Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Pétérù 3:1-18

3  Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ní báyìí o, èyí ni lẹ́tà kejì tí mo ń kọ sí yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nínú èyí tí mo kọ́kọ́ kọ,+ nínú èyí tí èmi ń ru agbára ìrònú yín ṣíṣe kedere sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìránnilétí,+  pé kí ẹ máa rántí àwọn àsọjáde tí àwọn wòlíì mímọ́+ ti sọ ní ìṣáájú àti àṣẹ Olúwa àti Olùgbàlà nípasẹ̀ àwọn àpọ́sítélì yín.+  Nítorí ẹ mọ èyí lákọ̀ọ́kọ́, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,+ àwọn olùyọṣùtì+ yóò wá pẹ̀lú ìyọṣùtì wọn, wọn yóò máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn+  wọn yóò sì máa wí pé:+ “Wíwàníhìn-ín rẹ̀ yìí tí a ti ṣèlérí dà?+ Họ́wù, láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ti sùn nínú ikú, ohun gbogbo ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.”+  Nítorí, ní ìbámu pẹ̀lú ìdàníyàn wọn, òtítọ́ yìí bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí wọn, pé àwọn ọ̀run+ wà láti ìgbà láéláé àti ilẹ̀ ayé kan tí ó dúró digbí-digbí láti inú omi+ àti ní àárín omi+ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run;  àti nípasẹ̀ ohun wọnnì, ayé ìgbà yẹn jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi bò ó mọ́lẹ̀.+  Ṣùgbọ́n nípa ọ̀rọ̀ kan náà, àwọn ọ̀run+ àti ilẹ̀ ayé+ tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná,+ a sì ń fi wọ́n pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́+ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.+  Bí ó ti wù kí ó rí, ẹ má ṣe jẹ́ kí òtítọ́ kan yìí bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, pé ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Jèhófà jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ̀rún ọdún àti ẹgbẹ̀rún ọdún gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kan.+  Jèhófà kò fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀,+ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan ti ka ìfi-nǹkan-falẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.+ 10  Síbẹ̀ ọjọ́ Jèhófà+ yóò dé gẹ́gẹ́ bí olè,+ nínú èyí tí àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ+ pẹ̀lú ariwo tí ó dún ṣì-ì-ì,+ ṣùgbọ́n àwọn ohun ìpìlẹ̀ tí ó ti gbóná janjan yóò di yíyọ́,+ ilẹ̀ ayé+ àti àwọn iṣẹ́ tí ń bẹ nínú rẹ̀ ni a ó sì wá rí.+ 11  Níwọ̀n bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti di yíyọ́ báyìí, irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, 12  ní dídúró de+ wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà+ àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí, nípasẹ̀ èyí tí àwọn ọ̀run tí wọ́n ti gbiná yóò di yíyọ́,+ tí àwọn ohun ìpìlẹ̀ tí ó ti gbóná janjan yóò sì yọ́! 13  Ṣùgbọ́n ọ̀run tuntun+ àti ilẹ̀ ayé tuntun+ wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.+ 14  Nítorí bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, níwọ̀n bí ẹ ti ń dúró de nǹkan wọ̀nyí, ẹ sa gbogbo ipá yín kí òun lè bá yín nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ní àìléèérí+ àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà.+ 15  Síwájú sí i, ẹ ka sùúrù Olúwa wa sí ìgbàlà, gan-an gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù arákùnrin wa olùfẹ́ ọ̀wọ́n ní ìbámu pẹ̀lú ọgbọ́n+ tí a fi fún un ti kọ̀wé sí yín pẹ̀lú,+ 16  ní sísọ̀rọ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe pẹ̀lú nínú gbogbo lẹ́tà rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ohun kan tí ó nira láti lóye wà nínú wọn, èyí tí àwọn aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn aláìdúrósójúkan ń lọ́, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń lọ́ àwọn Ìwé Mímọ́+ yòókù pẹ̀lú, sí ìparun ara wọn. 17  Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, bí ẹ ti ní ìmọ̀ èyí tẹ́lẹ̀,+ ẹ ṣọ́ ara yín kí a má bàa mú yín lọ pẹ̀lú wọn nípa ìṣìnà àwọn aṣàyàgbàǹgbà pe òfin níjà, kí ẹ sì ṣubú kúrò nínú ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin tiyín.+ 18  Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní dídàgbà nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti ìmọ̀ nípa Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi.+ Òun ni kí ògo jẹ́ tirẹ̀ nísinsìnyí àti títí dé ọjọ́ ayérayé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé