Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Sámúẹ́lì 10:1-19

10  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà pé ọba àwọn ọmọ Ámónì+ wá kú, Hánúnì ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.+  Látàrí èyí, Dáfídì sọ pé: “Èmi yóò ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí Hánúnì ọmọkùnrin Náháṣì, gan-an gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ ti ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí mi.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Dáfídì ránṣẹ́ nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀+ láti tù ú nínú nítorí baba rẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì wá sí ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì.  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ aládé àwọn ọmọ Ámónì sọ fún Hánúnì olúwa wọn pé: “Dáfídì ha ń bọlá fún baba rẹ ní ojú rẹ ní ti pé ó rán àwọn olùtùnú sí ọ? Kì í ha ṣe nítorí àtiwá wo ìlú ńlá yìí yíká-yíká àti láti ṣe amí+ rẹ̀ àti láti bì í ṣubú ni Dáfídì fi rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí ọ?”+  Nítorí náà, Hánúnì mú àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì, ó sì fá ààbọ̀ irùngbọ̀n+ wọn, ó sì gé ẹ̀wù wọn ní ààbọ̀ dé ekiti ìdí wọn, ó sì rán wọn lọ.+  Lẹ́yìn náà, àwọn ènìyàn ròyìn rẹ̀ fún Dáfídì, kíákíá, ó sì ránṣẹ́ lọ pàdé wọn, nítorí pé àwọn ọkùnrin náà wá rí i pé a tẹ́ wọn lógo gidigidi; ọba sì tẹ̀ síwájú láti sọ pé: “Ẹ máa gbé ní Jẹ́ríkò+ títí irùngbọ̀n yín yóò fi hù lọ́pọ̀ yanturu. Lẹ́yìn náà ni kí ẹ padà.”  Nígbà tí ó ṣe, àwọn ọmọ Ámónì rí i pé wọ́n ti di òórùn burúkú+ sí Dáfídì, àwọn ọmọ Ámónì sì tẹ̀ síwájú láti ránṣẹ́, wọ́n sì háyà àwọn ará Síríà ti Bẹti-réhóbù+ àti àwọn ará Síríà ti Sóbà,+ ọ̀kẹ́ kan àwọn ọkùnrin tí ń fẹsẹ̀ rìn, àti ọba Máákà,+ ẹgbẹ̀rún ọkùnrin, àti Íṣítóbù, ẹgbẹ̀rún méjì lá ọkùnrin.  Nígbà tí Dáfídì gbọ́, nígbà náà, ó rán Jóábù àti gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti àwọn ọkùnrin alágbára ńlá.+  Àwọn ọmọ Ámónì sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ, wọ́n sì tẹ́ ìtẹ́gun ní ibi àtiwọ ẹnubodè, àwọn ará Síríà ti Sóbà àti Réhóbù,+ àti Íṣítóbù àti Máákà pẹ̀lú dá wà nínú pápá gbalasa.+  Nígbà tí Jóábù rí i pé ìgbóguntini nínú ìjà ogun wá dojú kọ òun láti iwájú àti láti ẹ̀yìn, ní kíá, ó yan àwọn kan lára gbogbo àwọn ààyò+ ọkùnrin ní Ísírẹ́lì, ó sì fi wọ́n tẹ́ ìtẹ́gun láti pàdé àwọn ará Síríà. 10  Ìyókù àwọn ènìyàn náà sì ni ó fi sí ọwọ́ Ábíṣáì+ arákùnrin rẹ̀, kí ó lè fi wọ́n tẹ́ ìtẹ́gun láti pàdé àwọn ọmọ Ámónì.+ 11  Ó sì tẹ̀ síwájú láti sọ pé: “Bí àwọn ará Síríà bá le jù fún mi, nígbà náà, kí ìwọ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìgbàlà fún mi; ṣùgbọ́n bí àwọn ọmọ Ámónì fúnra wọn bá le jù fún ọ, kí èmi pẹ̀lú wá láti gbà ọ́ là.+ 12  Jẹ́ alágbára, kí a lè fi ara wa hàn ní onígboyà+ nítorí àwọn ènìyàn wa àti nítorí àwọn ìlú ńlá Ọlọ́run wa;+ ní ti Jèhófà, òun yóò ṣe ohun tí ó dára ní ojú rẹ̀.”+ 13  Nígbà náà ni Jóábù àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tẹ̀ síwájú síbi ìjà ogun láti gbéjà ko àwọn ará Síríà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ kúrò níwájú rẹ̀.+ 14  Ní ti àwọn ọmọ Ámónì, wọ́n rí i pé àwọn ará Síríà ti sá lọ, wọ́n sì fẹsẹ̀ fẹ kúrò níwájú Ábíṣáì, wọ́n sì tipa báyìí wọ ìlú ńlá náà.+ Lẹ́yìn ìyẹn, Jóábù padà dé láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì, ó sì wá sí Jerúsálẹ́mù.+ 15  Nígbà tí àwọn ará Síríà rí i pé a ti ṣẹ́gun wọn níwájú Ísírẹ́lì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kó ara wọn jọpọ̀. 16  Nítorí náà, Hadadésà+ ránṣẹ́, ó sì mú àwọn ará Síríà tí ó wà ní ẹkùn ilẹ̀ Odò+ jáde wá; lẹ́yìn náà, wọ́n wá sí Hélámù, pẹ̀lú Ṣóbákì+ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Hadadésà níwájú wọn. 17  Nígbà tí a ròyìn fún Dáfídì, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ, ó sì sọdá Jọ́dánì, ó sì wá sí Hélámù. Àwọn ará Síríà tẹ́ ìtẹ́gun wàyí láti pàdé Dáfídì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a jà.+ 18  Àwọn ara Síríà sì fẹsẹ̀ fẹ+ kúrò níwájú Ísírẹ́lì; Dáfídì sì wá pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin oníkẹ̀kẹ́ ẹṣin+ àti ọ̀kẹ́ méjì ẹlẹ́ṣin lára àwọn ará Síríà, Ṣóbákì olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn ni ó sì ṣá balẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú níbẹ̀.+ 19  Nígbà tí gbogbo àwọn ọba,+ àwọn ìránṣẹ́ Hadadésà, rí i pé a ti ṣẹ́gun+ wọn níwájú Ísírẹ́lì, kíákíá ni wọ́n wá àlàáfíà pẹ̀lú Ísírẹ́lì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sìn wọ́n;+ àyà sì fo àwọn ará Síríà láti tún gbìyànjú gbígba àwọn ọmọ Ámónì là.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé