Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

2 Kíróníkà 32:1-33

32  Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí àti ipa ọ̀nà ìṣòtítọ́ yìí,+ Senakéríbù+ ọba Ásíríà+ wá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbógun ti Júdà, ó sì dó ti àwọn ìlú ńlá olódi náà,+ ó sì ń ronú àtisọ wọ́n di tirẹ̀ nípasẹ̀ ìyawọ̀lú.  Nígbà tí Hesekáyà rí i pé Senakéríbù ti dé ní dídójúlé+ àtibá Jerúsálẹ́mù ja ogun,  nígbà náà, òun àti àwọn ọmọ aládé rẹ̀+ àti àwọn ọkùnrin alágbára ńlá pinnu láti sé omi inú àwọn ìsun tí ń bẹ ní òde ìlú ńlá+ náà pa; nítorí náà, wọ́n ràn án lọ́wọ́.  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, a kó ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn jọpọ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sé gbogbo ojúsun omi pa àti ọ̀gbàrá+ tí ń kún la àárín ilẹ̀ náà kọjá, wọ́n wí pé: “Èé ṣe tí àwọn ọba Ásíríà yóò fi wá, tí wọn yóò sì rí omi púpọ̀ ní ti gidi?”  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó mọ́kànle, ó sì mọ gbogbo ògiri tí a ti wó lulẹ̀,+ ó sì gbé àwọn ilé gogoro+ nà ró lé e lórí, àti ògiri+ mìíràn lóde, ó sì tún Òkìtì+ Ìlú Ńlá Dáfídì ṣe, ó sì ṣe àwọn ohun ọṣẹ́+ lọ́pọ̀ yanturu àti àwọn apata.+  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi olórí tí í ṣe ológun+ sórí àwọn ènìyàn náà, ó sì kó wọn jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ní ojúde ìlú+ ti ẹnubodè ìlú ńlá náà, ó sì bá ọkàn-àyà+ wọn sọ̀rọ̀ pé:  “Ẹ jẹ́ onígboyà àti alágbára.+ Ẹ má fòyà+ tàbí kí ẹ jáyà+ nítorí ọba Ásíríà+ àti ní tìtorí gbogbo ogunlọ́gọ̀ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀;+ nítorí àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.  Apá tí ó jẹ́ ẹran ara ni ó wà pẹ̀lú rẹ̀,+ ṣùgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run wa ni ó wà pẹ̀lú wa láti ràn wá lọ́wọ́+ àti láti ja àwọn ìjà ogun wa.”+ Àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ọ̀rọ̀ Hesekáyà ọba Júdà gbé ara wọn ró.+  Lẹ́yìn èyí ni Senakéríbù+ ọba Ásíríà rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù, nígbà tí ó wà ní Lákíṣì,+ tí gbogbo agbára ńlá ti aláyélúwà rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀,+ sí Hesekáyà ọba Júdà àti sí gbogbo àwọn ará Jùdíà tí ń bẹ ní Jerúsálẹ́mù pé: 10  “Èyí ni ohun tí Senakéríbù ọba Ásíríà wí,+ ‘Kí ni ẹ gbẹ́kẹ̀ lé bí ẹ ti jókòó jẹ́ẹ́ lábẹ́ ìsàgatì ní Jerúsálẹ́mù?+ 11  Kì í ha ṣe pé Hesekáyà+ ń dẹ yín lọ+ láti lè fi yín léni lọ́wọ́ láti kú nípasẹ̀ ìyàn àti nípasẹ̀ òùngbẹ, ní wíwí pé: “Jèhófà Ọlọ́run wa tìkára rẹ̀ yóò dá wa nídè kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ ọba Ásíríà”?+ 12  Kì í ha ṣe Hesekáyà fúnra rẹ̀ ni ó mú àwọn ibi gíga+ rẹ̀ àti àwọn pẹpẹ+ rẹ̀ kúrò, tí ó sì wá sọ fún Júdà àti Jerúsálẹ́mù pé: “Iwájú pẹpẹ kan ṣoṣo+ ni kí ẹ ti máa tẹrí ba,+ orí rẹ̀ sì ni kí ẹ ti máa rú èéfín ẹbọ”?+ 13  Ṣé ẹ̀yin kò mọ ohun tí èmi fúnra mi àti àwọn baba ńlá mi ṣe sí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn ni?+ Ṣé àwọn ọlọ́run+ àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ wọnnì lè dá ilẹ̀ wọn nídè rárá kúrò ní ọwọ́ mi? 14  Ta ní ń bẹ lára gbogbo àwọn ọlọ́run orílẹ̀-èdè wọ̀nyí tí àwọn baba ńlá mi yà sọ́tọ̀ fún ìparun tí ó lè dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè kúrò ní ọwọ́ mi, tí Ọlọ́run yín yóò fi lè dá yín nídè kúrò ní ọwọ́ mi?+ 15  Wàyí o, ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekáyà tàn yín jẹ+ tàbí kí o dẹ yín lọ+ lọ́nà yìí, ẹ má sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, nítorí kò sí ọlọ́run orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba èyíkéyìí tí ó lè dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè kúrò ní ọwọ́ mi àti kúrò ní ọwọ́ àwọn baba ńlá mi. Áńbọ̀sìbọ́sí Ọlọ́run tiyín, tí yóò wá fi dá yín nídè kúrò ní ọwọ́ mi!’”+ 16  Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì tún sọ̀rọ̀ síwájú sí i sí Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́+ àti sí Hesekáyà ìránṣẹ́ rẹ̀. 17  Ó tilẹ̀ kọ àwọn lẹ́tà+ láti fi gan Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì+ àti láti fi sọ̀rọ̀ sí i, pé: “Bí ti àwọn ọlọ́run+ àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ tí kò dá àwọn ènìyàn wọn nídè kúrò ní ọwọ́ mi,+ bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run Hesekáyà kì yóò dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè kúrò ní ọwọ́ mi.” 18  Wọ́n+ sì ń bá a nìṣó ní fífi ohùn rara+ ké ní èdè àwọn Júù+ sí àwọn ènìyàn Jerúsálẹ́mù tí ń bẹ lórí ògiri, láti mú wọn fòyà+ àti láti yọ wọ́n lẹ́nu, kí wọ́n lè gba ìlú ńlá náà. 19  Wọ́n sì ń bá a lọ ní sísọ̀rọ̀ sí+ Ọlọ́run Jerúsálẹ́mù+ ní ọ̀nà kan náà tí wọ́n gbà ń sọ̀rọ̀ sí àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé, iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn.+ 20  Ṣùgbọ́n Hesekáyà+ Ọba àti Aísáyà+ ọmọkùnrin Émọ́sì,+ wòlíì,+ ń gbàdúrà ṣáá lórí èyí,+ wọ́n sì ń kígbe sí ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́.+ 21  Jèhófà sì rán áńgẹ́lì kan,+ ó sì pa gbogbo akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin+ rẹ́ àti aṣáájú àti olórí nínú ibùdó ọba Ásíríà,+ tí ó fi jẹ́ pé ó fi ìtìjú padà lọ sí ilẹ̀ tirẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó wọ ilé ọlọ́run rẹ̀, àwọn kan báyìí tí wọ́n jáde wá láti ìhà inú òun fúnra rẹ̀ sì fi idà ké e lulẹ̀ níbẹ̀.+ 22  Bí Jèhófà ṣe gba Hesekáyà àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù là nìyẹn kúrò ní ọwọ́ Senakéríbù ọba Ásíríà+ àti kúrò ní ọwọ́ gbogbo àwọn yòókù, ó sì fún wọn ní ìsinmi yí ká.+ 23  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni ó wà tí ń mú ẹ̀bùn+ wá fún Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù àti àwọn ohun ààyò fún Hesekáyà ọba Júdà,+ ó sì wá di ẹni tí a gbé ga+ ní ojú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè lẹ́yìn ìyẹn. 24  Ní ọjọ́ wọnnì, Hesekáyà ṣàìsàn dé ojú ikú,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà+ sí Jèhófà. Nítorí náà, Òun bá a sọ̀rọ̀,+ Òun sì fún un ní àmì àgbàyanu.+ 25  Ṣùgbọ́n ní ìbámu pẹ̀lú àǹfààní tí a fi fún un, Hesekáyà kò dá nǹkan kan padà,+ nítorí ọkàn-àyà rẹ̀ di onírera,+ ìkannú+ sì wá wà sí i àti sí Júdà àti Jerúsálẹ́mù. 26  Àmọ́ ṣá o, Hesekáyà rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀+ nítorí ìrera ọkàn-àyà rẹ̀, òun àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù, ìkannú Jèhófà kò sì wá sórí wọn ní àwọn ọjọ́ Hesekáyà.+ 27  Hesekáyà sì wá ní ọrọ̀ àti ògo ní iye púpọ̀ gan-an;+ ó sì ṣe àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí fún ara rẹ̀ fún fàdákà àti fún wúrà+ àti fún àwọn òkúta iyebíye+ àti fún òróró básámù+ àti fún àwọn apata+ àti fún gbogbo àwọn ohun èlò fífani-lọ́kàn-mọ́ra;+ 28  àti àwọn ibi ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí+ pẹ̀lú fún èso ọkà àti wáìnì tuntun+ àti òróró, àti àwọn ibùso+ pẹ̀lú fún gbogbo onírúurú ẹranko àti àwọn ibùso fún àwọn agbo ẹran ọ̀sìn. 29  Ó sì gba àwọn ìlú ńlá fún ara rẹ̀, àti àwọn ohun ọ̀sìn ti inú agbo+ ọ̀wọ́ ẹran+ pẹ̀lú ní ọ̀pọ̀ yanturu; nítorí Ọlọ́run fún un ní ẹrù púpọ̀ gidigidi.+ 30  Hesekáyà sì ni ẹni tí ó sé+ orísun apá òkè ti omi+ Gíhónì+ pa, ó sì darí wọn ní tààràtà sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ìwọ̀-oòrùn sí Ìlú Ńlá Dáfídì,+ Hesekáyà sì ń bá a lọ ní ṣíṣe àṣeyọrí sí rere nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.+ 31  Bí ó sì ti jẹ́ nìyẹn pé, nípasẹ̀ àwọn agbọ̀rọ̀sọ àwọn ọmọ aládé Bábílónì+ tí a rán sí i+ láti ṣe ìwádìí nípa àmì àgbàyanu+ tí ó ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà, Ọlọ́run tòótọ́ fi í sílẹ̀+ láti dán an wò,+ láti lè mọ ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.+ 32  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí+ Hesekáyà àti àwọn ìṣe inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́,+ ibẹ̀ ni a kọ wọ́n sí nínú ìran Aísáyà wòlíì, ọmọkùnrin Émọ́sì,+ nínú Ìwé+ Àwọn Ọba Júdà àti Ísírẹ́lì. 33  Níkẹyìn, Hesekáyà dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ wọ́n sì sin ín síbi ìgòkè lọ sí àwọn ibi ìsìnkú àwọn ọmọ Dáfídì;+ gbogbo Júdà àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù sì bu ọlá fún un nígbà ikú rẹ̀.+ Mánásè+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé