Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Kọ́ríńtì 6:1-18

6  Ní bíbá a ṣiṣẹ́ pọ̀,+ àwa ń pàrọwà fún yín pẹ̀lú pé kí ẹ má ṣe tẹ́wọ́ gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run kí ẹ sì tàsé ète rẹ̀.+  Nítorí ó wí pé: “Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, mo gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, mo ràn ọ́ lọ́wọ́.”+ Wò ó! Ìsinsìnyí gan-an ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà.+ Wò ó! Ìsinsìnyí ni ọjọ́ ìgbàlà.+  Kò sí ọ̀nà kankan tí àwa gbà jẹ́ okùnfà èyíkéyìí fún ìkọ̀sẹ̀,+ kí a má bàa rí àléébù sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa;+  ṣùgbọ́n lọ́nà gbogbo, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà+ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run, nípa ìfaradà púpọ̀, nípa àwọn ìpọ́njú, nípa àwọn ọ̀ràn àìní, nípa àwọn ìṣòro,+  nípa lílù, nípa ẹ̀wọ̀n,+ nípa rúgúdù, nípa òpò, nípa àwọn òru àìlèsùn, nípa àwọn àkókò àìsí oúnjẹ,+  nípa ìmọ́gaara, nípa ìmọ̀, nípa ìpamọ́ra,+ nípa inú rere,+ nípa ẹ̀mí mímọ́, nípa ìfẹ́ tí kò ní àgàbàgebè,+  nípa ọ̀rọ̀ òtítọ́, nípa agbára Ọlọ́run;+ nípasẹ̀ àwọn ohun ìjà+ òdodo ní ọwọ́ ọ̀tún àti ní òsì,  nípasẹ̀ ògo àti àbùkù, nípasẹ̀ ìròyìn búburú àti ìròyìn rere; gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹlẹ́tàn,+ síbẹ̀ a jẹ́ olùsọ òtítọ́,  bí ẹni tí a kò mọ̀, síbẹ̀ a mọ̀ wá dájú,+ bí ẹni tí ń kú lọ, sì wò ó! síbẹ̀ a wà láàyè,+ bí ẹni tí a bá wí,+ síbẹ̀ a kò fà wá lé ikú lọ́wọ́,+ 10  bí ẹni tí ó kárí sọ ṣùgbọ́n tí ń yọ̀ nígbà gbogbo, bí òtòṣì ṣùgbọ́n tí ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di ọlọ́rọ̀, bí ẹni tí kò ní nǹkan kan, síbẹ̀ a ní ohun gbogbo.+ 11  A ti la ẹnu wa sí yín, ẹ̀yin ará Kọ́ríńtì, ọkàn-àyà wa+ ti gbòòrò síwájú. 12  Àyè kò há fún yín ní inú wa,+ ṣùgbọ́n àyè há fún yín ní inú ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́+ ti ẹ̀yin fúnra yín. 13  Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí èrè iṣẹ́ ní ìdápadà—mo ń sọ̀rọ̀ bí ẹní ń bá àwọn ọmọ+ sọ̀rọ̀—ẹ̀yin, pẹ̀lú, ẹ gbòòrò síwájú. 14  Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.+ Nítorí àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà àìlófin ní?+ Tàbí àjọpín wo ni ìmọ́lẹ̀ ní pẹ̀lú òkùnkùn?+ 15  Síwájú sí i, ìbáramu wo ni ó wà láàárín Kristi àti Bélíálì?+ Tàbí ìpín+ wo ni olùṣòtítọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́? 16  Ìfohùnṣọ̀kan wo sì ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní pẹ̀lú àwọn òrìṣà?+ Nítorí àwa jẹ́ tẹ́ńpìlì+ Ọlọ́run alààyè; gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí pé: “Èmi yóò máa gbé láàárín wọn,+ èmi yóò sì máa rìn láàárín wọn, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.”+ 17  “‘Nítorí náà, ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘kí ẹ sì jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́’”;+ “‘dájúdájú, èmi yóò sì gbà yín wọlé.’”+ 18  “‘Èmi yóò sì jẹ́ baba yín,+ ẹ ó sì jẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mi,’+ ni Jèhófà Olódùmarè wí.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé