Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Kíróníkà 6:1-42

6  Ìgbà náà ni Sólómọ́nì wí pé:+ “Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ pé òun yóò máa gbé inú ìṣúdùdù nínípọn;+  èmi, ní tèmi, sì ti kọ́ ilé tí ó jẹ́ ibùjókòó gíga fíofío fún ọ àti ibi àfìdímúlẹ̀ fún ọ+ láti máa gbé fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+  Nígbà náà ni ọba yí ojú rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí súre+ fún gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, bí gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì ti wà ní ìdúró.+  Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ ẹni tí ó fi ẹnu ara rẹ̀ bá Dáfídì baba mi+ sọ̀rọ̀ tí ó sì ti fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú un ṣẹ,+ pé,  ‘Láti ọjọ́ tí mo ti mú àwọn ènìyàn mi jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, èmi kò yan ìlú ńlá kan nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti kọ́ ilé fún orúkọ mi+ kí ó lè máa wà níbẹ̀, èmi kò sì yan ọkùnrin kan láti di aṣáájú lórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.+  Ṣùgbọ́n èmi yóò yan Jerúsálẹ́mù+ fún orúkọ mi kí ó lè máa wà níbẹ̀, èmi yóò sì yan Dáfídì láti wá wà lórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.’+  Ó sì wà ní góńgó ọkàn-àyà Dáfídì baba mi láti kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+  Ṣùgbọ́n Jèhófà wí fún Dáfídì baba mi pé, ‘Nítorí ìdí náà pé ó wà ní góńgó ọkàn-àyà rẹ láti kọ́ ilé fún orúkọ mi, o ṣe dáadáa nítorí pé ó wà ní góńgó ọkàn-àyà rẹ.+  Kìkì pé kì í ṣe ìwọ fúnra rẹ ni yóò kọ́ ilé náà,+ ṣùgbọ́n ọmọkùnrin rẹ tí yóò jáde láti abẹ́nú rẹ wá ni ẹni tí yóò kọ́ ilé náà fún orúkọ mi.’+ 10  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ọ̀rọ̀+ rẹ̀ tí ó ti sọ ṣẹ, kí èmi lè dìde ní ipò Dáfídì baba mi,+ kí n sì jókòó sórí ìtẹ́+ Ísírẹ́lì, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ,+ kí n sì lè kọ́ ilé náà fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ 11  kí n sì lè gbé Àpótí+ síbẹ̀ níbi tí májẹ̀mú Jèhófà wà, èyí tí ó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá.”+ 12  Ó sì dúró níwájú pẹpẹ Jèhófà ní iwájú gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì,+ ó sì tẹ́ àtẹ́lẹwọ́+ rẹ̀ wàyí. 13  (Nítorí pé Sólómọ́nì ti ṣe pèpéle+ bàbà, ó sì wá gbé e sí àárín gbàgede.+ Gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta; ó sì wà ní ìdúró lórí rẹ̀.) Ó sì kúnlẹ̀+ lórí eékún rẹ̀ ní iwájú gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, ó sì tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ sí ọ̀run.+ 14  Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ kò sí Ọlọ́run tí ó dà bí rẹ+ ní àwọn ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé, tí ń pa májẹ̀mú+ àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́ sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ń fi gbogbo ọkàn-àyà wọn rìn níwájú rẹ;+ 15  ìwọ tí o ti pa ohun tí o ṣèlérí fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì baba mi mọ́ sí i,+ tí ó fi jẹ́ pé, o fi ẹnu ara rẹ ṣe ìlérí, o sì ti fi ọwọ́ ara rẹ mú un ṣẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí yìí.+ 16  Wàyí o, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, pa ohun tí o ṣèlérí fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì baba mi mọ́ sí i, pé, ‘A kì yóò ké ọkùnrin tìrẹ kankan kúrò níwájú mi láti máa jókòó sórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì,+ kìkì bí àwọn ọmọ rẹ+ yóò bá kíyè sí ọ̀nà wọn nípa rírìn nínú òfin mi,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti rìn níwájú mi.’+ 17  Wàyí o, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ kí ìlérí+ rẹ tí o ti ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì já sí aṣeégbẹ́kẹ̀lé.+ 18  “Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ha máa bá aráyé gbé lórí ilẹ̀ ayé ní tòótọ́ bí?+ Wò ó! Ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀run àwọn ọ̀run, kò lè gbà ọ́;+ nígbà náà, áńbọ̀sìbọ́sí ilé yìí tí mo kọ́!+ 19  Kí o sì yíjú sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ+ àti sí ìbéèrè rẹ̀ fún ojú rere,+ ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, nípa fífetísí igbe ìpàrọwà+ àti sí àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà níwájú rẹ,+ 20  kí ojú rẹ lè là+ sí ilé yìí tọ̀sán-tòru, sí ibi tí o sọ pé ìwọ yóò fi orúkọ rẹ sí,+ nípa fífetísí àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà síhà ibí yìí.+ 21  Kí o sì fetí sí ìpàrọwà ìránṣẹ́+ rẹ àti ti àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà síhà ibí yìí,+ kí ìwọ fúnra rẹ lè gbọ́ láti ibi tí o ń gbé, láti ọ̀run;+ kí o sì gbọ́ kí o sì dárí jì.+ 22  “Bí ènìyàn kan bá ṣẹ̀ sí ọmọnìkejì rẹ̀,+ tí ó sì gbé ègún lé e lórí ní tòótọ́, láti mú un wá sínú ipò dídáhùn+ fún ègún náà, tí ó sì wá ní tòótọ́ síwájú pẹpẹ rẹ nínú ilé yìí,+ nígbà tí ó wà nínú ègún náà, 23  nígbà náà, kí ìwọ alára gbọ́ láti ọ̀run,+ kí o sì gbé ìgbésẹ̀,+ kí o sì ṣe ìdájọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ láti lè san án padà fún ẹni burúkú nípa fífi ipa ọ̀nà rẹ̀ sí orí òun fúnra rẹ̀+ àti nípa pípe olódodo ní olódodo+ nípa fífi fún un ní ìbámu pẹ̀lú òdodo tirẹ̀.+ 24  “Bí a bá sì ṣẹ́gun àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì níwájú ọ̀tá+ nítorí pé wọ́n ń bá a nìṣó ní dídẹ́ṣẹ̀ sí ọ,+ tí wọ́n sì padà ní tòótọ́,+ tí wọ́n sì gbé orúkọ+ rẹ lárugẹ, tí wọ́n sì gbàdúrà,+ tí wọ́n sì béèrè fún ojú rere níwájú rẹ nínú ilé yìí,+ 25  nígbà náà, kí ìwọ alára gbọ́ láti ọ̀run,+ kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì jì,+ kí o sì mú wọn padà wá+ sí ilẹ̀ tí o fi fún àwọn àti àwọn baba ńlá wọn.+ 26  “Nígbà tí a bá sé ọ̀run pa tó bẹ́ẹ̀ tí òjò kò rọ̀+ nítorí pé wọ́n ń bá a nìṣó ní dídẹ́ṣẹ̀+ sí ọ, tí wọ́n sì gbàdúrà ní tòótọ́ síhà ibí yìí,+ tí wọ́n sì gbé orúkọ rẹ lárugẹ, tí wọ́n sì yí padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí pé ìwọ ń bá a nìṣó ní ṣíṣẹ́ wọn níṣẹ̀ẹ́,+ 27  nígbà náà, kí ìwọ alára gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ jì, àní ti àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì, nítorí pé o fún wọn ní ìtọ́ni+ nípa ọ̀nà rere+ tí ó yẹ kí wọ́n máa rìn; kí o sì rọ̀jò+ sórí ilẹ̀ rẹ tí o ti fi fún àwọn ènìyàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní àjogúnbá.+ 28  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìyàn+ mú ní ilẹ̀ náà, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àjàkálẹ̀ àrùn+ jà, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìjógbẹ+ ṣẹlẹ̀ àti èbíbu,+ eéṣú+ àti aáyán;+ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọ̀tá+ wọn sàga tì wọ́n ní ilẹ̀ àwọn ẹnubodè+ wọn—irú ìyọnu àjàkálẹ̀ èyíkéyìí àti irú àrùn+ èyíkéyìí— 29  àdúrà+ yòówù, ìbéèrè fún ojú rere+ yòówù tí ó bá wáyé láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tàbí láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì,+ nítorí pé olúkúlùkù wọn mọ ìyọnu àjàkálẹ̀+ tirẹ̀ àti ìrora tirẹ̀; nígbà tí ó bá tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ ní tòótọ́ síhà ilé yìí,+ 30  nígbà náà, kí ìwọ alára gbọ́ láti ọ̀run, ibi tí o ń gbé,+ kí o sì dárí jì,+ kí o sì fi fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+ nítorí pé o mọ ọkàn-àyà rẹ̀+ (nítorí ìwọ fúnra rẹ nìkan ṣoṣo ni ó mọ ọkàn-àyà ọmọ aráyé ní àmọ̀dunjú);+ 31  kí wọ́n lè máa bẹ̀rù+ rẹ nípa rírìn ní àwọn ọ̀nà rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n wà láàyè ní orí ilẹ̀ tí o fi fún àwọn baba ńlá wa.+ 32  “Pẹ̀lúpẹ̀lù, ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí kì í ṣe ara àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì,+ tí ó sì ti ilẹ̀ jíjìnnà wá ní tòótọ́ nítorí orúkọ ńlá+ rẹ àti ọwọ́ líle+ rẹ àti apá rẹ nínà jáde,+ tí wọ́n sì wá ní tòótọ́, tí wọ́n sì gbàdúrà síhà ilé yìí,+ 33  ni kí ìwọ alára fetí sí nígbà náà láti ọ̀run, láti ibi àfìdímúlẹ̀ tí o ń gbé,+ kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè náà ké pè ọ́ sí;+ kí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé lè mọ orúkọ rẹ,+ kí wọ́n sì lè máa bẹ̀rù+ rẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì ti ń ṣe, kí wọ́n sì mọ̀ pé a ti fi orúkọ rẹ pe ilé yìí tí mo kọ́.+ 34  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn ènìyàn rẹ jáde lọ sí ogun+ láti gbéjà ko àwọn ọ̀tá wọn ní ọ̀nà tí o rán+ wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà+ sí ọ ní tòótọ́ sí ìhà ìlú ńlá yìí tí o yàn àti ilé tí mo kọ́ fún orúkọ rẹ,+ 35  kí o gbọ́ àdúrà wọn àti ìbéèrè wọn fún ojú rere+ pẹ̀lú láti ọ̀run, kí o sì mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún fún wọn.+ 36  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí ọ+ (nítorí kò sí ènìyàn tí kì í dẹ́ṣẹ̀),+ tí ìbínú rẹ sì ru sókè sí wọn, tí o sì jọ̀wọ́ wọn fún ọ̀tá, tí àwọn tí ó mú wọn ní òǹdè sì kó wọn lọ ní òǹdè ní ti tòótọ́ sí ilẹ̀ tí ó jìnnà tàbí tí ó wà nítòsí;+ 37  tí orí wọ́n sì wálé ní tòótọ́ ní ilẹ̀ tí a kó wọn lọ ní òǹdè, tí wọ́n sì padà ní ti tòótọ́, tí wọ́n sì béèrè fún ojú rere lọ́dọ̀ rẹ ní ilẹ̀ tí wọ́n ti jẹ́ òǹdè,+ pé, ‘A ti dẹ́ṣẹ̀,+ a ti ṣìnà,+ a sì ti ṣe burúkú’;+ 38  tí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn-àyà+ wọn àti gbogbo ọkàn wọn padà sọ́dọ̀ rẹ ní tòótọ́ ní ilẹ̀ tí wọ́n ti jẹ́ òǹdè+ àwọn tí ó kó wọn lọ ní òǹdè, tí wọ́n sì gbàdúrà ní tòótọ́ sí ìhà ilẹ̀ wọn tí o fi fún àwọn baba ńlá wọn àti ìlú ńlá tí o yàn+ àti ilé tí mo kọ́ fún orúkọ+ rẹ; 39  kí o sì gbọ́ àdúrà àti àwọn ìbéèrè wọn fún ojú rere+ láti ọ̀run, láti ibi àfìdímúlẹ̀ tí o ń gbé,+ kí o sì mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún+ fún wọn kí o sì dárí ji+ àwọn ènìyàn rẹ tí ó ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ. 40  “Wàyí o, ìwọ Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́, jẹ́ kí ojú rẹ+ là, kí etí+ rẹ sì ṣí sí àdúrà nípa ibí yìí. 41  Wàyí o, dìde,+ Jèhófà Ọlọ́run, sínú ìsinmi rẹ,+ ìwọ àti Àpótí okun rẹ.+ Jẹ́ kí a fi aṣọ ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà rẹ, Jèhófà Ọlọ́run, sì jẹ́ kí àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ yọ̀ nínú ohun rere.+ 42  Jèhófà Ọlọ́run, má ṣe yí ojú ẹni àmì òróró+ rẹ padà. Rántí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé