Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Kọ́ríńtì 7:1-16

7  Nítorí náà, níwọ̀n bí a ti ní ìlérí wọ̀nyí,+ ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́+ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí,+ kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.+  Ẹ fi àyè gbà wá.+ Àwa kò ṣe àìtọ́ sí ẹnì kankan, a kò sọ ẹnì kankan di ìbàjẹ́, a kò yan ẹnì kankan jẹ.+  Èmi kò sọ èyí láti dá yín lẹ́bi. Nítorí mo ti wí tẹ́lẹ̀ pé ẹ wà nínú ọkàn-àyà wa láti kú àti láti wà láàyè pẹ̀lú wa.+  Mo ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ńláǹlà sí yín. Mo ní ìṣògo ńláǹlà nípa yín.+ Mo kún fún ìtùnú,+ ìdùnnú mi kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú gbogbo ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ wa níṣẹ̀ẹ́.+  Ní ti tòótọ́, nígbà tí a dé Makedóníà,+ ẹran ara wa kò ní ìtura kankan,+ ṣùgbọ́n a ń bá a lọ lábẹ́ ìṣẹ́níṣẹ̀ẹ́+ lọ́nà gbogbo—ìjà wà lóde, ìbẹ̀rù wà nínú.  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run, ẹni tí ń tu+ àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ nínú, tù wá nínú nípa wíwàníhìn-ín Títù;  síbẹ̀, kì í ṣe nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n nípa ìtùnú tí a ti fi tù ú nínú nítorí yín pẹ̀lú, bí ó ti tún mú ọ̀rọ̀+ wá fún wa nípa ìyánhànhàn yín, ìkẹ́dùn yín, ìtara yín fún mi; tó bẹ́ẹ̀ tí mo túbọ̀ yọ̀.  Nítorí bẹ́ẹ̀, bí mo tilẹ̀ bà yín nínú jẹ́ nípasẹ̀ lẹ́tà mi,+ èmi kò kábàámọ̀ rẹ̀. Bí mo bá tilẹ̀ kábàámọ̀ rẹ̀ ní àkọ́kọ́, (mo rí i pé lẹ́tà yẹn bà yín nínú jẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀,)  nísinsìnyí, mo ń yọ̀, kì í ṣe nítorí pé a wulẹ̀ bà yín nínú jẹ́, bí kò ṣe nítorí pé a bà yín nínú jẹ́ sí ríronúpìwàdà;+ nítorí a bà yín nínú jẹ́ ní ọ̀nà ti Ọlọ́run,+ kí ẹ má bàa fara pa rárá nínú ohunkóhun nítorí wa. 10  Nítorí ìbànújẹ́ ní ọ̀nà ti Ọlọ́run ń yọrí sí ìrònúpìwàdà sí ìgbàlà tí a kì yóò kábàámọ̀;+ ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ti ayé ń mú ikú wá.+ 11  Nítorí pé, wò ó! ohun yìí gan-an, bíbà yín nínú jẹ́ ní ọ̀nà ti Ọlọ́run,+ ẹ wo irú ẹ̀mí ìfitaratara-ṣe-nǹkan tí ó mú jáde nínú yín, bẹ́ẹ̀ ni, wíwẹ ara yín mọ́, bẹ́ẹ̀ ni, ìkannú, bẹ́ẹ̀ ni, ìbẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ ni, ìyánhànhàn, bẹ́ẹ̀ ni, ìtara, bẹ́ẹ̀ ni, ṣíṣe àtúnṣe àìtọ́ náà!+ Ní gbogbo ọ̀nà, ẹ fi ara yín hàn gbangba ní oníwàmímọ́ nínú ọ̀ràn yìí. 12  Dájúdájú, bí mo tilẹ̀ kọ̀wé sí yín, èmi kò kọ ọ́ nítorí ẹni tí ó ṣe àìtọ́,+ tàbí nítorí ẹni tí a ṣe àìtọ́ sí, bí kò ṣe nítorí kí ẹ̀mí ìfitaratara-ṣe-nǹkan tí ẹ ní fún wa lè fara hàn kedere láàárín yín níwájú Ọlọ́run. 13  Ìdí nìyẹn tí a fi tù wá nínú. Bí ó ti wù kí ó rí, ní àfikún sí ìtùnú wa, àwa túbọ̀ ń yọ̀ púpọ̀púpọ̀ sí i nítorí ìdùnnú Títù, nítorí gbogbo yín ti tu ẹ̀mí rẹ̀+ lára. 14  Nítorí bí mo bá ti fi yín ṣògo èyíkéyìí níwájú rẹ̀, a kò kó ìtìjú bá mi; ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí a tí sọ ohun gbogbo fún yín ní òtítọ́, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìṣògo+ wa níwájú Títù ti já sí tòótọ́. 15  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀ túbọ̀ pọ̀ yanturu sí yín, bí ó ti rántí gbogbo ìgbọràn+ yín, bí ẹ ṣe gbà á pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì. 16  Mo yọ̀ pé ní gbogbo ọ̀nà mo lè ní ìgboyà gidi gan-an nítorí yín.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé