Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Kọ́ríńtì 3:1-18

3  Ṣé kí a tún ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà ni?+ Tàbí ó ha lè jẹ́ pé, àwa, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan, nílò àwọn lẹ́tà+ ìdámọ̀ràn fún ìtẹ́wọ́gbà sọ́dọ̀ yín tàbí láti ọ̀dọ̀ yín?  Ẹ̀yin tìkára yín ni lẹ́tà wa,+ tí a kọ sára ọkàn-àyà wa, tí gbogbo aráyé sì mọ̀, tí wọ́n sì ń kà.+  Nítorí a fi yín hàn pé ẹ jẹ́ lẹ́tà Kristi tí àwa gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ kọ,+ tí a kò fi yíǹkì kọ àkọọ́lẹ̀ rẹ̀ bí kò ṣe ẹ̀mí+ Ọlọ́run alààyè, kì í ṣe sára àwọn wàláà òkúta,+ bí kò ṣe sára àwọn wàláà ti ẹran ara, sára àwọn ọkàn-àyà.+  Wàyí o, nípasẹ̀ Kristi, àwa ní irú ìgbọ́kànlé+ yìí sí Ọlọ́run.  Kì í ṣe pé àwa fúnra wa tóótun tẹ́rùntẹ́rùn láti ṣírò ohunkóhun gẹ́gẹ́ bí èyí tí ń ti ọ̀dọ̀ àwa fúnra wa jáde wá,+ ṣùgbọ́n títóótun wa tẹ́rùntẹ́rùn ń jáde wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+  ẹni tí ó ti mú wa tóótun tẹ́rùntẹ́rùn ní tòótọ́ láti jẹ́ òjíṣẹ́ májẹ̀mú tuntun kan,+ kì í ṣe ti àkójọ òfin tí a kọ sílẹ̀,+ bí kò ṣe ti ẹ̀mí;+ nítorí àkójọ òfin tí a kọ sílẹ̀ ń dáni lẹ́bi+ ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ń sọni di ààyè.+  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí àkójọ òfin tí ń pín ikú fúnni,+ tí a sì fi àwọn lẹ́tà fín sára àwọn òkúta+ bá wá láti inú ògo,+ tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò lè fi tọkàntara tẹjú mọ́ ojú Mósè nítorí ògo ojú rẹ̀,+ ògo tí a óò mú wá sí òpin,  èé ṣe tí ìpínfúnni ẹ̀mí+ kì yóò fi ní ògo púpọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ?+  Nítorí bí àkójọ òfin tí ń pín ìdálẹ́bi+ fúnni bá jẹ́ ológo,+ ìpínfúnni òdodo+ pọ̀ gidigidi fún ògo+ jù bẹ́ẹ̀ lọ. 10  Ní ti tòótọ́, èyí tí a ṣe lógo nígbà kan rí pàápàá ni a ti bọ́ ògo kúrò lára rẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí,+ nítorí ògo tí ó ta á yọ.+ 11  Nítorí bí a bá mú èyí tí a óò mú wá sópin wọlé pẹ̀lú ògo,+ èyíinì tí ń wà nìṣó yóò ní ògo púpọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ.+ 12  Nítorí náà, bí a ti ní irú ìrètí bẹ́ẹ̀,+ àwa ń lo òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ńláǹlà, 13  a kì í sì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí Mósè a fi ìbòjú+ bo ojú rẹ̀, kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì má bàa fi tọkàntara tẹjú mọ́ òpin+ èyíinì tí a óò mú wá sópin. 14  Ṣùgbọ́n a mú agbára èrò orí wọn pòkúdu.+ Nítorí títí di òní olónìí, ìbòjú kan náà ṣì wà láìká kúrò nígbà tí a bá ń ka májẹ̀mú láéláé,+ nítorí a mú un wá sí òpin nípasẹ̀ Kristi.+ 15  Ní ti tòótọ́, títí di òní, nígbàkigbà tí wọ́n bá ń ka òfin Mósè,+ ìbòjú a bo ọkàn-àyà wọn.+ 16  Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá yíjú sí Jèhófà, ìbòjú náà a ká kúrò.+ 17  Wàyí o, Jèhófà ni Ẹ̀mí náà;+ níbi tí ẹ̀mí+ Jèhófà+ bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira wà.+ 18  Nígbà tí a ń fi ojú tí a kò fi ìbòjú bò ṣe àgbéyọ ògo Jèhófà+ bí i dígí, gbogbo wa+ ni a sì ń pa lára dà+ sí àwòrán+ kan náà láti ògo dé ògo,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà+ Ẹ̀mí náà ti ṣe.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé