Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Kíróníkà 5:1-14

5  Níkẹyìn, gbogbo iṣẹ́ tí Sólómọ́nì ní í ṣe fún ilé Jèhófà dé ìparí rẹ̀,+ Sólómọ́nì sì bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ohun tí Dáfídì baba rẹ̀ sọ di mímọ́ wọlé;+ fàdákà àti wúrà àti gbogbo nǹkan èlò ni ó sì kó sínú àwọn ìṣúra ilé Ọlọ́run tòótọ́.+  Nígbà náà ni Sólómọ́nì tẹ̀ síwájú láti pe àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì+ jọ àti gbogbo olórí àwọn ẹ̀yà,+ àwọn ìjòyè ti àwọn ìdí ilé baba+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, sí Jerúsálẹ́mù, láti gbé àpótí+ májẹ̀mú Jèhófà gòkè wá+ láti Ìlú Ńlá Dáfídì,+ èyíinì ni, Síónì.+  Nítorí náà, gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì péjọ pọ̀ sọ́dọ̀ ọba nígbà àjọyọ̀ náà, ti oṣù keje.+  Nítorí náà, gbogbo àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì wá,+ àwọn ọmọ Léfì sì bẹ̀rẹ̀ sí ru Àpótí+ náà.  Wọ́n sì ń gbé Àpótí+ gòkè bọ̀ àti àgọ́ ìpàdé+ àti gbogbo nǹkan èlò mímọ́+ tí ń bẹ nínú àgọ́. Àwọn àlùfáà àwọn ọmọ Léfì gbé wọn gòkè wá.+  Sólómọ́nì Ọba àti gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n ń pa àdéhùn wọn mọ́ pẹ̀lú rẹ̀ níwájú Àpótí ń fi àgùntàn àti màlúù tí kò ṣeé kà tàbí tí kò níye rúbọ+ nítorí jíjẹ́ ògìdìgbó.  Nígbà náà ni àwọn àlùfáà gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà wá sí àyè rẹ̀, sínú yàrá inú pátápátá+ nínú ilé náà, sí Ibi Mímọ́ Jù Lọ,+ sí abẹ́ ìyẹ́ apá àwọn kérùbù náà.+  Àwọn kérúbù náà tipa báyìí na ìyẹ́ apá wọn jáde sórí ibi tí Àpótí wà nígbà gbogbo, tí ó fi jẹ́ pé àwọn kérúbù náà bo Àpótí àti àwọn ọ̀pá+ rẹ̀ láti òkè wá.+  Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀pá náà gùn, tí ó fi jẹ́ pé orí àwọn ọ̀pá náà ni a lè rí ní Ibi Mímọ́ ní iwájú yàrá inú pátápátá, ṣùgbọ́n a kò lè rí wọn lóde, wọ́n sì wà níbẹ̀ títí di òní yìí.+ 10  Kò sí nǹkan mìíràn nínú Àpótí náà ju wàláà méjì+ tí Mósè fi fúnni ní Hórébù,+ nígbà tí Jèhófà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú+ nígbà tí wọ́n ń jáde kúrò ní Íjíbítì.+ 11  Ó sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn àlùfáà jáde wá láti ibi mímọ́ (nítorí gbogbo àwọn àlùfáà tí a rí, ní tiwọn, ti sọ ara wọn di mímọ́+—kò sí ìdí kankan láti pa àwọn ìpín mọ́);+ 12  àwọn ọmọ Léfì+ tí ó jẹ́ akọrin tí ó jẹ́ ti gbogbo wọn, èyíinì ni, ti Ásáfù,+ ti Hémánì,+ ti Jédútúnì+ àti ti àwọn ọmọkùnrin wọn àti ti àwọn arákùnrin wọn tí wọ́n wọ aṣọ híhun àtàtà pẹ̀lú aro+ àti pẹ̀lú àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín+ àti háàpù,+ sì dúró síhà ìlà-oòrùn pẹpẹ àti pa pọ̀ pẹ̀lú wọn ọgọ́fà àlùfáà tí ń fun kàkàkí;+ 13  ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí àwọn afunkàkàkí àti àwọn akọrin ṣe ọ̀kan+ ní mímú kí a gbọ́ ìró kan ní yíyin Jèhófà àti dídúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, gbàrà tí wọ́n sì mú ìró náà dún sókè pẹ̀lú kàkàkí àti pẹ̀lú aro àti pẹ̀lú àwọn ohun èlò orin+ ní yíyin+ Jèhófà, “nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere,+ nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́+ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin,” ilé náà kún fún àwọsánmà,+ ilé Jèhófà gan-an,+ 14  àwọn àlùfáà kò sì lè dúró láti ṣe ìránṣẹ́ nítorí àwọsánmà náà;+ nítorí ògo Jèhófà+ kún ilé Ọlọ́run tòótọ́.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé