Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Kọ́ríńtì 11:1-33

11  Ì bá wù mí kí ẹ fara dà á fún mi nínú àìlọ́gbọ́n-nínú díẹ̀.+ Ṣùgbọ́n, ní ti tòótọ́, ẹ ń fara dà á fún mi!  Nítorí èmi ń jowú lórí yín pẹ̀lú owú lọ́nà ti Ọlọ́run,+ nítorí èmi fúnra mi ti fẹ́ yín sọ́nà+ fún ọkọ+ kan, kí èmi lè mú yín wá fún Kristi+ gẹ́gẹ́ bí wúńdíá oníwàmímọ́.+  Ṣùgbọ́n mo ń fòyà pé lọ́nà kan ṣáá, bí ejò ti sún Éfà dẹ́ṣẹ̀+ nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí rẹ̀, a lè sọ èrò inú yín di ìbàjẹ́+ kúrò nínú òtítọ́ inú àti ìwà mímọ́ tí ó tọ́ sí Kristi.+  Nítorí, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, bí ẹnì kan bá wá, tí ó sì ń wàásù Jésù kan yàtọ̀ sí èyí tí àwa wàásù,+ tàbí ẹ̀yin rí ẹ̀mí kan gbà yàtọ̀ sí ohun tí ẹ rí gbà,+ tàbí ìhìn rere+ yàtọ̀ sí ohun tí ẹ gbà, ẹ fara dà á fún un+ tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn.  Nítorí mo rò pé nínú ẹyọ ohun kan èmi kò tíì já sí ẹni tí ó rẹlẹ̀+ sí àwọn àpọ́sítélì yín adárarégèé.+  Ṣùgbọ́n bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjáfáfá nínú ọ̀rọ̀ sísọ,+ dájúdájú, èmi kò jẹ́ bẹ́ẹ̀ nínú ìmọ̀;+ ṣùgbọ́n ní gbogbo ọ̀nà, àwa ń fi í hàn kedere fún yín nínú ohun gbogbo.+  Tàbí mo ha dá ẹ̀ṣẹ̀ nípa rírẹ ara mi sílẹ̀+ kí a bàa lè gbé yín ga, nítorí lọ́fẹ̀ẹ́+ ni mo fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ polongo ìhìn rere Ọlọ́run fún yín?  Àwọn ìjọ mìíràn ni mo jà lólè nípa títẹ́wọ́gba àwọn ìpèsè kí n bàa lè ṣe ìránṣẹ́ fún yín;+  síbẹ̀síbẹ̀, nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ yín, tí mo sì bọ́ sínú àìní, èmi kò di ẹrù ìnira fún ẹyọ ẹnì kan,+ nítorí pé àwọn arákùnrin tí wọ́n wá láti Makedóníà+ pèsè lọ́pọ̀ yanturu fún àìnító mi. Bẹ́ẹ̀ ni, lọ́nà gbogbo, mo pa ara mi mọ́ láìjẹ́ ẹrù ìnira fún yín, èmi yóò sì máa pa ara mi mọ́ bẹ́ẹ̀.+ 10  Òtítọ́+ Kristi ni ó jẹ́ nínú ọ̀ràn mi pé dájúdájú a kì yóò pa ìṣògo+ mi yìí lẹ́nu mọ́ ní àwọn ẹkùn ilẹ̀ Ákáyà. 11  Fún ìdí wo? Ṣé nítorí èmi kò nífẹ̀ẹ́ yín ni? Ọlọ́run mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ yín.+ 12  Wàyí o, ohun tí mo ń ṣe ni èmi yóò máa ṣe+ síbẹ̀ dájúdájú, kí n lè ké ohun àfiṣe-bojúbojú kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ń fẹ́ ohun àfiṣe-bojúbojú láti rí i pé àwọn bá wa dọ́gba nínú ipò iṣẹ́ tí wọ́n fi ń ṣògo. 13  Nítorí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ èké àpọ́sítélì, àwọn oníṣẹ́ ẹ̀tàn,+ tí ń pa ara wọn dà di àpọ́sítélì Kristi.+ 14  Kò sì ṣeni ní kàyéfì, nítorí Sátánì fúnra rẹ̀ a máa pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.+ 15  Nítorí náà, kì í ṣe ohun ńlá bí àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀+ pẹ̀lú bá ń pa ara wọn dà di òjíṣẹ́ òdodo. Ṣùgbọ́n òpin wọn dájúdájú yóò rí bí iṣẹ́ wọn.+ 16  Mo tún wí pé, Kí ẹnikẹ́ni má rò pé mo jẹ́ aláìlọ́gbọ́n-nínú. Síbẹ̀, bí ẹ bá rò bẹ́ẹ̀ ní ti gidi, ẹ tẹ́wọ́ gbà mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n-nínú pàápàá, kí èmi pẹ̀lú lè ṣògo díẹ̀.+ 17  Ohun tí mo ń sọ ni mo ń sọ, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú àpẹẹrẹ ti Olúwa, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí nínú àìlọ́gbọ́n-nínú, nínú ìdára-ẹni-lójú jù yìí tí ó jẹ́ ti ìṣògo nìkan.+ 18  Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ ti ń ṣògo nípa ti ẹran ara,+ dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò ṣògo. 19  Nítorí pẹ̀lú ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ni ẹ ń fara dà á fún àwọn aláìlọ́gbọ́n-nínú, ní rírí i pé ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n-nínú. 20  Ní ti tòótọ́, ẹ ń fara dà á fún ẹnì yòówù tí ó sọ yín di ẹrú,+ ẹnì yòówù tí ó jẹ ohun tí ẹ ní ní àjẹrun, ẹnì yòówù tí ó já ohun tí ẹ ní gbà, ẹnì yòówù tí ó gbé ara rẹ̀ ga lé yín lórí, ẹnì yòówù tí ó gbá yín lójú.+ 21  Mo sọ èyí fún àbùkù wa, bí ẹni pé ipò wa ti jẹ́ aláìlera. Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni mìíràn bá gbé ìgbésẹ̀ àyà-níní nínú ohun kan—èmi ń sọ̀rọ̀ lọ́nà àìlọ́gbọ́n-nínú+—èmi náà ń gbé ìgbésẹ̀ àyà-níní nínú rẹ̀. 22  Hébérù ni wọ́n bí? Èmi pẹ̀lú jẹ́ ọ̀kan.+ Ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n bí? Èmi pẹ̀lú jẹ́ ọ̀kan. Irú-ọmọ Ábúráhámù ni wọ́n bí? Èmi pẹ̀lú jẹ́ bẹ́ẹ̀.+ 23  Òjíṣẹ́ Kristi ni wọ́n bí? Mo fèsì bí aṣiwèrè, lọ́nà tí ó túbọ̀ ta yọ, mo jẹ́ ọ̀kan:+ nínú òpò ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ,+ nínú ẹ̀wọ̀n ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ,+ nínú lílù dé ìwọ̀n tí ó pọ̀ lápọ̀jù, nínú bèbè ikú ní ọ̀pọ̀ ìgbà.+ 24  Ìgbà márùn-ún ni mo gba ẹgba ogójì+ dín ọ̀kan láti ọwọ́ àwọn Júù, 25  ìgbà mẹ́ta ni a fi ọ̀pá nà mí,+ lẹ́ẹ̀kan a sọ mí lókùúta,+ ìgbà mẹ́ta ni mo ní ìrírí ọkọ̀ rírì,+ òru kan àti ọ̀sán kan ni mo ti lò nínú ibú; 26  nínú àwọn ìrìn àjò ní ọ̀pọ̀ ìgbà, nínú àwọn ewu odò, nínú àwọn ewu dánàdánà,+ nínú àwọn ewu láti ọwọ́ ẹ̀yà tèmi+ fúnra mi, nínú àwọn ewu láti ọwọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,+ nínú àwọn ewu nínú ìlú ńlá,+ nínú àwọn ewu nínú aginjù, nínú àwọn ewu lójú òkun, nínú àwọn ewu láàárín àwọn èké arákùnrin, 27  nínú òpò àti làálàá, nínú àwọn òru àìlèsùn+ ní ọ̀pọ̀ ìgbà, nínú ebi àti òùngbẹ,+ nínú ìtakété sí oúnjẹ+ ní ọ̀pọ̀ ìgbà, nínú òtútù àti ìhòòhò. 28  Yàtọ̀ sí nǹkan wọnnì tí ó jẹ́ ti òde, àwọn nǹkan tí ń rọ́ wọlé tọ̀ mí láti ọjọ́ dé ọjọ́ wà níbẹ̀, àníyàn fún gbogbo àwọn ìjọ.+ 29  Ta ní jẹ́ aláìlera,+ tí èmi kò sì jẹ́ aláìlera? Ta ní a mú kọsẹ̀, tí ara mi kò sì gbaná jẹ? 30  Bí ìṣògo bá ní láti wà, dájúdájú, èmi yóò ṣògo+ nínú àwọn ohun tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àìlera mi. 31  Ọlọ́run àti Baba Jésù Olúwa, àní Ẹni tí a óò máa yìn títí láé, mọ̀ pé èmi kò purọ́. 32  Ní Damásíkù, gómìnà abẹ́ Árétásì Ọba ń ṣọ́ ìlú ńlá àwọn ará Damásíkù láti gbá mi mú,+ 33  ṣùgbọ́n a sọ̀ mí kalẹ̀ nínú apẹ̀rẹ̀ pankẹ́rẹ́+ gba ojú fèrèsé lára ògiri, mo sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé