Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kọ́ríńtì 12:1-21

12  Mo ní láti ṣògo. Kò ṣàǹfààní; ṣùgbọ́n èmi yóò kọjá lọ sínú àwọn ìran tí ó jù ti ẹ̀dá lọ+ àti àwọn ìṣípayá ti Olúwa.  Mo mọ ọkùnrin kan ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, ẹni tí a gbà lọ+ lọ́nà bẹ́ẹ̀ sí ọ̀run kẹta ní ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yìn—yálà nínú ara èmi kò mọ̀, tàbí lóde ara èmi kò mọ̀; Ọlọ́run mọ̀.  Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ irúfẹ́ ọkùnrin kan bẹ́ẹ̀—yálà nínú ara tàbí láìsí ara,+ èmi kò mọ̀, Ọlọ́run mọ̀—  pé a gbà á lọ sínú párádísè,+ ó sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí a kò lè fẹnu sọ, èyí tí kò bófin mu fún ènìyàn láti sọ.  Nípa irúfẹ́ ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣògo, ṣùgbọ́n èmi kì yóò ṣògo nípa ara mi, àyàfi nípa àwọn àìlera mi.+  Nítorí bí mo bá fẹ́ láti ṣògo pẹ́nrẹ́n,+ èmi kì yóò jẹ́ aláìlọ́gbọ́n-nínú, nítorí èmi yóò sọ òtítọ́. Ṣùgbọ́n mo fà sẹ́yìn, kí ẹnikẹ́ni má bàa gbé mi níyì ju ohun tí ó rí pé mo jẹ́ tàbí tí ó gbọ́ láti ọ̀dọ̀ mi,  kìkì nítorí àpọ̀jù àwọn ìṣípayá. Nítorí náà, kí èmi má bàa ní ìmọ̀lára pé a gbé mi ga púpọ̀ jù,+ a fi ẹ̀gún kan sínú ẹran ara mi,+ áńgẹ́lì Sátánì, láti máa gbá mi ní àbàrá ṣáá, kí a má bàa gbé mi ga púpọ̀ jù.  Nítorí èyí, ìgbà mẹ́ta+ ni mo pàrọwà fún Olúwa pé kí ó lè kúrò lára mi;  síbẹ̀síbẹ̀, ó sọ fún mi ní ti gidi pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ;+ nítorí agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.”+ Nítorí náà, ṣe ni èmi yóò kúkú máa fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gan-an ṣògo nípa àwọn àìlera [mi],+ kí agbára Kristi lè wà lórí mi bí àgọ́. 10  Nítorí náà, mo ní ìdùnnú nínú àwọn àìlera, nínú àwọn ìwọ̀sí, nínú àwọn ọ̀ràn àìní, nínú àwọn inúnibíni àti àwọn ìṣòro, fún Kristi. Nítorí nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.+ 11  Mo ti di aláìlọ́gbọ́n-nínú. Ẹ̀yin ni ẹ sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún mi+ láti dà bẹ́ẹ̀, nítorí ó yẹ kí ẹ ti dámọ̀ràn mi fún ìtẹ́wọ́gbà. Nítorí nínú ẹyọ ohun kan, èmi kò já sí ẹni tí ó rẹlẹ̀ sí àwọn àpọ́sítélì yín adárarégèé,+ bí èmi kò tilẹ̀ jẹ́ nǹkan kan.+ 12  Ní tòótọ́, àwọn àmì àpọ́sítélì+ ni a mú jáde láàárín yín nípasẹ̀ ìfaradà+ gbogbo, àti nípasẹ̀ àwọn àmì àti àwọn àmì àgbàyanu àti àwọn iṣẹ́ agbára.+ 13  Nítorí lọ́nà wo ni ẹ̀yin gbà rẹlẹ̀ sí àwọn ìjọ yòókù, àyàfi pé èmi fúnra mi kò di ẹrù ìnira fún yín?+ Ẹ fi inú rere dárí àìtọ́ yìí jì mí. 14  Wò ó! Èyí ni ìgbà kẹta+ tí mo múra tán láti wá sọ́dọ̀ yín, síbẹ̀síbẹ̀, èmi kì yóò di ẹrù ìnira. Nítorí kì í ṣe àwọn ohun ìní+ yín ni mo ń wá bí kò ṣe ẹ̀yin; nítorí kò yẹ fún àwọn ọmọ+ láti to nǹkan jọ fún àwọn òbí wọn, bí kò ṣe àwọn òbí fún àwọn ọmọ+ wọn. 15  Ní tèmi, ṣe ni èmi yóò máa fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gan-an náwó, a ó sì ná mi tán pátápátá fún ọkàn yín.+ Bí mo bá nífẹ̀ẹ́ yín púpọ̀púpọ̀, a ha ní láti nífẹ̀ẹ́ mi lọ́nà tí ó dìn kú bí? 16  Ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí èyíinì rí, èmi kò di ẹrù ìnira rù yín.+ Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ sọ pé, mo jẹ́ “alárekérekè” mo sì “fi ìwà àgálámàṣà” mú yín.+ 17  Ní ti ẹnikẹ́ni nínú àwọn tí mo ti rán wá sọ́dọ̀ yín, èmi kò yàn yín jẹ nípasẹ̀ rẹ̀, àbí mo ṣe bẹ́ẹ̀? 18  Mo rọ Títù, mo sì rán arákùnrin náà pẹ̀lú rẹ̀. Títù kò yàn yín jẹ rárá, àbí ó ṣe bẹ́ẹ̀?+ Nínú ẹ̀mí kan náà ni a rìn,+ àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Nínú ipasẹ̀ kan náà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? 19  Ẹ ha ti ń ronú ní gbogbo ìgbà yìí pé àwa ti ń gbèjà ara wa níwájú yín bí? Níwájú Ọlọ́run ni a ti ń sọ̀rọ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi. Ṣùgbọ́n, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ohun gbogbo wà fún ìgbéró yín.+ 20  Nítorí mo ń fòyà pé lọ́nà kan ṣáá, nígbà tí mo bá dé,+ mo lè má bá yín gẹ́gẹ́ bí èmi ì bá ti fẹ́, mo sì lè má jẹ́ sí yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ì bá ti fẹ́, ṣùgbọ́n, dípò bẹ́ẹ̀, kí ó jẹ́ pé lọ́nà kan ṣáá gbọ́nmi-si omi-ò-to, owú,+ àwọn ọ̀ràn ìbínú, asọ̀, ìsọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn, ìsọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́, àwọn ọ̀ràn ìwúfùkẹ̀, rúdurùdu+ ni yóò wà. 21  Bóyá, nígbà tí mo bá tún dé, Ọlọ́run mi lè tẹ́ mi lógo láàárín yín, mo sì lè ṣọ̀fọ̀ lórí ọ̀pọ̀ lára àwọn tí ó ti dẹ́ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí+ ṣùgbọ́n tí wọn kò tíì ronú pìwà dà ìwà àìmọ́ àti àgbèrè+ àti ìwà àìníjàánu+ wọn tí wọ́n ti fi ṣe ìwà hù.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé