Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Pétérù 2:1-22

2  Àmọ́ ṣá o, àwọn wòlíì èké wà pẹ̀lú láàárín àwọn ènìyàn náà, gẹ́gẹ́ bí àwọn olùkọ́ èké yóò ti wà pẹ̀lú láàárín yín.+ Àwọn wọ̀nyí ni yóò yọ́ mú àwọn ẹ̀ya ìsìn tí ń pani run wọlé wá, wọn yóò sì sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú olúwa tí ó rà wọ́n pàápàá,+ wọn yóò mú ìparun yíyára kánkán wá sórí ara wọn.  Síwájú sí i, ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò tẹ̀ lé+ àwọn ìwà àìníjàánu wọn,+ ní tìtorí àwọn wọ̀nyí, ọ̀nà òtítọ́ yóò sì di èyí tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ tèébútèébú.+  Bákan náà, pẹ̀lú ojúkòkòrò, wọn yóò fi àwọn ayédèrú ọ̀rọ̀ kó yín nífà.+ Ṣùgbọ́n ní tiwọn, ìdájọ́ náà láti ìgbà láéláé+ kò falẹ̀, ìparun wọn kò sì tòògbé.+  Dájúdájú, bí Ọlọ́run kò bá fawọ́ sẹ́yìn ní fífìyàjẹ àwọn áńgẹ́lì+ tí ó ṣẹ̀, ṣùgbọ́n, nípa sísọ wọ́n sínú Tátárọ́sì,+ ó jù wọ́n sínú àwọn kòtò òkùnkùn biribiri láti fi wọ́n pa mọ́ de ìdájọ́;+  kò sì fawọ́ sẹ́yìn ní fífìyàjẹ ayé ìgbàanì,+ ṣùgbọ́n ó pa Nóà, oníwàásù òdodo+ mọ́ láìséwu pẹ̀lú àwọn méje mìíràn+ nígbà tí ó mú àkúnya omi+ wá sórí ayé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run;  àti nípa sísọ àwọn ìlú ńlá náà Sódómù àti Gòmórà di eérú, ó dá wọn lẹ́bi,+ ní fífi àpẹẹrẹ kan lélẹ̀ fún àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run nípa àwọn ohun tí ń bọ̀;+  ó sì dá Lọ́ọ̀tì olódodo nídè,+ ẹni tí ìkẹ́ra-ẹni-bàjẹ́ nínú ìwà àìníjàánu àwọn aṣàyàgbàǹgbà pe òfin níjà kó wàhálà-ọkàn bá gidigidi+  nítorí ohun tí ọkùnrin olódodo yẹn rí, tí ó sì gbọ́ nígbà tí ó ń gbé láàárín wọn láti ọjọ́ dé ọjọ́ ń mú ọkàn òdodo rẹ̀ joró nítorí àwọn ìṣe àìlófin wọn—  Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò,+ ṣùgbọ́n láti fi àwọn aláìṣòdodo pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ láti ké wọn kúrò,+ 10  bí ó ti wù kí ó rí, ní pàtàkì, àwọn tí ń tọ ẹran ara lẹ́yìn pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn láti sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin,+ tí wọ́n sì ń fojú tẹ́ńbẹ́lú ipò olúwa.+ Wọ́n jẹ́ aṣàyàgbàǹgbà, aṣetinú-ẹni, wọn kì í wárìrì níwájú àwọn ẹni ògo ṣùgbọ́n wọn a máa sọ̀rọ̀ tèébútèébú,+ 11  nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn áńgẹ́lì, bí wọ́n tilẹ̀ pọ̀ gidigidi ní okun àti agbára, kì í mú ẹ̀sùn wá lòdì sí wọn nínú àwọn ọ̀rọ̀ èébú,+ wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ọ̀wọ̀ fún Jèhófà.+ 12  Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wọ̀nyí, gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹran tí kì í ronú, tí a bí lọ́nà ti ẹ̀dá fún mímú àti píparun, nínú àwọn ohun tí wọ́n ti jẹ́ aláìmọ̀kan, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ tèébútèébú,+ yóò tilẹ̀ jìyà ìparun ní ipa ọ̀nà ìparun tiwọn, 13  ní ṣíṣe àìtọ́ sí ara àwọn tìkára wọn+ gẹ́gẹ́ bí èrè fún ìwà àìtọ́.+ Wọ́n ka ìgbésí ayé fàájì ní ìgbà ọ̀sán sí adùn.+ Wọ́n jẹ́ èérí àti àbààwọ́n, wọ́n ń kẹ́ra bàjẹ́ pẹ̀lú inú dídùn aláìníjàánu nínú àwọn ẹ̀kọ́ ìtannijẹ wọn bí wọ́n ti ń jẹ àsè pa pọ̀ pẹ̀lú yín.+ 14  Wọ́n ní ojú tí ó kún fún panṣágà,+ tí kò sì lè yọwọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀,+ wọ́n sì ń ré àwọn ọkàn tí kò dúró sójú kan lọ. Wọ́n ní ọkàn-àyà tí a fi ojúkòkòrò kọ́.+ Wọ́n jẹ́ ọmọ ègún.+ 15  Ní pípa ipa ọ̀nà títọ́ tì, a ti ṣì wọ́n lọ́nà. Wọ́n ti tẹ̀ lé ipa ọ̀nà Báláámù,+ ọmọkùnrin Béórì, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ èrè ìwà àìtọ́,+ 16  ṣùgbọ́n tí ó gba ìbáwí àfitọ́nisọ́nà nítorí ṣíṣẹ̀ tí òun fúnra rẹ̀ ṣẹ̀ sí ohun tí ó tọ́.+ Ẹranko arẹrù tí kò lè fọhùn, ní sísọ àsọjáde pẹ̀lú ohùn ènìyàn,+ dí ipa ọ̀nà wèrè wòlíì náà lọ́wọ́.+ 17  Àwọn wọ̀nyí jẹ́ àwọn ojúsun tí kò ní omi,+ àti ìkùukùu tí ìjì lílenípá ń gbá kiri, àwọn ni a sì ti fi ìdúdú òkùnkùn pa mọ́ dè.+ 18  Nítorí tí wọ́n ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà tí kò ní èrè, àti nípa àwọn ìfẹ́-ọkàn ara+ àti nípa àwọn ìwà tí kò níjàánu, àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yè bọ́+ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ń hùwà nínú ìṣìnà ni wọ́n ń ré lọ.+ 19  Nígbà tí wọ́n ń ṣèlérí òmìnira fún wọn,+ àwọn fúnra wọ́n wà gẹ́gẹ́ bí ẹrú ìdíbàjẹ́.+ Nítorí ẹnì yòówù tí ẹlòmíràn ṣẹ́pá rẹ̀ ni ẹni yìí sọ di ẹrú.+ 20  Dájúdájú, bí ó bá jẹ́ pé, lẹ́yìn tí wọ́n ti yè bọ́ kúrò nínú àwọn ẹ̀gbin ayé+ nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye nípa Jésù Kristi Olúwa àti Olùgbàlà, wọ́n tún kó wọnú nǹkan wọ̀nyí gan-an, tí a si ṣẹ́pá wọn,+ àwọn ipò ìgbẹ̀yìn ti burú fún wọn ju ti àkọ́kọ́.+ 21  Nítorí ì bá sàn kí wọn má mọ ipa ọ̀nà òdodo lọ́nà pípéye ju+ pé lẹ́yìn tí wọ́n ti mọ̀ ọ́n lọ́nà pípéye kí wọ́n yí padà kúrò nínú àṣẹ mímọ́ tí a fi lé wọn lọ́wọ́.+ 22  Òwe tòótọ́ náà ti a máa ń pa ti ṣẹ sí wọn lára: “Ajá+ ti padà sínú èébì ara rẹ̀, àti abo ẹlẹ́dẹ̀ tí a ti wẹ̀ sínú yíyígbiri nínú ẹrẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé