Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

2 Kọ́ríńtì 10:1-18

10  Wàyí o, èmi fúnra mi, Pọ́ọ̀lù, fi ìwà tútù+ àti inú rere+ Kristi pàrọwà fún yín, bí mo tilẹ̀ jẹ́ ẹni rírẹlẹ̀ ní ìrísí+ láàárín yín, ṣùgbọ́n mo láyà sí yín+ nígbà tí èmi kò bá sí lọ́dọ̀ yín.  Ní tòótọ́, mo bẹ̀bẹ̀ pé, nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín, kí èmi má lo àyà-níní+ pẹ̀lú ìgbọ́kànlé yẹn, èyí tí mo fi ń gbójú lé gbígbé àwọn ìgbésẹ̀ àyà-níní lòdì sí àwọn kan tí ń díwọ̀n wa bí ẹni pé àwa ń rìn gẹ́gẹ́ bí ohun tí a jẹ́ nínú ẹran ara.  Nítorí bí àwa tilẹ̀ ń rìn nínú ẹran ara,+ a kò ja ogun gẹ́gẹ́ bí ohun tí a jẹ́ nínú ẹran ara.+  Nítorí àwọn ohun ìjà ogun wa kì í ṣe ti ara,+ ṣùgbọ́n wọ́n jẹ alágbára láti ọwọ́ Ọlọ́run+ fún dídojú àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in dé.  Nítorí àwọn ìrònú àti gbogbo ohun gíga fíofío tí a gbé dìde lòdì sí ìmọ̀ nípa Ọlọ́run+ ni àwa ń dojú wọn dé; a sì ń mú gbogbo ìrònú wá sí oko òǹdè láti mú un ṣègbọràn sí Kristi; 6  àwa sì ti múra sílẹ̀ láti fi ìyà jẹni fún gbogbo àìgbọ́ràn,+ ní gbàrà tí ẹ bá ti mú ìgbọràn tiyín ṣẹ ní kíkún.+  Ẹ ń wo àwọn nǹkan gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe rí lójú.+ Bí ẹnikẹ́ni bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara rẹ̀ pé òun jẹ́ ti Kristi, kí ó tún gba òtítọ́ yìí rò fún ara rẹ̀, pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí òun ti jẹ́ ti Kristi, bẹ́ẹ̀ ni àwa pẹ̀lú jẹ́.+  Nítorí bí mo bá tilẹ̀ níláti ṣògo+ lọ́nà tí ó pọ̀ díẹ̀ nípa ọlá àṣẹ tí Olúwa fi fún wa láti fi gbé yín ró, kì í sì í ṣe láti ya yín lulẹ̀,+ a kì yóò kó ìtìjú bá mi,  kí ó má bàa dà bí pé mo ń fẹ́ láti fi àwọn lẹ́tà mi já yín láyà. 10  Nítorí, wọ́n wí pé: “Àwọn lẹ́tà rẹ̀ wúwo, wọ́n sì lágbára, ṣùgbọ́n wíwàníhìn-ín òun alára jẹ́ aláìlera,+ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì ní láárí.”+ 11  Kí irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ gba èyí rò, pé ohun tí a jẹ́ nínú ọ̀rọ̀ wa nínú lẹ́tà nígbà tí a kò sí lọ́dọ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò jẹ́ pẹ̀lú nínú ìṣe nígbà tí a bá wà lọ́dọ̀ yín.+ 12  Nítorí àwa kò jẹ́ gbójúgbóyà láti fi ara wa sí ìsọ̀rí àwọn kan tàbí fi ara wa wé àwọn kan tí ń dámọ̀ràn ara wọn fún ìtẹ́wọ́gbà.+ Dájúdájú, ní fífi ara wọn díwọ̀n ara wọn àti fífi ara wọn wé ara wọn, wọn kò ní òye.+ 13  Ní tiwa, ó dájú pé a kì yóò ṣògo lóde àwọn ààlà tí a pa sílẹ̀+ fún wa, ṣùgbọ́n ní ìbámu pẹ̀lú ààlà ìpínlẹ̀ tí Ọlọ́run pín fún wa nípa ìdíwọ̀n, ní mímú kí ó lọ jìnnà títí dé ọ̀dọ̀ yín pàápàá.+ 14  Ní ti gidi, a kò na ara wa tàntàn ré kọjá ààlà bí ẹni pé a kò dé ọ̀dọ̀ yín, nítorí àwa ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó wá àní títí dé ọ̀dọ̀ yín ní pípolongo ìhìn rere nípa Kristi.+ 15  Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa kò ṣògo ní ẹ̀yìn òde àwọn ìpínlẹ̀ tí a yàn fún wa nínú òpò ti ẹlòmíràn,+ ṣùgbọ́n àwa ní ìrètí náà pé, bí a ti ń sọ ìgbàgbọ́ yín di púpọ̀ sí i,+ a lè sọ wá di ẹni ńlá láàárín yín ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìpínlẹ̀ wa.+ Dájúdájú, nígbà náà, àwa yóò túbọ̀ máa pọ̀ sí i gidigidi, 16  láti polongo ìhìn rere fún àwọn ẹkùn ìpínlẹ̀ tí ó wà ní ìkọjá ọ̀dọ̀ yín,+ kí a má bàa ṣògo nínú ìpínlẹ̀ ti ẹlòmíràn níbi tí wọ́n ti múra àwọn nǹkan sílẹ̀ tẹ́lẹ̀. 17  “Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣògo, kí ó máa ṣògo nínú Jèhófà.”+ 18  Nítorí kì í ṣe ẹni tí ń dámọ̀ràn ara rẹ̀ fún ìtẹ́wọ́gbà ni a tẹ́wọ́ gbà,+ bí kò ṣe ẹni tí Jèhófà+ dámọ̀ràn fún ìtẹ́wọ́gbà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé