Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Kọ́ríńtì 2:1-17

2  Nítorí èyí ni ohun tí mo ti pinnu fún ara mi, láti má ṣe tún tọ̀ yín wá nínú ìbànújẹ́.+  Nítorí bí mo bá bà yín nínú jẹ́,+ ta ni ó wà níbẹ̀ láti mú orí mi yá gágá ní tòótọ́ bí kò ṣe ẹni tí mo bà nínú jẹ́?  Nítorí náà sì ni mo ṣe kọ̀wé ohun yìí gan-an, pé, nígbà tí mo bá dé, kí n má bàa banú jẹ́+ nítorí àwọn tí ó yẹ kí n tìtorí wọn yọ̀;+ nítorí mo ní ìgbọ́kànlé+ nínú gbogbo yín pé ìdùnnú tí mo ní jẹ́ ti gbogbo yín.  Nítorí nínú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú àti làásìgbò ọkàn-àyà ni mo kọ̀wé sí yín pẹ̀lú ọ̀pọ̀ omijé,+ kì í ṣe pé kí a lè bà yín nínú jẹ́,+ bí kò ṣe kí ẹ lè mọ ìfẹ́ tí mo ní pàápàá jù lọ fún yín.  Wàyí o, bí ẹnikẹ́ni bá ti fa ìbànújẹ́,+ kì í ṣe èmi ni ó ti bà nínú jẹ́, bí kò ṣe gbogbo yín dé àyè kan—láti má ṣe le koko jù nínú ohun tí mo ń sọ.  Ìbáwí mímúná+ yìí tí ọ̀pọ̀ jù lọ fi fún un ti tó fún irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀,  tí ó fi jẹ́ pé, dípò èyí nísinsìnyí, kí ẹ fi inú rere dárí jì í,+ kí ẹ sì tù ú nínú, pé lọ́nà kan ṣáá, kí ìbànújẹ́ rẹ̀ tí ó pàpọ̀jù+ má bàa gbé irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ mì.  Nítorí náà, mo gbà yín níyànjú pé kí ẹ fìdí òtítọ́ ìfẹ́+ yín fún un múlẹ̀.  Nítorí fún ète yìí pẹ̀lú ni mo ṣe kọ̀wé láti wádìí ẹ̀rí yín dájú, bóyá ẹ jẹ́ onígbọràn nínú ohun gbogbo.+ 10  Ohunkóhun tí ẹ bá fi inú rere dárí ji ẹnikẹ́ni, èmi náà ṣe bẹ́ẹ̀.+ Ní ti tòótọ́, ní tèmi, ohun yòówù tí mo bá ti fi inú rere dárí rẹ̀ jini, bí mo bá tí fi inú rere dárí ohunkóhun jini, ó jẹ́ nítorí yín níwájú Kristi; 11  kí Sátánì+ má bàa fi ọgbọ́n àyínìke borí wa, nítorí àwa kò ṣe aláìmọ àwọn ète-ọkàn rẹ̀.+ 12  Wàyí o, nígbà tí mo dé Tíróásì+ láti polongo ìhìn rere nípa Kristi, tí a sì ṣí ìlẹ̀kùn kan fún mi nínú Olúwa,+ 13  èmi kò ní ìtura nínú ẹ̀mí mi ní tìtorí pé èmi kò rí Títù+ arákùnrin mi, ṣùgbọ́n mo wí pé ó dìgbòóṣe fún wọn, mo sì kúrò lọ sí Makedóníà.+ 14  Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, ẹni tí ń ṣamọ̀nà+ wa nígbà gbogbo nínú ìtọ́wọ̀ọ́rìn aláyọ̀ ìṣẹ́gun ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀+ pẹ̀lú Kristi, tí ó sì ń mú kí a tipasẹ̀ wa gbọ́ òórùn ìmọ̀ nípa rẹ̀ ní ibi gbogbo!+ 15  Nítorí fún Ọlọ́run, àwa jẹ́ òórùn dídùn+ Kristi láàárín àwọn tí a ń gbà là àti láàárín àwọn tí ń ṣègbé;+ 16  fún àwọn ti ìkẹyìn yìí, òórùn tí ń jáde láti inú ikú sí ikú,+ fún àwọn ti ìṣáájú òórùn tí ń jáde láti inú ìyè sí ìyè. Ta ní sì tóótun tẹ́rùntẹ́rùn fún nǹkan wọ̀nyí?+ 17  Àwa ni; nítorí àwa kì í ṣe akirità ọ̀rọ̀ Ọlọ́run+ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti jẹ́,+ ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí pẹ̀lú òtítọ́ inú, bẹ́ẹ̀ ni, gẹ́gẹ́ bí a ti rán wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ní iwájú Ọlọ́run, ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, ni àwa ń sọ̀rọ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé