Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Kọ́ríńtì 9:1-15

9  Wàyí o, ní ti iṣẹ́ òjíṣẹ́+ tí ó wà fún àwọn ẹni mímọ́, àṣerégèé ni ó jẹ́ fún mi láti kọ̀wé sí yín,  nítorí mo mọ ìmúratán èrò inú yín, èyí tí mo fi ń ṣògo nípa yín fún àwọn ará Makedóníà, pé Ákáyà ti múra tán fún ọdún kan nísinsìnyí,+ ìtara yín sì ti ru ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn sókè.  Ṣùgbọ́n mo ń rán àwọn arákùnrin náà, kí ìṣògo wa nípa yín má bàa já sí òfìfo nínú ọ̀ràn yìí, ṣùgbọ́n kí ẹ lè múra tán ní ti gidi,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti máa ń sọ pé ẹ ó ṣe.  Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, lọ́nà kan ṣáá, bí àwọn ará Makedóníà bá bá mi wá, tí wọ́n sì bá yín ní àìmúrasílẹ̀, a óò kó ìtìjú bá àwa—kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé ẹ̀yin—nínú ìdánilójú wa yìí.  Nítorí náà, mo ronú pé ó pọndandan láti fún àwọn arákùnrin náà ní ìṣírí láti wá sọ́dọ̀ yín ṣaájú àti láti múra ẹ̀bùn yanturu yín sílẹ̀, tí ẹ ti ṣèlérí tẹ́lẹ̀,+ nípa báyìí kí èyí lè wà nílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn yanturu, kì í sì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí a fi agbára gbà.+  Ṣùgbọ́n ní ti èyí, ẹni tí ó bá ń fúnrúgbìn kín-ún+ yóò ká kín-ún pẹ̀lú; ẹni tí ó bá sì ń fúnrúgbìn yanturu+ yóò ká yanturu pẹ̀lú.  Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀+ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.+  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ọlọ́run lè mú kí gbogbo inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ pọ̀ gidigidi fún yín, pé, bí ẹ ti ń fi ìgbà gbogbo ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ànító nínú ohun gbogbo, kí ẹ lè ní púpọ̀ rẹpẹtẹ fún iṣẹ́ rere gbogbo.+  (Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Ó ti pín nǹkan fúnni lọ́nà gbígbòòrò, ó ti fún àwọn òtòṣì, òdodo rẹ̀ ń bá a lọ títí láé.”+ 10  Wàyí o, ẹni tí ń pèsè irúgbìn lọ́pọ̀ yanturu fún afúnrúgbìn àti oúnjẹ fún jíjẹ+ yóò pèsè irúgbìn, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀ sí i fún yín láti gbìn, yóò sì mú èso òdodo+ yín pọ̀ sí i.) 11  Nínú ohun gbogbo, a ń sọ yín di ọlọ́rọ̀ fún gbogbo onírúurú ìwà ọ̀làwọ́, èyí tí ń mú ìfọpẹ́hàn wá fún Ọlọ́run+ nípasẹ̀ wa; 12  nítorí iṣẹ́ òjíṣẹ́ iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn yìí kì í ṣe kìkì láti pèsè fún àìní àwọn ẹni mímọ́+ lọ́pọ̀ yanturu ṣùgbọ́n láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ọ̀pọ̀ ìfọpẹ́hàn fún Ọlọ́run pẹ̀lú. 13  Nípasẹ̀ ẹ̀rí tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí ń fúnni, wọ́n ń yin Ọlọ́run lógo nítorí tí ẹ ní ẹ̀mí ìtẹríba fún ìhìn rere nípa Kristi,+ gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń polongo ní gbangba pé ẹ jẹ́, àti nítorí pé ẹ jẹ́ ọ̀làwọ́ nínú ọrẹ yín fún wọn àti fún gbogbo ènìyàn;+ 14  àti pẹ̀lú ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ fún yín, aáyun yín ń yun wọn nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ Ọlọ́run títayọ ré kọjá tí ó wà lórí yín. 15  Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run fún ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ rẹ̀ aláìṣeé-ṣàpèjúwe.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé