Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Sámúẹ́lì 11:1-27

11  Ó sì ṣẹlẹ̀ nígbà ìyípo ọdún,+ nígbà tí àwọn ọba máa ń jáde ogun,+ pé Dáfídì tẹ̀ síwájú láti rán Jóábù àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ àti gbogbo Ísírẹ́lì, pé kí wọ́n lè run+ àwọn ọmọ Ámónì, kí wọ́n sì sàga ti Rábà,+ nígbà tí Dáfídì ń gbé ní Jerúsálẹ́mù.  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní àkókò ìrọ̀lẹ́ pé, Dáfídì tẹ̀ síwájú láti dìde lórí ibùsùn rẹ̀, ó sì rìn káàkiri lórí òrùlé+ ilé ọba; láti orí òrùlé náà ni ó sì ti tajú kán rí+ obìnrin kan tí ń wẹ ara rẹ̀, obìnrin náà sì dára gan-an ní ìrísí.+  Nígbà náà ni Dáfídì ránṣẹ́, ó sì ṣe ìwádìí nípa obìnrin náà,+ ẹnì kan sì sọ pé: “Bátí-ṣébà+ ọmọbìnrin Élíámù+ aya Ùráyà+ ọmọ Hétì+ kọ́ yìí?”  Lẹ́yìn ìyẹn, Dáfídì rán àwọn ońṣẹ́ kí ó lè mú un.+ Nítorí náà, ó wọlé tọ̀ ọ́+ wá, ó sì sùn tì í,+ nígbà tí obìnrin náà ń sọ ara rẹ di mímọ́ kúrò nínú ohun àìmọ́ rẹ̀.+ Lẹ́yìn náà, ó padà sí ilé rẹ̀.  Obìnrin náà sì lóyún. Nítorí náà, ó ránṣẹ́, ó sì sọ fún Dáfídì, ó sì wí pé: “Mo ti lóyún.”  Látàrí èyí, Dáfídì ránṣẹ́ sí Jóábù, pé: “Rán Ùráyà ọmọ Hétì sí mi.” Nítorí náà, Jóábù rán Ùráyà sí Dáfídì.  Nígbà tí Ùráyà dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè bí Jóábù ti ń ṣe sí àti bí àwọn ènìyàn náà ti ń ṣe sí àti bí ogun náà ti ń ṣe sí.  Níkẹyìn, Dáfídì sọ fún Ùráyà pé: “Sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ, kí o sì wẹ ẹsẹ̀ rẹ.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ùráyà jáde kúrò ní ilé ọba, ẹ̀bùn onínúure láti ọ̀dọ̀ ọba sì jáde tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.  Bí ó ti wù kí ó rí, Ùráyà dùbúlẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà ilé ọba pẹ̀lú gbogbo àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀ yòókù, kò sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀. 10  Nítorí náà, wọ́n sọ fún Dáfídì, pé: “Ùráyà kò sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀.” Látàrí ìyẹn, Dáfídì sọ fún Ùráyà pé: “Ìrìn àjò ni ìwọ ti wọlé wá, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Èé ṣe tí o kò fi sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ?” 11  Látàrí èyí, Ùráyà sọ fún Dáfídì pé: “Àpótí+ àti Ísírẹ́lì àti Júdà ń gbé nínú àwọn àtíbàbà, olúwa mi Jóábù àti àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi+ sì dó sí orí pápá, èmi—èmi yóò ha sì lọ sínú ilé mi láti jẹ àti láti mu àti láti sùn ti aya mi?+ Bí ìwọ ti ń bẹ àti bí ọkàn rẹ ti ń bẹ,+ èmi kì yóò ṣe nǹkan yìí!” 12  Nígbà náà ni Dáfídì sọ fún Ùráyà pé: “Gbé ìhín lónìí pẹ̀lú, lọ́la èmi yóò sì rán ọ lọ.” Nítorí náà, Ùráyà ń bá a nìṣó ní gbígbé ní Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ yẹn àti ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e. 13  Síwájú sí i, Dáfídì pè é, kí ó lè jẹun níwájú rẹ̀, kí ó sì mu. Nítorí náà, ó mú kí ó mutí para.+ Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó jáde lọ ní alẹ́ láti dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, kò sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀. 14  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní òwúrọ̀ pé, Dáfídì tẹ̀ síwájú láti kọ lẹ́tà+ kan sí Jóábù, ó sì fi í ránṣẹ́ nípa ọwọ́ Ùráyà. 15  Nítorí náà, ó kọ ọ́ sínú lẹ́tà náà, pé:+ “Ẹ fi Ùráyà sí iwájú ibi tí ìjà ogun ti gbóná jù lọ,+ kí ẹ sì sá padà lẹ́yìn rẹ̀, kí a sì ṣá a balẹ̀, kí ó sì kú.”+ 16  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí Jóábù ti ń ṣọ́ ìlú ńlá náà, ó fi Ùráyà sí ibi tí ó mọ̀ pé àwọn akíkanjú ọkùnrin wà.+ 17  Nígbà tí àwọn ọkùnrin ìlú ńlá náà jáde wá, tí wọ́n sì ń bá Jóábù jà, nígbà náà, díẹ̀ lára àwọn ènìyàn náà, àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì, ṣubú, Ùráyà ọmọ Hétì sì kú pẹ̀lú.+ 18  Jóábù wá ránṣẹ́ wàyí, kí òun lè ròyìn gbogbo ọ̀ràn ogun náà fún Dáfídì. 19  Ó sì ń bá a lọ láti pàṣẹ fún ońṣẹ́ náà, pé: “Gbàrà tí o bá parí sísọ̀rọ̀ nípa gbogbo ọ̀ràn ogun náà fún ọba, 20  nígbà náà, yóò ṣẹlẹ̀ pé, bí ìhónú ọba bá ru, tí ó sì sọ fún ọ pé, ‘Èé ṣe tí ẹ fi ní láti sún mọ́ ìlú ńlá náà tó bẹ́ẹ̀ láti jà? Ṣé ẹ kò mọ̀ pé wọn yóò tafà láti orí ògiri ni? 21  Ta ni ẹni tí ó ṣá Ábímélékì+ ọmọkùnrin Jerubéṣétì+ balẹ̀? Kì í ha ṣe obìnrin ni ó ju ọmọ ọlọ lù ú+ láti orí ògiri, tí ó fi kú ní Tébésì?+ Èé ṣe tí ẹ fi ní láti sún mọ́ ògiri náà tó bẹ́ẹ̀?’ kí ìwọ pẹ̀lú sọ pé, ‘Ìránṣẹ́ rẹ Ùráyà ọmọ Hétì kú pẹ̀lú.’”+ 22  Nítorí náà, ońṣẹ́ náà lọ, ó sì wá sọ nípa gbogbo èyí tí Jóábù rán an fún Dáfídì. 23  Ońṣẹ́ náà sì ń bá a lọ láti sọ fún Dáfídì pé: “Ọwọ́ àwọn ọkùnrin náà le ju tiwa lọ, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi jáde wá láti gbéjà kò wá nínú pápá; ṣùgbọ́n a ń bá a nìṣó ní títì wọ́n lọ títí dé ibi àtiwọ ẹnubodè. 24  Àwọn ọ̀tafà sì ń bá a nìṣó ní títafà sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ láti orí ògiri,+ tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ ọba fi kú; ìránṣẹ́ rẹ Ùráyà ọmọ Hétì sì kú pẹ̀lú.”+ 25  Látàrí ìyẹn, Dáfídì sọ fún ońṣẹ́ náà pé: “Èyí ni ohun tí ìwọ yóò sọ fún Jóábù, ‘Má ṣe jẹ́ kí ọ̀ràn yìí jẹ́ ohun tí ó burú ní ojú rẹ, nítorí idà a máa jẹ+ ẹni tibí àti tọ̀hún run. Mú ìjà ogun rẹ gbóná janjan sí ìlú ńlá náà, kí o sì wó o palẹ̀.’+ Kí o sì fún un ní ìṣírí.” 26  Aya Ùráyà sì wá gbọ́ pé Ùráyà ọkọ òun ti kú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pohùn réré ẹkún+ nítorí olúwa rẹ̀.+ 27  Nígbà tí sáà ìṣọ̀fọ̀+ kọjá, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Dáfídì ránṣẹ́, ó sì mú un wálé sí ilé ara rẹ̀, ó sì wá di aya rẹ̀.+ Nígbà tí ó ṣe, ó bí ọmọkùnrin kan fún un, ṣùgbọ́n ohun tí Dáfídì ṣe jẹ́ ohun tí ó burú+ ní ojú+ Jèhófà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé