Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Pétérù 1:1-21

1  Símónì Pétérù, ẹrú+ àti àpọ́sítélì+ Jésù Kristi, sí àwọn tí ó ti gba ìgbàgbọ́, tí a dì mú nínú àǹfààní dídọ́gba pẹ̀lú tiwa,+ nípa òdodo+ Ọlọ́run wa àti Jésù Kristi Olùgbàlà:+  Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà pọ̀ sí i fún yín+ nípasẹ̀ ìmọ̀+ pípéye nípa Ọlọ́run àti nípa Jésù Olúwa wa,  níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé lọ́fẹ́ẹ́ ni agbára àtọ̀runwá rẹ̀ fún wa ní gbogbo ohun tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìyè+ àti fífọkànsin Ọlọ́run,+ nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye nípa ẹni tí ó pè+ wá nípasẹ̀ ògo+ àti ìwà funfun.  Nípasẹ̀ nǹkan wọ̀nyí, lọ́fẹ̀ẹ́ ni ó ti fún wa ní àwọn ìlérí ṣíṣeyebíye àti títóbi lọ́lá gan-an,+ kí ẹ lè tipasẹ̀ ìwọ̀nyí di alájọpín ìwà ẹ̀dá+ ti ọ̀run,+ bí ẹ ti yè bọ́ kúrò nínú ìdíbàjẹ́ tí ó wà nínú ayé+ nípasẹ̀ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.  Bẹ́ẹ̀ ni, fún ìdí yìí gan-an, nípa fífi gbogbo ìsapá+ àfi-taratara-ṣe ṣètìlẹyìn ní ìdáhùnpadà, ẹ pèsè ìwà funfun+ kún ìgbàgbọ́ yín, ìmọ̀ kún ìwà funfun yín,+  ìkóra-ẹni-níjàánu kún ìmọ̀ yín, ìfaradà kún ìkóra-ẹni-níjàánu yín,+ ìfọkànsin Ọlọ́run+ kún ìfaradà yín,  ìfẹ́ni ará kún ìfọkànsin Ọlọ́run yín, ìfẹ́ kún ìfẹ́ni ará yín.+  Nítorí bí nǹkan wọ̀nyí bá wà nínú yín, tí wọ́n sì kún àkúnwọ́sílẹ̀, wọn kì yóò jẹ́ kí ẹ di aláìṣiṣẹ́ tàbí aláìléso+ ní ti ìmọ̀ pípéye nípa Olúwa wa Jésù Kristi.  Nítorí bí nǹkan wọ̀nyí kò bá sí nínú ẹnikẹ́ni, ó fọ́jú, ó di ojú rẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀,+ ó sì ti di ẹni tí ó gbàgbé+ ìwẹ̀nùmọ́+ rẹ̀ kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn. 10  Fún ìdí yìí, ẹ̀yin ará, ẹ túbọ̀ máa sa gbogbo ipá yín láti mú pípè+ àti yíyàn+ yín dájú fún ara yín; nítorí bí ẹ bá ń bá a nìṣó ní ṣíṣe nǹkan wọ̀nyí, ẹ kì yóò kùnà lọ́nàkọnà láé.+ 11  Ní ti tòótọ́, nípa báyìí ni a ó pèsè fún yín lọ́pọ̀ jaburata ìwọlé+ sínú ìjọba àìnípẹ̀kun+ ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi.+ 12  Fún ìdí yìí, èmi yóò múra tán nígbà gbogbo láti rán yín létí+ nǹkan wọ̀nyí, bí ẹ tilẹ̀ mọ̀ wọ́n, tí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nínú òtítọ́+ tí ó wà nínú yín.+ 13  Ṣùgbọ́n mo kà á sí pé ó tọ̀nà, níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà nínú àgọ́+ yìí, láti ta yín jí gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti rán yín létí,+ 14  bí mo ti mọ̀ ní tòótọ́ pé bíbọ́ àgọ́ mi kúrò yóò wáyé láìpẹ́,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Olúwa wa Jésù Kristi pẹ̀lú ti fi àmì tọ́ka sí i fún mi.+ 15  Nítorí náà, ṣe ni èmi yóò sa gbogbo ipá mi pẹ̀lú ní gbogbo ìgbà pé, lẹ́yìn lílọ mi,+ kí ẹ lè fúnra yín mẹ́nu kan nǹkan wọ̀nyí. 16  Bẹ́ẹ̀ kọ́, kì í ṣe nípa títẹ̀lé àwọn ìtàn èké àdọ́gbọ́nhùmọ̀ lọ́nà àrékendá+ ni àwa fi sọ yín di ojúlùmọ̀ agbára àti wíwàníhìn-ín Olúwa wa Jésù Kristi,+ ṣùgbọ́n ó jẹ́ nípa fífi tí a fi ojú rí ọlá ńlá rẹ̀.+ 17  Nítorí ó gba ọlá àti ògo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba,+ nígbà tí ògo ọlọ́lá ńlá gbé irú ọ̀rọ̀ báwọ̀nyí wá fún un pé: “Èyí ni ọmọ mi, olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹni tí èmi tìkára mi tẹ́wọ́ gbà.”+ 18  Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni a gbọ́+ tí a gbé wá láti ọ̀run nígbà tí a wà pẹ̀lú rẹ̀ ní òkè ńlá mímọ́ náà.+ 19  Nítorí náà, a ní ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀+ tí a túbọ̀ mú dáni lójú;+ ẹ sì ń ṣe dáadáa ní fífún un ní àfiyèsí gẹ́gẹ́ bí fún fìtílà+ tí ń tàn ní ibi tí ó ṣókùnkùn, títí tí ojúmọ́ yóò fi mọ́, tí ìràwọ̀ ojúmọ́+ yóò sì yọ, nínú ọkàn-àyà yín. 20  Nítorí ẹ mọ èyí lákọ̀ọ́kọ́ pé, kò sí àsọtẹ́lẹ̀ kankan nínú Ìwé Mímọ́ tí ó jáde wá láti inú ìtúmọ̀ ti ara ẹni èyíkéyìí.+ 21  Nítorí a kò fi ìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípa ìfẹ́ ènìyàn,+ ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run+ bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé