sọ fún un pé: “Mo nífẹ̀ẹ́+ Támárì arábìnrin+ Ábúsálómù arákùnrin mi gidigidi.”  Látàrí èyí, Jèhónádábù sọ fún un pé: “Dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn rẹ, kí o sì ṣe bí aláìsàn.+ Dájúdájú, baba rẹ yóò wá wò ọ́, kí o sì sọ fún un pé, ‘Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Támárì arábìnrin mi wá, kí ó sì fún mi ní oúnjẹ bí aláìsàn tí ń gba ìtọ́jú, òun yóò sì ṣe oúnjẹ ìtùnú ní ìṣojú mi, kí n lè rí i, èmi yóò sì jẹ ẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀.’”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ámínónì dùbúlẹ̀, ó sì ṣe bí aláìsàn,+ nítorí náà, ọba wọlé wá láti wò ó. Nígbà náà ni Ámínónì sọ fún ọba pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Támárì arábìnrin mi wá, kí ó sì yan àkàrà méjì onírìísí ọkàn-àyà ní ìṣojú mi, kí n lè jẹ oúnjẹ ní ọwọ́ rẹ̀ bí aláìsàn tí ń gba ìtọ́jú.”  Látàrí ìyẹn, Dáfídì ránṣẹ́ sí Támárì ní ilé pé: “Jọ̀wọ́, lọ sí ilé Ámínónì arákùnrin rẹ, kí o sì ṣe oúnjẹ ìtùnú fún un.”  Nítorí náà, Támárì lọ sí ilé Ámínónì+ arákùnrin rẹ̀ bí ó ti wà ní ìdùbúlẹ̀. Nígbà náà ni ó mú àpòrọ́ ìyẹ̀fun, ó sì pò ó, ó sì ṣe àwọn àkàrà náà ní ìṣojú rẹ̀, ó sì ṣe àwọn àkàrà onírìísí ọkàn-àyà náà.  Níkẹyìn, ó mú páànù jíjinnú, ó sì dà á jáde níwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n Ámínónì kọ̀ láti jẹun, ó sì sọ pé: “Ẹ mú kí gbogbo ènìyàn jáde kúrò lọ́dọ̀ mi!”+ Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 10  Wàyí o, Ámínónì sọ fún Támárì pé: “Mú oúnjẹ ìtùnú náà wá sínú yàrá inú lọ́hùn-ún, kí n lè jẹ ẹ́ ní ọwọ́ rẹ bí aláìsàn tí ń gba ìtọ́jú.” Nítorí náà, Támárì mú àwọn àkàrà onírìísí ọkàn-àyà tí ó ti ṣe, ó sì mú wọn wọlé wá fún Ámínónì arákùnrin rẹ̀ nínú yàrá inú lọ́hùn-ún. 11  Nígbà tí ó sún mọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ kí ó lè jẹun, ó rá a mú+ ní kíá, ó sì sọ fún un pé: “Wá, sùn tì mí,+ arábìnrin mi.”+ 12  Bí ó ti wù kí ó rí, ó sọ fún un pé: “Rárá, arákùnrin mi! Má ṣe tẹ́ mi lógo;+ nítorí a kì í ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ní Ísírẹ́lì.+ Má hu ìwà ẹ̀gọ̀ tí ń dójú tini yìí.+ 13  Àti èmi—ibo ni èmi yóò mú kí ẹ̀gàn mi lọ? Àti ìwọ—ìwọ yóò dà bí ọ̀kan nínú àwọn òpònú ọkùnrin ní Ísírẹ́lì. Wàyí o, jọ̀wọ́, bá ọba sọ̀rọ̀; nítorí kì yóò kọ̀ láti fi mí fún ọ.” 14  Kò sì gbà láti fetí sí ohùn rẹ̀, ṣùgbọ́n ó lo okun tí ó ju tirẹ̀ lọ, ó sì tẹ́ ẹ lógo,+ ó sì sùn tì í.+ 15  Ámínónì sì bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra rẹ̀ pẹ̀lú ìkórìíra ńláǹlà, nítorí ìkórìíra tí ó fi kórìíra rẹ̀ ju ìfẹ́ tí ó fi nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ rí lọ, tó bẹ́ẹ̀ tí Ámínónì fi sọ fún un pé: “Dìde, máa lọ!” 16  Látàrí èyí, ó sọ fún un pé: “Rárá, arákùnrin mi; nítorí ìwà búburú ti rírán mi lọ yìí ju èyí tí o ti ṣe sí mi!” Kò sì gbà láti fetí sí i. 17  Látàrí ìyẹn, ó pe ẹmẹ̀wà rẹ̀ tí ń ṣèránṣẹ́ fún un, ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, lé ẹni yìí jáde kúrò lọ́dọ̀ mi, sí òde, kí o sì ti ilẹ̀kùn mọ́ ọn.” 18  (Wàyí o, aṣọ abilà+ wà lára rẹ̀; nítorí bí àwọn ọmọbìnrin ọba, àwọn wúńdíá, ṣe máa ń múra nìyẹn pẹ̀lú aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá.) Nítorí náà, aṣèránṣẹ́ rẹ̀ sì tẹ̀ síwájú láti mú un jáde lọ sí òde pátápátá, ó sì ti ilẹ̀kùn mọ́ ọn. 19  Nígbà náà ni Támárì kó eérú+ sí orí rẹ̀, ó sì gbọn aṣọ abilà tí ó wà lára rẹ̀ ya; ó sì ká ọwọ́ lé orí,+ ó sì ń rìn lọ, ó ń ké bí ó ti ń rìn lọ. 20  Látàrí èyí, Ábúsálómù+ arákùnrin rẹ̀ sọ fún un pé: “Ṣé Ámínónì+ arákùnrin rẹ ni ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ? Wàyí o, dákẹ́, arábìnrin mi. Arákùnrin rẹ ni.+ Má fi ọkàn-àyà rẹ sí ọ̀ràn yìí.” Támárì sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní ilé Ábúsálómù arákùnrin rẹ̀ láìbá àwọn yòókù kẹ́gbẹ́. 21  Dáfídì Ọba pàápàá sì gbọ́ nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí,+ ó sì bínú gidigidi.+ 22  Ábúsálómù kò sì bá Ámínónì sọ̀rọ̀, yálà búburú tàbí rere; nítorí Ábúsálómù kórìíra+ Ámínónì lórí òtítọ́ náà pé ó ti tẹ́ Támárì arábìnrin rẹ̀ lógo. 23  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ọdún méjì pé, Ábúsálómù wá ní àwọn olùrẹ́run àgùntàn+ ní Baali-hásórì, èyí tí ó wà nítòsí Éfúráímù;+ Ábúsálómù sì tẹ̀ síwájú láti ké sí gbogbo àwọn ọmọ ọba.+ 24  Nítorí náà, Ábúsálómù wọlé tọ ọba wá, ó sì wí pé: “Kíyè sí i, nísinsìnyí, ìránṣẹ́ rẹ ní àwọn olùrẹ́run àgùntàn! Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ọba, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú, bá ìránṣẹ́ rẹ lọ.” 25  Ṣùgbọ́n ọba sọ fún Ábúsálómù pé: “Rárá, ọmọkùnrin mi! Jọ̀wọ́, má ṣe jẹ́ kí gbogbo wa lọ, kí a má bàa jẹ́ ẹrù ìnira fún ọ.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń rọ̀+ ọ́ ṣáá, kò gbà láti lọ, ṣùgbọ́n ó súre+ fún un. 26  Níkẹyìn, Ábúsálómù sọ pé: “Bí ìwọ kò bá lè lọ, jọ̀wọ́, jẹ́ kí Ámínónì arákùnrin mi bá wa lọ.”+ Látàrí èyí, ọba sọ fún un pé: “Èé ṣe tí yóò fi bá ọ lọ?” 27  Ábúsálómù sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀+ ọ́, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi rán Ámínónì àti gbogbo àwọn ọmọ ọba lọ pẹ̀lú rẹ̀. 28  Lẹ́yìn náà ni Ábúsálómù pàṣẹ fún àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ rí i pé gbàrà tí wáìnì bá ti mú kí ọkàn-àyà Ámínónì wà nínú ipò àríyá,+ dájúdájú, èmi yóò sì sọ fún yín pé, ‘Ẹ ṣá Ámínónì balẹ̀!’ nígbà náà, ẹ gbọ́dọ̀ fi ikú pa á. Ẹ má fòyà.+ Èmi fúnra mi kò ha ti pàṣẹ fún yín bí? Ẹ jẹ́ alágbára, kí ẹ sì fi ara yín hàn ní akíkanjú.” 29  Àwọn ẹmẹ̀wà Ábúsálómù sì tẹ̀ síwájú láti ṣe sí Ámínónì gan-an gẹ́gẹ́ bí Ábúsálómù ti pàṣẹ;+ gbogbo ìyókù àwọn ọmọ ọba sì bẹ̀rẹ̀ sí dìde, olúkúlùkù sì gun ìbaaka tirẹ̀, wọ́n sì fẹsẹ̀ fẹ. 30  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí wọ́n wà lójú ọ̀nà, ìròyìn náà dé ọ̀dọ̀ Dáfídì pé: “Ábúsálómù ti ṣá gbogbo àwọn ọmọ ọba balẹ̀, ọ̀kan kò sì ṣẹ́ kù nínú wọn.” 31  Látàrí èyí, ọba dìde, ó sì gbọn aṣọ ara rẹ̀ ya,+ ó sì dùbúlẹ̀ sórí ilẹ̀,+ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dúró tì í pẹ̀lú ẹ̀wù wọn tí a gbọ̀n ya.+ 32  Bí ó ti wù kí ó rí, Jèhónádábù+ ọmọkùnrin Ṣímẹ́à,+ arákùnrin Dáfídì, dáhùn, ó sì sọ pé: “Kí olúwa mi má rò pé gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí í ṣe ọmọ ọba ni wọ́n ti fi ikú pa, nítorí Ámínónì nìkan ṣoṣo ni ó kú,+ nítorí pé nípa àṣẹ ìtọ́ni Ábúsálómù ni ó fi ṣẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun kan tí a yàn kalẹ̀+ láti ọjọ́ tí ó ti tẹ́+ Támárì arábìnrin rẹ̀+ lógo. 33  Wàyí o, kí olúwa mi ọba má fi ọ̀rọ̀ náà sí ọkàn-àyà rẹ̀ pé, ‘Gbogbo àwọn ọmọ ọba ni ó ti kú’; ṣùgbọ́n Ámínónì nìkan ṣoṣo ni ó kú.” 34  Láàárín àkókò yìí, Ábúsálómù fẹsẹ̀ fẹ.+ Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ́kùnrin náà, olùṣọ́,+ gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì rí i, sì wò ó! ọ̀pọ̀ ènìyàn ń bọ̀ ní ojú ọ̀nà lẹ́yìn rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè ńlá. 35  Látàrí èyí, Jèhónádábù+ sọ fún ọba pé: “Wò ó! Àwọn ọmọ ọba ti wọlé. Ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣẹlẹ̀.”+ 36  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ó parí ọ̀rọ̀ sísọ, kíyè sí i, àwọn ọmọ ọba wọlé, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sunkún; àní ọba àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pàápàá sunkún pẹ̀lú ẹkún sísun gidigidi. 37  Ní ti Ábúsálómù, ó sá lọ, kí ó lè lọ sọ́dọ̀ Tálímáì+ ọmọkùnrin Ámíhúdù ọba Géṣúrì.+ Dáfídì sì ń bá a lọ láti ṣọ̀fọ̀+ ọmọkùnrin rẹ̀ ní gbogbo àwọn ọjọ́ náà. 38  Ní ti Ábúsálómù, ó sá lọ, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí Géṣúrì;+ ó sì wà níbẹ̀ fún ọdún mẹ́ta. 39  Níkẹyìn, aáyun ń yun ọkàn Dáfídì Ọba láti jáde tọ Ábúsálómù lọ; nítorí ó ti tu ara rẹ̀ nínú nípa Ámínónì, nítorí pé ó ti kú.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé