Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Sámúẹ́lì 12:1-31

12  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti rán Nátánì+ sí Dáfídì. Nítorí náà, ó wọlé tọ̀ ọ́ wá,+ ó sì sọ fún un pé: “Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọkùnrin méjì ń bẹ ní ìlú ńlá kan, ọ̀kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, èkejì sì jẹ́ aláìnílọ́wọ́.  Ó ṣẹlẹ̀ pé ọlọ́rọ̀ náà ní àgùntàn àti màlúù púpọ̀ gan-an;+  ṣùgbọ́n ọkùnrin aláìnílọ́wọ́ náà kò ní nǹkan kan bí kò ṣe abo ọ̀dọ́ àgùntàn kan, èyí kékeré kan, tí ó rà.+ Ó sì ń pa á mọ́ láàyè, ó sì ń dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ àti pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, gbogbo wọn lápapọ̀. Ara òkèlè rẹ̀ ni ó ti ń jẹ, inú ife rẹ̀ sì ni ó ti ń mu, oókan àyà rẹ̀ sì ni ó máa ń dùbúlẹ̀ sí, ó sì wá dà bí ọmọbìnrin fún un.  Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, àlejò kan tọ ọlọ́rọ̀ náà wá, ṣùgbọ́n ó fà sẹ́yìn kúrò ní mímú lára àgùntàn tirẹ̀ àti màlúù tirẹ̀ láti pèsè rẹ̀ fún arìnrìn-àjò tí ó wọlé tọ̀ ọ́ wá. Nítorí náà, ó mú abo ọ̀dọ́ àgùntàn ọkùnrin aláìnílọ́wọ́ náà, ó sì pèsè rẹ̀ fún ọkùnrin tí ó wọlé tọ̀ ọ́ wá.”+  Látàrí èyí, ìbínú Dáfídì gbóná gidigidi sí ọkùnrin náà,+ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi sọ fún Nátánì pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ,+ ikú tọ́ sí ọkùnrin tí ó ṣe èyí!+  Àti ní ti abo ọ̀dọ́ àgùntàn náà, òun yóò fi mẹ́rin+ san àsanfidípò,+ gẹ́gẹ́ bí àbájáde òtítọ́ náà pé ó ti ṣe nǹkan yìí àti nítorí pé kò ní ìyọ́nú.”+  Nígbà náà ni Nátánì sọ fún Dáfídì pé: “Ìwọ fúnra rẹ ni ọkùnrin náà! Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Èmi ni mo fòróró yàn+ ọ́ ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì, èmi sì ni mo dá ọ nídè+ kúrò lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù.  Èmi sì múra tán láti fún ọ ní ilé olúwa rẹ+ àti láti fi àwọn aya olúwa rẹ+ sí oókan àyà rẹ, àti láti fún ọ ní ilé Ísírẹ́lì àti ti Júdà.+ Bí kò bá sì tó, èmi múra tán láti fi àwọn nǹkan bí ìwọ̀nyí àti bí àwọn nǹkan mìíràn kún un fún ọ.+  Èé ṣe tí o fi tẹ́ńbẹ́lú ọ̀rọ̀ Jèhófà nípa ṣíṣe ohun tí ó burú+ ní ojú rẹ̀? Ùráyà ọmọ Hétì ni ìwọ fi idà ṣá balẹ̀,+ aya rẹ̀ ni ìwọ sì mú ṣe aya rẹ,+ òun ni ìwọ sì fi idà àwọn ọmọ Ámónì pa. 10  Wàyí o, idà+ kì yóò lọ kúrò ní ilé tìrẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ gẹ́gẹ́ bí àbájáde òtítọ́ náà pé o tẹ́ńbẹ́lú mi tó bẹ́ẹ̀ tí o fi sọ aya Ùráyà ọmọ Hétì di aya rẹ.’ 11  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò gbé ìyọnu àjálù dìde sí ọ láti inú ilé rẹ;+ dájúdájú, èmi yóò sì gba àwọn aya rẹ ní ojú rẹ, èmi yóò sì fi wọ́n fún ọmọnìkejì rẹ,+ òun yóò sì sùn ti àwọn aya rẹ dájúdájú ní ojú oòrùn yìí.+ 12  Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìkọ̀kọ̀+ ni ìwọ ti ṣe é, èmi, ní tèmi, yóò ṣe nǹkan yìí ní iwájú gbogbo Ísírẹ́lì+ àti ní iwájú oòrùn.’”+ 13  Dáfídì wá sọ+ fún Nátánì pé: “Èmi ti ṣẹ̀ sí Jèhófà.”+ Látàrí èyí, Nátánì sọ fún Dáfídì pé: “Jèhófà, ẹ̀wẹ̀, jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kọjá lọ.+ Ìwọ kì yóò kú.+ 14  Láìka èyí sí, nítorí pé ìwọ hùwà àìlọ́wọ̀+ sí Jèhófà láìsí àní-àní, nípa nǹkan yìí, ọmọkùnrin náà gan-an pẹ̀lú, tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí fún ọ, yóò kú dájúdájú.”+ 15  Lẹ́yìn náà, Nátánì lọ sí ilé rẹ̀. Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti mú ìyọnu àgbálù+ bá ọmọ tí aya Ùráyà bí fún Dáfídì tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣàìsàn. 16  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí wá Ọlọ́run tòótọ́ nítorí ọmọdékùnrin náà, Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí gba ààwẹ̀ mímúná janjan,+ ó sì wọlé, ó sì dùbúlẹ̀ sórí ilẹ̀ mọ́jú.+ 17  Nítorí náà, àwọn àgbà ọkùnrin ilé rẹ̀ dìde dúró lẹ́bàá rẹ̀ láti gbé e dìde kúrò lórí ilẹ̀, ṣùgbọ́n kò gbà, kò sì bá wọn jẹ oúnjẹ.+ 18  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ keje pé, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọmọ náà kú. Àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì fòyà láti sọ fún un pé ọmọ náà ti kú; nítorí wọ́n sọ pé: “Wò ó! Nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láàyè, a bá a sọ̀rọ̀, kò sì fetí sí ohùn wa; nítorí náà, báwo ni a ṣe lè sọ fún un pé, ‘Ọmọ náà ti kú’? Nígbà náà, òun yóò ṣe ohun búburú dájúdájú.” 19  Nígbà tí Dáfídì wá rí i pé àwọn ìránṣẹ́ òun ń jùmọ̀ sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́, Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí fi òye mọ̀ pé ọmọ náà ti kú. Nítorí náà, Dáfídì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ṣé ọmọ náà ti kú ni?” Wọ́n fèsì pé: “Ó ti kú.” 20  Nígbà náà ni Dáfídì dìde kúrò lórí ilẹ̀, ó sì wẹ̀, ó sì fi òróró para,+ ó sì pààrọ̀ aṣọ àlàbora rẹ̀, ó sì wá sí ilé+ Jèhófà, ó sì wólẹ̀;+ lẹ́yìn èyí tí ó wá sínú ilé tirẹ̀, ó sì béèrè, wọ́n sì gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú rẹ̀ ní kánmọ́kánmọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹun. 21  Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé: “Kí ni ohun tí o ṣe yìí túmọ̀ sí? Nítorí ọmọ náà, nígbà tí ó wà láàyè, o gbààwẹ̀, o sì ń sunkún ṣáá; gbàrà tí ọmọ náà sì kú, o dìde, o sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ oúnjẹ.” 22  Ó fèsì pé: “Nígbà tí ọmọ náà ṣì wà láàyè mo gbààwẹ̀+ ní tòótọ́, mo sì ń sunkún ṣáá,+ nítorí mo sọ fún ara mi pé, ‘Ta ní mọ̀ bóyá Jèhófà lè fi ojú rere hàn sí mi, tí ọmọ náà yóò sì wà láàyè dájúdájú?’+ 23  Nísinsìnyí tí ó ti kú, èé ṣe tí èmi yóò fi máa gbààwẹ̀? Èmi ha lè tún mú un padà wá?+ Èmi ni yóò tọ̀ ọ́ lọ,+ ṣùgbọ́n, ní tirẹ̀, òun kì yóò padà tọ̀ mí wá.”+ 24  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí tu Bátí-ṣébà aya rẹ̀ nínú.+ Síwájú sí i, ó wọlé tọ̀ ọ́, ó sì sùn tì í. Nígbà tí ó ṣe, ó bí ọmọkùnrin kan,+ a sì wá pe orúkọ rẹ̀ ní Sólómọ́nì.+ Jèhófà tìkára rẹ̀ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.+ 25  Nítorí náà, ó ránṣẹ́ nípasẹ̀ Nátánì+ wòlíì, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jedidáyà, nítorí Jèhófà. 26  Jóábù+ sì ń bá a lọ láti bá Rábà+ ti àwọn ọmọ Ámónì jà, ó sì wá gba ìlú ńlá ìjọba náà. 27  Nítorí náà, Jóábù rán àwọn ońṣẹ́ sí Dáfídì, ó sì sọ pé: “Mo ti bá Rábà jà.+ Mo ti gba ìlú ńlá tí ó ní omi pẹ̀lú. 28  Wàyí o, kó ìyókù àwọn ènìyàn náà jọ, kí o sì dó ti ìlú ńlá náà, kí o sì gbà á; kí èmi fúnra mi má bàa jẹ́ ẹni tí yóò gba ìlú ńlá náà, kí a má sì wá fi orúkọ mi pè é.” 29  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Dáfídì kó gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ, ó sì lọ sí Rábà, ó sì bá a jà, ó sì gbà á. 30  Ó sì wá mú adé Málíkámù kúrò ní orí rẹ̀,+ ìwọ̀n èyí tí ó jẹ́ tálẹ́ńtì wúrà kan, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn òkúta iyebíye; ó sì wá wà ní orí Dáfídì. Ohun ìfiṣèjẹ+ tí ó kó jáde láti inú ìlú ńlá náà sì pọ̀ gidigidi. 31  Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀ ni ó sì kó jáde, kí ó lè fi wọ́n sídìí fífi ayùn rẹ́ òkúta àti sídìí àwọn ohun èlò mímú tí a fi irin ṣe+ àti sídìí àáké tí a fi irin ṣe, ó sì mú kí wọ́n sìn nídìí bíríkì ṣíṣe. Bẹ́ẹ̀ sì ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe sí gbogbo àwọn ìlú ńlá àwọn ọmọ Ámónì. Níkẹyìn, Dáfídì àti gbogbo àwọn ènìyàn náà padà sí Jerúsálẹ́mù.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé