Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kọ́ríńtì 8:1-24

8  Wàyí o, ẹ̀yin ará, àwa jẹ́ kí ẹ mọ̀ nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run èyí tí a ti fi jíǹkí àwọn ìjọ Makedóníà,+  pé nígbà ìdánwò ńlá lábẹ́ ìṣẹ́níṣẹ̀ẹ́, ọ̀pọ̀ yanturu ìdùnnú wọn àti ipò òṣì paraku wọn mú kí ọrọ̀ ìwà ọ̀làwọ́ wọn pọ̀ gidigidi.+  Nítorí ní ìbámu pẹ̀lú agbára+ wọn gan-an, bẹ́ẹ̀ ni, mo jẹ́rìí pé, èyí ré kọjá agbára wọn gan-an,  nígbà tí àwọn, láti inú ìdánúṣe àwọn fúnra wọn, ń bẹ̀ wá ṣáá pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìpàrọwà fún àǹfààní ìfúnni onínúrere àti fún ìpín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a ti yán tẹ́lẹ̀ fún àwọn ẹni mímọ́.+  Kì í sì í ṣe kìkì bí àwa ti retí, ṣùgbọ́n lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n fi ara wọn fún Olúwa+ àti fún àwa nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run.  Èyí sún wa láti fún Títù ní ìṣírí+ pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé òun ni ẹni tí ó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ láàárín yín, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni kí ó parí ìfúnni onínúrere yìí tí ó ti ọ̀dọ̀ yín wá.  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti pọ̀ gidigidi nínú ohun gbogbo,+ nínú ìgbàgbọ́ àti ọ̀rọ̀ àti ìmọ̀+ àti gbogbo ẹ̀mí ìfitaratara-ṣe-nǹkan àti nínú ìfẹ́ wa yìí fún yín, kí ẹ pọ̀ gidigidi nínú ìfúnni onínúrere yìí pẹ̀lú.  Kì í ṣe lọ́nà pípàṣẹ fún yín,+ bí kò ṣe nítorí ẹ̀mí ìfitaratara-ṣe-nǹkan tí àwọn ẹlòmíràn ní àti láti dán jíjẹ́ ojúlówó ìfẹ́ yín wò, ni èmi fi ń sọ̀rọ̀.  Nítorí ẹ mọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa wa, pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun jẹ́ ọlọ́rọ̀, ó di òtòṣì nítorí yín,+ kí ẹ lè di ọlọ́rọ̀+ nípasẹ̀ ipò òṣì rẹ̀. 10  Àti pé nínú èyí mo sọ èrò kan:+ nítorí ọ̀ràn yìí ṣàǹfààní fún yín,+ níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé láti ọdún kan sẹ́yìn ni ẹ ti bẹ̀rẹ̀, kì í ṣe ṣíṣe nìkan ṣùgbọ́n fífẹ́ láti ṣe pẹ̀lú;+ 11  nígbà náà, ẹ parí ṣíṣe rẹ̀ pẹ̀lú nísinsìnyí, kí ó lè jẹ́ pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìmúratán láti fẹ́ ṣe ti wà, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ó yẹ kí àṣeparí rẹ̀ wà láti inú ohun tí ẹ ní. 12  Nítorí bí ìmúratán bá kọ́kọ́ wà, ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà ní pàtàkì ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn ní,+ kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn kò ní. 13  Nítorí èmi kò ní i lọ́kàn pé kí ó dẹrùn fún àwọn ẹlòmíràn,+ ṣùgbọ́n kí ó nira fún yín; 14  ṣùgbọ́n pé nípasẹ̀ ìmúdọ́gba, kí àṣẹ́kùsílẹ̀ yín nísinsìnyí gan-an lè dí àìnító wọn, kí àṣẹ́kùsílẹ̀ wọn lè wá dí àìnító yín pẹ̀lú, kí ìmúdọ́gba lè ṣẹlẹ̀.+ 15  Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Ẹni tí ó ní púpọ̀ kò ní púpọ̀ jù, ẹni tí ó sì ní díẹ̀ kò ní kíkéré jù.”+ 16  Wàyí o, ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run fún fífi ẹ̀mí ìfitaratara-ṣe-nǹkan kan náà tí a ní fún yín sínú ọkàn-àyà Títù,+ 17  nítorí ó ti dáhùn padà sí ìṣírí náà ní tòótọ́, ṣùgbọ́n, bí ó ti ní ẹ̀mí ìfitaratara-ṣe-nǹkan, ó ń jáde lọ sọ́dọ̀ yín láti inú ìdánúṣe ara rẹ̀. 18  Ṣùgbọ́n àwa ń rán arákùnrin náà pẹ̀lú rẹ̀, ẹni tí ìyìn rẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìhìn rere ti tàn kálẹ̀ dé gbogbo ìjọ. 19  Kì í ṣe èyíinì nìkan, ṣùgbọ́n àwọn ìjọ yàn án+ pẹ̀lú pé kí ó jẹ́ alájọrin ìrìn àjò wa ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀bùn inú rere yìí tí a fẹ́ pín fúnni fún ògo+ Olúwa àti láti fúnni ní ẹ̀rí ìdánilójú ìmúratán èrò inú wa.+ 20  Nípa báyìí, a ń yẹra fún jíjẹ́ kí ẹnikẹ́ni rí àléébù+ kà sí wa lọ́rùn ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ọrẹ aláìṣahun+ tí a óò pín fúnni. 21  Nítorí àwa “ń ṣe ìpèsè aláìlábòsí, kì í ṣe níwájú Jèhófà nìkan, ṣùgbọ́n níwájú àwọn ènìyàn pẹ̀lú.”+ 22  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwa ń rán arákùnrin wa pẹ̀lú wọn, ẹni tí àwa ti fún ní ẹ̀rí ìdánilójú ní ọ̀pọ̀ ìgbà nínú ohun púpọ̀ pé ó jẹ́ olùfitaratara-ṣe-nǹkan, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ó túbọ̀ jẹ́ olùfitaratara ṣe nǹkan jù bẹ́ẹ̀ lọ nítorí ìgbọ́kànlé ńláǹlà tí ó ní nínú yín. 23  Ṣùgbọ́n bí ìbéèrè èyíkéyìí bá wà nípa Títù, ó jẹ́ alájọpín pẹ̀lú mi àti alábàáṣiṣẹ́pọ̀+ fún ire yín; tàbí bí ó bá jẹ́ nípa àwọn arákùnrin wa, wọn jẹ́ àpọ́sítélì àwọn ìjọ àti ògo Kristi. 24  Nítorí náà, ẹ fi ẹ̀rí ìfẹ́ yín+ àti ohun tí àwa fi ṣògo+ nípa yín hàn gbangba fún wọn, ní ojú àwọn ìjọ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé