Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kọ́ríńtì 5:1-21

5  Nítorí àwa mọ̀ pé bí ilé wa ti ilẹ̀ ayé,+ àgọ́ yìí,+ bá di títúpalẹ̀,+ àwa yóò ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́,+ ti àìnípẹ̀kun+ ní ọ̀run.+  Nítorí nínú ilé gbígbé yìí, àwa ń kérora+ ní tòótọ́, a ń fi taratara ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé èyí tí ó wà fún wa láti ọ̀run wọ̀,  kí ó lè jẹ́ pé, lẹ́yìn gbígbé e wọ̀ ní ti gidi, a kò ní rí wa ní ìhòòhò.+  Ní ti tòótọ́, àwa tí a wà nínú àgọ́ yìí ń kérora, níwọ̀n bí a ti dẹrù pa wá; nítorí pé àwa kò fẹ́ láti bọ́ ọ kúrò, bí kò ṣe láti gbé èkejì wọ̀,+ kí ìyè lè gbé èyí tí ó jẹ́ kíkú mì.+  Wàyí o, ẹni tí ó mú wa jáde fún ohun yìí gan-an ni Ọlọ́run,+ ẹni tí ó fún wa ní àmì ìdánilójú+ ohun tí ń bọ̀, èyíinì ni, ẹ̀mí+ náà.  Nítorí náà, àwa jẹ́ onígboyà gidi gan-an nígbà gbogbo, a sì mọ̀ pé, nígbà tí ilé wa ń bẹ nínú ara, a kò sí lọ́dọ̀ Olúwa,+  nítorí nípa ìgbàgbọ́ ni àwa ń rìn, kì í ṣe nípa ohun tí a rí.+  Ṣùgbọ́n àwa jẹ́ onígboyà gidi gan-an, ó sì dùn mọ́ wa nínú jọjọ láti kúkú má ṣe wà nínú ara, kí a sì fi ọ̀dọ̀ Olúwa ṣe ilé wa.+  Nítorí náà, a ń fi í ṣe ìfojúsùn wa pẹ̀lú pé, yálà ilé wa ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ tàbí kí ó má sí lọ́dọ̀ rẹ̀,+ kí a lè ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.+ 10  Nítorí a gbọ́dọ̀ fi gbogbo wa hàn kedere níwájú ìjókòó ìdájọ́ Kristi,+ kí olúkúlùkù lè gba ìpín èrè tirẹ̀ fún àwọn ohun tí ó ti ṣe nínú ara, gẹ́gẹ́ bí àwọn ohun tí ó ti fi ṣe ìwà hù, yálà ó jẹ́ rere tàbí búburú.+ 11  Nítorí náà, ní mímọ ìbẹ̀rù+ Olúwa, àwa ń yí àwọn ènìyàn lérò padà,+ ṣùgbọ́n a ti fi wá hàn kedere fún Ọlọ́run. Bí ó ti wù kí ó rí, mo ní ìrètí pé a ti fi wá hàn kedere pẹ̀lú fún ẹ̀rí-ọkàn yín.+ 12  Àwa kò tún máa dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà+ yín mọ́, ṣùgbọ́n a ń fún yín ní ìsúnniṣe fún ìṣògo nípa wa,+ kí ẹ lè ní ìdáhùn fún àwọn tí ń ṣògo lórí ìrísí òde+ ṣùgbọ́n tí kì í ṣe lórí ọkàn-àyà.+ 13  Nítorí bí orí wa bá yí,+ fún Ọlọ́run ni; bí orí wa bá pé,+ fún yín ni. 14  Nítorí ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa, nítorí èyí ni ohun tí àwa ti ṣèdájọ́, pé ọkùnrin kan kú fún gbogbo ènìyàn;+ nítorí bẹ́ẹ̀, gbogbo wọ́n ti kú; 15  ó sì kú fún gbogbo wọn kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́,+ bí kò ṣe fún ẹni+ tí ó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde.+ 16  Nítorí náà, láti ìsinsìnyí lọ, a kò mọ ènìyàn kankan nípa ti ẹran ara.+ Bí a tilẹ̀ ti mọ Kristi nípa ti ẹran ara,+ dájúdájú, a kò mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀ mọ́ nísinsìnyí.+ 17  Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, ìṣẹ̀dá tuntun+ ni ó jẹ́; àwọn ohun ògbólógbòó ti kọjá lọ,+ wò ó! àwọn ohun tuntun ti wá wà.+ 18  Ṣùgbọ́n ohun gbogbo wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni ti ó tipasẹ̀ Kristi mú wa padà bá ara rẹ̀ rẹ́,+ tí ó sì fún wa ní iṣẹ́ òjíṣẹ́+ ìpadàrẹ́, 19  èyíinì ni, pé Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi+ ń mú ayé+ kan padà bá ara rẹ̀+ rẹ́, láìṣírò àwọn àṣemáṣe+ wọn sí wọn lọ́rùn, ó sì fi ọ̀rọ̀+ ìpadàrẹ́ náà lé wa+ lọ́wọ́. 20  Nítorí náà, àwa+ jẹ́ ikọ̀+ tí ń dípò fún Kristi,+ bí ẹni pé Ọlọ́run ń pàrọwà nípasẹ̀ wa.+ Gẹ́gẹ́ bí àwọn adípò fún Kristi, àwa bẹ̀bẹ̀ pé:+ “Ẹ padà bá Ọlọ́run rẹ́.” 21  Ẹni náà tí kò mọ ẹ̀ṣẹ̀+ ni òun sọ di ẹ̀ṣẹ̀+ fún wa, kí àwa lè di òdodo Ọlọ́run+ nípasẹ̀ rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé