Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Kọ́ríńtì 13:1-14

13  Èyí ni ìgbà kẹta+ tí mo ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín. “Lẹ́nu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó fìdí ọ̀ràn gbogbo múlẹ̀.”+  Mo ti sọ ní ìṣáájú àti pé, bí ẹni pé mo wà lọ́dọ̀ yín ní ìgbà kejì àti síbẹ̀ nísinsìnyí tí èmi kò sí lọ́dọ̀ yín, mo ń sọ ṣáájú fún àwọn tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí àti fún gbogbo àwọn yòókù, pé bí mo bá tún dé, dájúdájú èmi kì yóò dá wọn sí,+  níwọ̀n bí ẹ ti ń wá ẹ̀rí ìdánilójú pé Kristi ń sọ̀rọ̀ nínú mi,+ Kristi tí kì í ṣe aláìlera sí yín ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ alágbára láàárín yín.  Ní ti gidi, lóòótọ́ a kàn án mọ́gi+ nítorí àìlera,+ ṣùgbọ́n ó wà láàyè nítorí agbára Ọlọ́run.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, lóòótọ́ a jẹ́ aláìlera pẹ̀lú rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò wà láàyè pa pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀+ nítorí agbára Ọlọ́run+ sí yín.  Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́, ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.+ Tàbí ẹ kò mọ̀ dájú pé Jésù Kristi wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú yín?+ Àyàfi bí ẹ bá jẹ́ ẹni tí a kò tẹ́wọ́ gbà.  Mo ní ìrètí lóòótọ́ pé ẹ óò wá mọ̀ pé àwa kì í ṣe ẹni tí a kò tẹ́wọ́ gbà.  Wàyí o, àwa ń gbàdúrà+ sí Ọlọ́run pé kí ẹ má ṣe ohun àìtọ́ kankan, kì í ṣe kí àwa fúnra wa lè fara hàn bí ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, bí kò ṣe kí ẹ lè máa ṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa fúnra wa lè fara hàn bí ẹni tí a kò tẹ́wọ́ gbà.  Nítorí a kò lè ṣe ohunkóhun lòdì sí òtítọ́, bí kò ṣe kìkì fún òtítọ́.+  Dájúdájú, àwa ń yọ̀ nígbàkígbà tí a bá jẹ́ aláìlera ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin jẹ́ alágbára;+ èyí sì ni àwa ń gbàdúrà+ fún, títọ́ yín sọ́nà padà. 10  Ìdí nìyẹn tí èmi fi ń kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí nígbà tí èmi kò sí lọ́dọ̀ yín, pé, nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín, kí n má bàa gbé ìgbésẹ̀ pẹ̀lú ìmúnájanjan+ gẹ́gẹ́ bí ọlá àṣẹ tí Olúwa fún mi, láti gbéró+ kì í sì í ṣe láti ya lulẹ̀. 11  Lákòótán, ẹ̀yin ará, ẹ máa bá a lọ ní yíyọ̀, ní gbígba ìtọ́sọ́nàpadà, ní gbígba ìtùnú,+ ní ríronú ní ìfohùnṣọ̀kan,+ ní gbígbé pẹ̀lú ẹ̀mí àlàáfíà;+ Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà+ yóò sì wà pẹ̀lú yín. 12  Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.+ 13  Gbogbo ẹni mímọ́ kí yín. 14  Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ti Jésù Kristi Olúwa àti ìfẹ́ Ọlọ́run àti ṣíṣe àjọpín nínú ẹ̀mí mímọ́ wà pẹ̀lú gbogbo yín.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé