Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Kíróníkà 36:1-23

36  Nígbà náà ni àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú Jèhóáhásì+ ọmọkùnrin Jòsáyà, wọ́n sì fi í jẹ ọba ní ipò baba rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù.+  Ẹni ọdún mẹ́tàlélógún ni Jèhóáhásì nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, oṣù mẹ́ta sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù.+  Àmọ́ ṣá o, ọba Íjíbítì mú un kúrò ní Jerúsálẹ́mù,+ ó sì bu ọgọ́rùn-ún tálẹ́ńtì fàdákà+ àti tálẹ́ńtì wúrà kan lé ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ìtanràn.  Síwájú sí i, ọba+ Íjíbítì fi Élíákímù+ arákùnrin rẹ̀ jẹ ọba lé Júdà àti Jerúsálẹ́mù lórí, ó sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí Jèhóákímù; ṣùgbọ́n Nékò+ mú Jèhóáhásì arákùnrin rẹ̀, ó sì mú un wá sí Íjíbítì.+  Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni Jèhóákímù+ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mọ́kànlá sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù;+ ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ̀.  Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì sì gòkè wá+ láti gbéjà kò ó, kí ó lè fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà méjì dè é láti gbé e lọ sí Bábílónì.+  Nebukadinésárì+ sì kó lára àwọn nǹkan èlò+ ilé Jèhófà wá sí Bábílónì, ó sì wá kó wọn sínú ààfin rẹ̀ ní Bábílónì.+  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí+ Jèhóákímù àti àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí+ rẹ̀ tí ó ṣe àti ohun tí a rí lòdì sí i, ibẹ̀ ni a kọ wọ́n sí nínú Ìwé+ Àwọn Ọba Ísírẹ́lì àti Júdà; Jèhóákínì+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.  Ẹni ọdún méjìdínlógún ni Jèhóákínì+ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, oṣù mẹ́ta+ àti ọjọ́ mẹ́wàá sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù; ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.+ 10  Nígbà ìyípo+ ọdún, Nebukadinésárì Ọba sì ránṣẹ́,+ ó sì tẹ̀ síwájú láti mú un wá sí Bábílónì+ pẹ̀lú àwọn ohun èlò fífani-lọ́kàn-mọ́ra ti ilé Jèhófà.+ Síwájú sí i, ó fi Sedekáyà+ arákùnrin baba rẹ̀ jẹ ọba lé Júdà àti Jerúsálẹ́mù+ lórí. 11  Ẹni ọdún mọ́kànlélógún ni Sedekáyà+ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mọ́kànlá sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù.+ 12  Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó burú+ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀. Kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀+ ní tìtorí Jeremáyà+ wòlíì+ fún àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà. 13  Ó tilẹ̀ ṣọ̀tẹ̀+ sí Nebukadinésárì Ọba, ẹni tí ó ti mú kí ó fi Ọlọ́run+ búra; ó sì ń bá a nìṣó ní mímú ọrùn rẹ̀ le+ àti ní sísé ọkàn-àyà rẹ̀ le+ kí ó má bàa padà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì. 14  Àní gbogbo olórí àwọn àlùfáà+ àti àwọn ènìyàn náà alára hu ìwà àìṣòótọ́ ní ìwọ̀n púpọ̀ gan-an, gẹ́gẹ́ bí gbogbo àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí+ ti àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó fi jẹ́ pé wọ́n sọ ilé Jèhófà di ẹlẹ́gbin, èyí tí òun ti sọ di mímọ́ ní Jerúsálẹ́mù.+ 15  Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọ́n sì ń ránṣẹ́ lòdì sí wọn ṣáá nípasẹ̀ àwọn ońṣẹ́+ rẹ̀, ó ń ránṣẹ́ léraléra, nítorí pé ó ní ìyọ́nú sí àwọn ènìyàn+ rẹ̀ àti sí ibùgbé+ rẹ̀. 16  Ṣùgbọ́n wọ́n ń bá a lọ ní fífi àwọn ońṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀fẹ̀,+ wọ́n sì ń tẹ́ńbẹ́lú àwọn ọ̀rọ̀+ rẹ̀, wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà,+ títí ìhónú+ Jèhófà fi jáde wá sórí àwọn ènìyàn rẹ̀, títí kò fi sí ìmúláradá.+ 17  Nítorí náà, ó gbé ọba àwọn ará Kálídíà+ dìde sí wọn, ẹni tí ó bẹ̀rẹ̀ sí fi idà+ pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn nínú ilé ibùjọsìn+ wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìyọ́nú sí ọ̀dọ́kùnrin tàbí wúńdíá, arúgbó tàbí ọ̀jọ̀kútọtọ.+ Ohun gbogbo ni ó fi lé e lọ́wọ́. 18  Gbogbo àwọn nǹkan èlò ilé+ Ọlọ́run tòótọ́, ńlá+ àti kékeré, àti àwọn ìṣúra+ ilé Jèhófà àti àwọn ìṣúra ọba+ àti ti àwọn ọmọ aládé rẹ̀, gbogbo rẹ̀ sì ni ó kó wá sí Bábílónì. 19  Ó sì tẹ̀ síwájú láti fi iná sun ilé Ọlọ́run tòótọ́,+ ó sì bi ògiri+ Jerúsálẹ́mù wó; gbogbo àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ̀ sì ni wọ́n fi iná sun àti gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ fífani-lọ́kàn-mọ́ra+ pẹ̀lú, láti lè mú ìparun wá.+ 20  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó kó àwọn tí ó ṣẹ́ kù lọ́wọ́ idà lọ sí Bábílónì+ ní òǹdè, wọ́n sì wá di ìránṣẹ́ fún òun+ àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí di ìgbà tí agbára ìṣàkóso Páṣíà+ bẹ̀rẹ̀ sí jọba; 21  láti mú ọ̀rọ̀ Jèhófà láti ẹnu Jeremáyà+ ṣẹ, títí ilẹ̀ náà fi san àwọn sábáàtì+ rẹ̀ tán pátá. Ní gbogbo ọjọ́ tí ó fi wà ní ahoro, ó ń pa sábáàtì mọ́, láti mú àádọ́rin ọdún+ pé. 22  Àti ní ọdún kìíní Kírúsì+ ọba Páṣíà,+ kí a lè mú ọ̀rọ̀+ Jèhófà láti ẹnu Jeremáyà+ ṣẹ, Jèhófà ta ẹ̀mí+ Kírúsì ọba Páṣíà jí, tí ó fi mú kí igbe kan la gbogbo ìjọba rẹ̀ kọjá, a sì kọ̀wé+ rẹ̀ pẹ̀lú, pé: 23  “Èyí ni ohun tí Kírúsì ọba Páṣíà+ wí, ‘Gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé ni Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run ti fi fún mi,+ òun fúnra rẹ̀ sì ti fàṣẹ yàn mí pé kí n kọ́ ilé fún òun ní Jerúsálẹ́mù, tí ó wà ní Júdà.+ Ẹnì yòówù tí ń bẹ láàárín yín nínú gbogbo ènìyàn rẹ̀,+ kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.+ Nítorí náà, kí ó gòkè lọ.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé