Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Kíróníkà 34:1-33

34  Ẹni ọdún mẹ́jọ+ ni Jòsáyà+ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù.+  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà,+ ó sì ń rìn ní àwọn ọ̀nà Dáfídì baba ńlá rẹ̀;+ kò sì yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.+  Àti ní ọdún kẹjọ ìgbà ìjọba rẹ̀, nígbà tí ó ṣì jẹ́ ọmọdékùnrin,+ ó bẹ̀rẹ̀ sí wá+ Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ̀; ní ọdún kejìlá sì ni ó bẹ̀rẹ̀ sí fọ+ àwọn ibi gíga+ àti àwọn òpó ọlọ́wọ̀+ àti àwọn ère fífín+ àti àwọn ère dídà kúrò ní Júdà àti Jerúsálẹ́mù.  Síwájú sí i, wọ́n bi àwọn pẹpẹ+ àwọn Báálì+ wó níwájú rẹ̀; àwọn pẹpẹ tùràrí+ tí ó sì wà ní òkè ni ó ké lulẹ̀ kúrò lára wọn; ó sì fọ́ àwọn òpó ọlọ́wọ̀+ àti àwọn ère fífín+ àti àwọn ère dídà sí wẹ́wẹ́, ó sì sọ wọ́n di ekuru,+ lẹ́yìn náà sì ni ó wọ́n ọn sí ojú àwọn ibi ìsìnkú àwọn tí ó ti máa ń rúbọ sí wọn.+  Ó sì fi iná sun egungun+ àwọn àlùfáà lórí àwọn pẹpẹ wọn.+ Bí ó ṣe fọ Júdà àti Jerúsálẹ́mù mọ́ nìyẹn.  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ní àwọn ìlú ńlá Mánásè+ àti Éfúráímù+ àti Síméónì àti títí lọ dé Náfútálì, ní àwọn ibi ìparundahoro wọn yí ká,  ó tilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bi àwọn pẹpẹ+ àti àwọn òpó ọlọ́wọ̀+ wó, ó sì fọ́ àwọn ère fífín+ túútúú, ó sì sọ wọ́n di ekuru;+ ó sì ké gbogbo àwọn pẹpẹ tùràrí+ lulẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì, lẹ́yìn èyí tí ó padà wá sí Jerúsálẹ́mù.  Àti ní ọdún kejìdínlógún+ ìgbà ìjọba rẹ̀, nígbà tí ó ti fọ ilẹ̀ àti ilé náà mọ́, ó rán Ṣáfánì+ ọmọkùnrin Asaláyà àti Maaseáyà olórí ìlú ńlá náà àti Jóà ọmọkùnrin Jóáhásì akọ̀wé ìrántí láti lọ tún ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ ṣe.+  Wọ́n sì tọ Hilikáyà+ àlùfáà àgbà wá, wọ́n sì fún un ní owó tí a ń mú wá sí ilé Ọlọ́run, èyí tí àwọn ọmọ Léfì àti àwọn olùṣọ́nà+ ti kó jọ láti ọwọ́ Mánásè+ àti Éfúráímù+ àti láti ọwọ́ gbogbo ìyókù Ísírẹ́lì+ àti láti ọwọ́ gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù. 10  Nígbà náà ni wọ́n fi í lé ọwọ́ àwọn olùṣe iṣẹ́ náà, àwọn tí a yàn sípò lórí ilé Jèhófà.+ Ẹ̀wẹ̀, àwọn olùṣe iṣẹ́ náà tí wọ́n jẹ́ aláápọn nínú ilé Jèhófà sì lò ó fún ìmúbọ̀sípò àti títún ilé náà ṣe. 11  Nítorí náà, wọ́n fi í fún àwọn oníṣẹ́ ọnà àti àwọn akọ́lé+ láti fi ra àwọn òkúta gbígbẹ́+ àti àwọn ẹ̀là gẹdú fún àwọn ẹ̀mú-amóhunpọ̀ àti pé kí wọ́n fi àwọn ìtì igi kọ́ àwọn ilé tí àwọn ọba+ Júdà ti run. 12  Àwọn ọkùnrin náà sì ń fi ìṣòtítọ́+ hùwà nínú iṣẹ́ náà; a sì yan Jáhátì àti Ọbadáyà, àwọn ọmọ Léfì, láti inú àwọn ọmọ Mérárì+ sípò lé wọn lórí, àti Sekaráyà àti Méṣúlámù, láti inú àwọn ọmọkùnrin lára ọmọ Kóhátì,+ láti máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó. Àti àwọn ọmọ Léfì, tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọ́n jẹ́ ògbógi nínú àwọn ohun èlò orin,+ 13  ni ó wà lórí àwọn arẹrù,+ àti àwọn alábòójútó+ gbogbo àwọn olùṣe iṣẹ́ náà fún onírúurú iṣẹ́ ìsìn; láti inú àwọn ọmọ Léfì+ sì ni àwọn akọ̀wé+ àti onípò àṣẹ àti aṣọ́bodè+ ti wá. 14  Wàyí o, bí wọ́n ti ń mú owó+ náà jáde, èyí tí a ń mú wá sí ilé Jèhófà, Hilikáyà+ àlùfáà rí ìwé+ òfin Jèhófà+ láti ọwọ́ Mósè.+ 15  Nítorí náà, Hilikáyà dáhùn, ó sì wí fún Ṣáfánì+ akọ̀wé pé: “Ìwé òfin gan-an ni mo ti rí ní ilé Jèhófà.” Pẹ̀lú ìyẹn, Hilikáyà fi ìwé náà fún Ṣáfánì. 16  Nígbà náà ni Ṣáfánì mú ìwé náà wá sọ́dọ̀ ọba, ó sì tún fún ọba lésì pé: “Gbogbo ohun tí a fi lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ lọ́wọ́ ni wọ́n ń ṣe. 17  Wọ́n sì da owó tí a rí nínú ilé Jèhófà, wọ́n sì fi í lé ọwọ́ àwọn ọkùnrin tí a yàn sípò àti lé ọwọ́ àwọn olùṣe iṣẹ́ náà.”+ 18  Ṣáfánì akọ̀wé sì ń bá a lọ láti ròyìn fún ọba pé: “Ìwé+ kan wà tí Hilikáyà àlùfáà fi fún mi.”+ Ṣáfánì sì bẹ̀rẹ̀ sí kà láti inú rẹ̀ níwájú ọba.+ 19  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ọba gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ òfin náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó gbọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya.+ 20  Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Hilikáyà+ àti Áhíkámù+ ọmọkùnrin Ṣáfánì àti Ábídónì ọmọkùnrin Míkà àti Ṣáfánì+ akọ̀wé+ àti Ásáyà+ ìránṣẹ́ ọba, pé: 21  “Ẹ lọ, ẹ wádìí+ lọ́dọ̀ Jèhófà nítorí tèmi+ àti nítorí èyí tí ó ṣẹ́ kù nínú Ísírẹ́lì àti nínú Júdà nípa àwọn ọ̀rọ̀ ìwé+ tí a rí, nítorí títóbi ni ìhónú+ Jèhófà tí a óò tú jáde sórí wa nítorí òtítọ́ náà pé àwọn baba ńlá wa kò pa ọ̀rọ̀ Jèhófà mọ́ nípa ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí a kọ sínú ìwé yìí.”+ 22  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Hilikáyà, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ọba ti sọ, lọ sọ́dọ̀ Húlídà+ wòlíì obìnrin,+ aya Ṣálúmù ọmọkùnrin Tíkífà ọmọkùnrin Háhásì olùbójútó àwọn ẹ̀wù,+ bí ó ti ń gbé ní Jerúsálẹ́mù ní ìhà kejì; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà yìí. 23  Ẹ̀wẹ̀, ó wí fún wọn pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Ẹ wí fún ọkùnrin tí ó rán yín wá sọ́dọ̀ mi pé: 24  “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò mú ìyọnu àjálù+ wá sórí ibí yìí àti àwọn olùgbé+ rẹ̀, gbogbo ègún+ tí a kọ sínú ìwé tí wọ́n kà níwájú ọba Júdà,+ 25  nítorí òtítọ́ náà pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀,+ wọ́n sì lọ ń rú èéfín ẹbọ sí àwọn ọlọ́run+ mìíràn, kí wọ́n lè fi gbogbo ìgbòkègbodò iṣẹ́ ọwọ́+ wọn mú mi bínú,+ kí ìhónú+ mi sì lè tú jáde sórí ibí yìí, kí a má sì fẹ́ ẹ pa.’”+ 26  Àti sí ọba Júdà, tí ó rán yín láti wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, èyí ni ohun tí ẹ óò wí fún un: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí,+ ‘Ní ti àwọn ọ̀rọ̀+ tí o ti gbọ́, 27  nítorí ìdí náà pé ọkàn-àyà+ rẹ rọ̀, tí ó fi jẹ́ pé o rẹ ara rẹ sílẹ̀+ nítorí Ọlọ́run bí o ṣe gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa ibí yìí àti àwọn olùgbé rẹ̀, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú mi,+ tí o sì gbọn ẹ̀wù rẹ ya,+ tí o sì sunkún níwájú mi, èmi, àní èmi, ti gbọ́,+ ni àsọjáde Jèhófà. 28  Kíyè sí i, èmi yóò kó ọ jọ sọ́dọ̀ àwọn baba ńlá rẹ, a ó sì kó ọ jọ dájúdájú sínú itẹ́ rẹ ní àlàáfíà,+ ojú rẹ kì yóò sì rí gbogbo ìyọnu àjálù+ tí èmi yóò mú wá sórí ibí yìí àti àwọn olùgbé rẹ̀.’”’”+ Nígbà náà ni wọ́n mú èsì wá fún ọba. 29  Ọba sì tẹ̀ síwájú láti ránṣẹ́, ó sì kó gbogbo àwọn àgbà ọkùnrin Júdà àti ti Jerúsálẹ́mù+ jọ. 30  Wàyí o, ọba gòkè lọ sí ilé Jèhófà+ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn Júdà àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù àti àwọn àlùfáà+ àti àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo àwọn ènìyàn náà, ẹni ńlá àti ẹni kékeré; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ka+ gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé májẹ̀mú náà, tí a rí ní ilé Jèhófà+ sí etí wọn. 31  Ọba sì wà ní ìdúró ní ipò rẹ̀,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dá májẹ̀mú+ níwájú Jèhófà pé òun yóò máa fi gbogbo ọkàn-àyà+ àti gbogbo ọkàn+ tọ Jèhófà lẹ́yìn àti pé òun yóò pa àwọn àṣẹ+ rẹ̀ àti àwọn gbólóhùn ẹ̀rí+ rẹ̀ àti àwọn ìlànà+ rẹ̀ mọ́, pé òun yóò máa tẹ̀ lé+ àwọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí a kọ sínú ìwé yìí.+ 32  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó mú kí gbogbo àwọn tí a rí ní Jerúsálẹ́mù àti Bẹ́ńjámínì mú ìdúró wọn nínú rẹ̀. Àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú Ọlọ́run, Ọlọ́run àwọn baba ńlá+ wọn. 33  Lẹ́yìn ìyẹn, Jòsáyà mú gbogbo àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí+ kúrò nínú gbogbo àwọn ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ ó sì mú kí gbogbo àwọn tí a rí ní Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn, láti máa sin Jèhófà Ọlọ́run wọn. Ní gbogbo ọjọ́ rẹ̀, wọn kò yà kúrò nínú títọ Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá+ wọn lẹ́yìn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé